-
Mátíù 9:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Àmọ́ àwọn Farisí ń sọ pé: “Agbára alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù ló fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”+
-
-
Mátíù 12:24-29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Nígbà tí àwọn Farisí gbọ́ èyí, wọ́n sọ pé: “Ọ̀gbẹ́ni yìí kò lè lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, tí kò bá ní agbára Béélísébúbù,* alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”+ 25 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó wá sọ fún wọn pé: “Gbogbo ìjọba tó bá pínyà sí ara rẹ̀ máa pa run, gbogbo ìlú tàbí ilé tó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ kò ní dúró. 26 Lọ́nà kan náà, tí Sátánì bá ń lé Sátánì jáde, ó ti pínyà sí ara rẹ̀ nìyẹn; báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe máa wá dúró? 27 Bákan náà, tó bá jẹ́ agbára Béélísébúbù ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa jẹ́ adájọ́ yín. 28 Àmọ́ tó bá jẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, Ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín lójijì lóòótọ́.+ 29 Àbí báwo ni ẹnì kan ṣe lè gbógun wọ ilé ọkùnrin alágbára, kó sì fipá gba àwọn ohun ìní rẹ̀, tí kò bá kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà mọ́lẹ̀? Ìgbà yẹn ló máa tó lè kó o lẹ́rù nínú ilé rẹ̀.
-