27 Torí náà, wọ́n mú wọn wá, wọ́n sì ní kí wọ́n dúró níwájú Sàhẹ́ndìrìn. Àlùfáà àgbà wá bi wọ́n ní ìbéèrè, 28 ó sì sọ pé: “A kìlọ̀ fún yín gidigidi pé kí ẹ má ṣe máa kọ́ni nípa orúkọ yìí,+ síbẹ̀, ẹ wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù, ẹ sì pinnu láti mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sórí wa.”+