34 Ó dà bí ọkùnrin kan tó ń rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fún àwọn ẹrú rẹ̀ ní àṣẹ,+ tó yan iṣẹ́ fún kálukú, tó sì pàṣẹ fún aṣọ́nà pé kó máa ṣọ́nà.+
36 Jésù dáhùn pé:+ “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.+ Ká ní Ìjọba mi jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ì bá ti jà kí wọ́n má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́.+ Àmọ́, bó ṣe rí yìí, Ìjọba mi ò wá láti orísun yìí.”