-
Mátíù 13:3-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ó wá fi àpèjúwe sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan fún wọn,+ ó ní: “Ẹ wò ó! Afúnrúgbìn kan jáde lọ fún irúgbìn.+ 4 Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, àwọn ẹyẹ wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.+ 5 Àwọn míì já bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì hù lójú ẹsẹ̀ torí pé iyẹ̀pẹ̀ náà ò jìn.+ 6 Àmọ́ nígbà tí oòrùn ràn, ó jó wọn gbẹ, wọ́n sì rọ torí pé wọn ò ní gbòǹgbò. 7 Àwọn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún náà yọ, wọ́n sì fún wọn pa.+ 8 Síbẹ̀ àwọn míì já bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í so èso, eléyìí so ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ìyẹn ọgọ́ta (60), òmíràn ọgbọ̀n (30).+ 9 Kí ẹni tó bá ní etí fetí sílẹ̀.”+
-
-
Lúùkù 8:5-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 “Afúnrúgbìn kan jáde lọ fún irúgbìn rẹ̀. Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ lára rẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, wọ́n tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ.+ 6 Àwọn kan já bọ́ sórí àpáta, lẹ́yìn tí wọ́n sì rú jáde, wọ́n gbẹ dà nù torí pé omi ò rin ibẹ̀.+ 7 Àwọn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún tí wọ́n sì jọ dàgbà fún wọn pa.+ 8 Àmọ́ àwọn míì já bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, lẹ́yìn tí wọ́n sì rú jáde, wọ́n so èso ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100).”+ Bó ṣe sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbóhùn sókè, ó ní: “Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+
-