Mátíù 4:16, 17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 16 Àwọn èèyàn tó jókòó sínú òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò, ní ti àwọn tó jókòó sí agbègbè òjìji ikú, ìmọ́lẹ̀+ tàn sórí wọn.”+ 17 Àtìgbà yẹn lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, tó sì ń sọ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”+ Jòhánù 3:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 Ohun tí a máa gbé ìdájọ́ kà nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ti wá sí ayé,+ àmọ́ àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, torí pé oníṣẹ́ ibi ni wọ́n. Jòhánù 12:46 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 46 Mo wá sínú ayé bí ìmọ́lẹ̀,+ kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú mi má bàa wà nínú òkùnkùn.+ 1 Jòhánù 2:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Síbẹ̀, àṣẹ tuntun ni mò ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín, ó jẹ́ òótọ́ nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ àti nínú tiyín, torí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ sì ti tàn báyìí.+
16 Àwọn èèyàn tó jókòó sínú òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò, ní ti àwọn tó jókòó sí agbègbè òjìji ikú, ìmọ́lẹ̀+ tàn sórí wọn.”+ 17 Àtìgbà yẹn lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, tó sì ń sọ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”+
19 Ohun tí a máa gbé ìdájọ́ kà nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ti wá sí ayé,+ àmọ́ àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, torí pé oníṣẹ́ ibi ni wọ́n.
8 Síbẹ̀, àṣẹ tuntun ni mò ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín, ó jẹ́ òótọ́ nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ àti nínú tiyín, torí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ sì ti tàn báyìí.+