-
Mátíù 27:20-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà rọ àwọn èrò náà pé kí wọ́n sọ pé Bárábà ni àwọn fẹ́,+ àmọ́ kí wọ́n pa Jésù.+ 21 Gómìnà dá wọn lóhùn pé: “Èwo nínú àwọn méjèèjì lẹ fẹ́ kí n tú sílẹ̀ fún yín?” Wọ́n sọ pé: “Bárábà.” 22 Pílátù sọ fún wọn pé: “Kí wá ni kí n ṣe sí Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi?” Gbogbo wọ́n sọ pé: “Kàn án mọ́gi!”*+ 23 Ó sọ pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ló ṣe?” Síbẹ̀, wọ́n túbọ̀ ń kígbe ṣáá pé: “Kàn án mọ́gi!”+
-
-
Ìṣe 3:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ sọ pé ẹ ò mọ ẹni mímọ́ àti olódodo yẹn rí, ẹ sì ní kí wọ́n fún yín ní ọkùnrin tó jẹ́ apààyàn,+
-