Orin ọpẹ́.
100 Ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ayé.+
 2 Ẹ fi ayọ̀ sin Jèhófà.+
Ẹ fi igbe ayọ̀ wá síwájú rẹ̀.
 3 Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run.+
Òun ló dá wa, tirẹ̀ la sì jẹ́.+
Àwa ni èèyàn rẹ̀ àti àgùntàn ibi ìjẹko rẹ̀.+
 4 Ẹ wọlé sínú àwọn ẹnubodè rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́,+
Sínú àwọn àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn.+
Ẹ fi ọpẹ́ fún un; ẹ yin orúkọ rẹ̀.+
 5 Nítorí Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+
Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé,
Òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.+