11 Tí a bá fúnrúgbìn nǹkan tẹ̀mí láàárín yín, ṣé ó pọ̀ jù ni tí a bá kórè nǹkan tara lọ́dọ̀ yín?+ 12 Tí àwọn míì bá ní ẹ̀tọ́ yìí lórí yín, ṣé èyí táwa ní kò ju tiwọn lọ fíìfíì ni? Síbẹ̀, a ò lo ẹ̀tọ́+ yìí, àmọ́ à ń fara da ohun gbogbo ká má bàa dènà ìhìn rere nípa Kristi lọ́nàkọnà.+