29 Ni gbogbo ìlú bá dà rú, wọ́n sì jọ rọ́ wọnú gbọ̀ngàn ìwòran náà, wọ́n wọ́ Gáyọ́sì àti Àrísítákọ́sì jáde,+ àwọn ará Makedóníà tí wọ́n máa ń bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò.
2 A wọ ọkọ̀ òkun kan láti Adiramítíúmù tó fẹ́ lọ sí àwọn èbúté tó wà ní etíkun ìpínlẹ̀ Éṣíà, ọkọ̀ náà sì gbéra; Àrísítákọ́sì+ ará Makedóníà láti Tẹsalóníkà wà pẹ̀lú wa.