-
Mátíù 28:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Lẹ́yìn Sábáàtì, nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, Màríà Magidalénì àti Màríà kejì wá wo sàréè náà.+
-
-
Mátíù 28:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Torí náà, wọ́n yára kúrò ní ibojì ìrántí náà, bí ẹ̀rù ṣe ń bà wọ́n, tínú wọn sì ń dùn gan-an, wọ́n sáré lọ ròyìn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.+
-
-
Lúùkù 24:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 wọ́n dé látibi ibojì* náà, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan yìí fún àwọn Mọ́kànlá náà àti gbogbo àwọn yòókù.+ 10 Àwọn obìnrin náà ni Màríà Magidalénì, Jòánà àti Màríà ìyá Jémíìsì. Bákan náà, àwọn obìnrin yòókù tó wà pẹ̀lú wọn ń sọ àwọn nǹkan yìí fún àwọn àpọ́sítélì. 11 Àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí dà bí ìsọkúsọ létí wọn, wọn ò sì gba àwọn obìnrin náà gbọ́.
-