-
Ìṣe 25:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Késárì, níbi tó yẹ kí a ti dá ẹjọ́ mi. Mi ò ṣe àìdáa kankan sí àwọn Júù, bí ìwọ náà ṣe ń rí i kedere báyìí. 11 Tó bá jẹ́ pé oníwà àìtọ́ ni mí lóòótọ́, tí mo sì ti ṣe ohun tó yẹ fún ikú,+ mi ò bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ má pa mí; àmọ́ tí kò bá sí òótọ́ nínú gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn ọkùnrin yìí fi kàn mí, kò sẹ́ni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi mí lé wọn lọ́wọ́ kó lè fi wá ojú rere. Mo ké gbàjarè sí Késárì!”+ 12 Lẹ́yìn tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì ti bá àwùjọ àwọn agbani-nímọ̀ràn sọ̀rọ̀, ó fèsì pé: “Késárì lo ké gbàjarè sí; ọ̀dọ̀ Késárì ni wàá sì lọ.”
-