-
Lúùkù 23:20-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Pílátù tún gbóhùn sókè bá wọn sọ̀rọ̀, torí ó fẹ́ tú Jésù sílẹ̀.+ 21 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”*+ 22 Ó sọ fún wọn lẹ́ẹ̀kẹta pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ni ọkùnrin yìí ṣe? Mi ò rí ohunkóhun tó ṣe tí ikú fi tọ́ sí i; torí náà, ṣe ni màá fìyà jẹ ẹ́, màá sì tú u sílẹ̀.” 23 Ni wọ́n bá kọ̀ jálẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé àfi kó pa á,* ọ̀rọ̀ wọn ló sì borí.+ 24 Torí náà, Pílátù pinnu pé òun máa ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. 25 Ó tú ọkùnrin tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀, ẹni tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ìdìtẹ̀ sí ìjọba àti ìpànìyàn, àmọ́ ó fa Jésù lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ sí i.
-