-
Jòhánù 5:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Jésù rí ọkùnrin yìí tó dùbúlẹ̀ síbẹ̀, ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tó ti ń ṣàìsàn, ó wá sọ fún ọkùnrin náà pé: “Ṣé o fẹ́ kí ara rẹ yá?”+ 7 Ọkùnrin aláìsàn náà dá a lóhùn pé: “Ọ̀gá, mi ò lẹ́ni tó lè gbé mi sínú adágún omi náà tó bá ti rú, torí tí n bá ti ń lọ síbẹ̀, ẹlòmíì á ti sọ̀ kalẹ̀ ṣáájú mi.” 8 Jésù sọ fún un pé: “Dìde! Gbé ẹní* rẹ, kí o sì máa rìn.”+ 9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ara ọkùnrin náà yá, ó gbé ẹní* rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.
Ọjọ́ Sábáàtì ni.
-