-
Máàkù 6:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ọba Hẹ́rọ́dù wá gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, torí òkìkí orúkọ Jésù ti kàn káàkiri, àwọn èèyàn sì ń sọ pé: “A ti jí Jòhánù Onírìbọmi dìde, ìdí nìyẹn tó fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí.”+
-
-
Lúùkù 9:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Hẹ́rọ́dù* alákòóso agbègbè náà* wá gbọ́ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀ rárá torí àwọn kan ń sọ pé a ti jí Jòhánù dìde,+ 8 àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà ti fara hàn, àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ti dìde.+ 9 Hẹ́rọ́dù sọ pé: “Mo ti bẹ́ Jòhánù lórí.+ Ta wá ni ẹni tí mò ń gbọ́ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀?” Torí náà, ó ń wá bó ṣe máa rí i.+
-