ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 12:9-14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Lẹ́yìn tó kúrò níbẹ̀, ó lọ sínú sínágọ́gù wọn, 10 wò ó! ọkùnrin kan wà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ!+ Kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án, wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì?”+ 11 Ó sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá ní àgùntàn kan, tí àgùntàn náà sì já sínú kòtò ní Sábáàtì, ṣé ẹnì kan wà nínú yín tí kò ní dì í mú, kó sì gbé e jáde?+ 12 Ṣé èèyàn ò wá ṣeyebíye ju àgùntàn lọ? Torí náà, ó bófin mu láti ṣe ohun tó dáa ní Sábáàtì.” 13 Ó wá sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa dà rí bíi ti ọwọ́ kejì. 14 Àmọ́ àwọn Farisí jáde lọ, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

  • Lúùkù 6:6-11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Ní sábáàtì míì,+ ó wọ inú sínágọ́gù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni. Ọkùnrin kan sì wà níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ.+ 7 Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá ń ṣọ́ Jésù lójú méjèèjì, wọ́n ń wò ó bóyá ó máa ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì, kí wọ́n lè rí ọ̀nà láti fẹ̀sùn kàn án. 8 Àmọ́ ó mọ ohun tí wọ́n ń rò,+ torí náà, ó sọ fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé: “Dìde, kí o dúró ní àárín.” Ó dìde, ó sì dúró síbẹ̀. 9 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Mò ń bi yín, Ṣé ó bófin mu ní Sábáàtì láti ṣe rere tàbí láti ṣe ibi, láti gba ẹ̀mí* là tàbí láti pa á run?”+ 10 Lẹ́yìn tó wo gbogbo wọn yí ká, ó sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. 11 Àmọ́ wọ́n bínú gidigidi láìronú jinlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn sọ ohun tí wọ́n lè ṣe sí Jésù.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́