-
Mátíù 9:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù wá bá a, wọ́n sì bi í pé: “Kí ló dé tí àwa àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”+ 15 Jésù sọ fún wọn pé: “Kò sí ohun tó máa mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó ṣọ̀fọ̀ tí ọkọ ìyàwó+ bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ó wà? Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n máa wá gbààwẹ̀.
-
-
Lúùkù 5:33-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Wọ́n sọ fún un pé: “Léraléra ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù máa ń gbààwẹ̀, tí wọ́n sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń jẹ, wọ́n sì ń mu.”+ 34 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ ò lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó gbààwẹ̀ tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀? 35 Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó+ kúrò lọ́dọ̀ wọn ní tòótọ́; wọ́n máa wá gbààwẹ̀ láwọn ọjọ́ yẹn.”+
-