-
Nọ́ńbà 6:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì pé òun fẹ́ di Násírì*+ fún Jèhófà, 3 kó yẹra fún wáìnì àti àwọn ohun mímu míì tó ní ọtí. Kó má mu ohun kíkan tí wọ́n fi wáìnì ṣe tàbí ohun kíkan tí wọ́n fi nǹkan tó ní ọtí+ ṣe. Kó má mu ohunkóhun tí wọ́n fi èso àjàrà ṣe, kó má sì jẹ èso àjàrà, ì báà jẹ́ tútù tàbí gbígbẹ.
-
-
Mátíù 11:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Bákan náà, Jòhánù wá, kò jẹ, kò sì mu, àmọ́ àwọn èèyàn sọ pé, ‘Ẹlẹ́mìí èṣù ni.’
-