24 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tó sì gba Ẹni tó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ a ò sì ní dá a lẹ́jọ́, àmọ́ ó ti tinú ikú bọ́ sínú ìyè.+
8 Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i báyìí, síbẹ̀ ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, inú yín sì ń dùn gan-an, ayọ̀ yín kọjá àfẹnusọ, ó sì jẹ́ ológo, 9 bí ọwọ́ yín ṣe ń tẹ èrè ìgbàgbọ́ yín, ìgbàlà yín.*+