-
Mátíù 9:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Kò sí ẹni tó máa rán ègé aṣọ tí kò tíì sún kì mọ́ ara aṣọ àwọ̀lékè tó ti gbó, torí aṣọ tuntun náà máa ya kúrò lára aṣọ àwọ̀lékè náà, ó sì máa ya ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.+ 17 Àwọn èèyàn kì í sì í rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àpò náà máa bẹ́, wáìnì á dà nù, àpò náà á sì bà jẹ́. Àmọ́ inú àpò awọ tuntun ni àwọn èèyàn máa ń rọ wáìnì tuntun sí, ohunkóhun ò sì ní ṣe méjèèjì.”
-
-
Lúùkù 5:36-38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
36 Ó tún sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Kò sí ẹni tó máa gé lára aṣọ àwọ̀lékè tuntun, kó sì rán ègé náà mọ́ ara aṣọ tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ègé aṣọ tuntun náà máa ya kúrò, aṣọ tí wọ́n gé lára aṣọ tuntun náà kò sì ní bá èyí tó ti gbó mu.+ 37 Bákan náà, kò sí ẹni tó máa rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, wáìnì tuntun náà máa bẹ́ àpò awọ náà, ó máa dà nù, àpò náà sì máa bà jẹ́. 38 Àmọ́ inú àpò awọ tuntun la gbọ́dọ̀ rọ wáìnì tuntun sí.
-