Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì JẸ́NẸ́SÍSÌ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé (1, 2) Àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ní ọjọ́ kìíní sí ìkẹfà (3-31) Ọjọ́ 1: ìmọ́lẹ̀; ọ̀sán àti òru (3-5) Ọjọ́ 2: òfúrufú (6-8) Ọjọ́ 3: ilẹ̀ àti ewéko (9-13) Ọjọ́ 4: àwọn orísun ìmọ́lẹ̀ tó wà lọ́run (14-19) Ọjọ́ 5: àwọn ẹja àtàwọn ẹyẹ (20-23) Ọjọ́ 6: àwọn ẹran orí ilẹ̀ àti èèyàn (24-31) 2 Ọlọ́run sinmi ní ọjọ́ keje (1-3) Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé (4) Ọkùnrin àti obìnrin nínú ọgbà Édẹ́nì (5-25) Ọlọ́run fi erùpẹ̀ mọ ọkùnrin (7) Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ (15-17) Ọlọ́run dá obìnrin (18-25) 3 Bí èèyàn ṣe kọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ (1-13) Irọ́ àkọ́kọ́ (4, 5) Jèhófà dá àwọn ọlọ̀tẹ̀ lẹ́jọ́ (14-24) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọmọ obìnrin náà (15) Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà jáde ní Édẹ́nì (23, 24) 4 Kéènì àti Ébẹ́lì (1-16) Àtọmọdọ́mọ Kéènì (17-24) Sẹ́ẹ̀tì àti Énọ́ṣì ọmọ rẹ̀ (25, 26) 5 Látorí Ádámù dórí Nóà (1-32) Ádámù bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin (4) Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn (21-24) 6 Àwọn ọmọ Ọlọ́run fẹ́ ìyàwó ní ayé (1-3) Wọ́n bí àwọn Néfílímù (4) Ìwà búburú èèyàn ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ (5-8) Ọlọ́run ní kí Nóà kan áàkì (9-16) Ọlọ́run kéde pé Ìkún Omi ń bọ̀ (17-22) 7 Wọ́n ń wọ inú áàkì (1-10) Ìkún Omi tó bo ayé (11-24) 8 Omi ń fà (1-14) Nóà rán àdàbà jáde (8-12) Wọ́n ń kúrò nínú áàkì (15-19) Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún ayé (20-22) 9 Àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún aráyé (1-7) Òfin nípa ẹ̀jẹ̀ (4-6) Májẹ̀mú tí Ọlọ́run fi òṣùmàrè dá (8-17) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn àtọmọdọ́mọ Nóà (18-29) 10 Àwọn orílẹ̀-èdè (1-32) Àtọmọdọ́mọ Jáfẹ́tì (2-5) Àtọmọdọ́mọ Hámù (6-20) Nímírọ́dù ta ko Jèhófà (8-12) Àtọmọdọ́mọ Ṣémù (21-31) 11 Ilé Gogoro Bábélì (1-4) Jèhófà da èdè rú (5-9) Látorí Ṣémù dórí Ábúrámù (10-32) Ìdílé Térà (27) Ábúrámù kúrò ní Úrì (31) 12 Ábúrámù kúrò ní Háránì lọ sí Kénáánì (1-9) Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúrámù (7) Ábúrámù àti Sáráì ní Íjíbítì (10-20) 13 Ábúrámù pa dà sí Kénáánì (1-4) Ábúrámù àti Lọ́ọ̀tì lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ (5-13) Ọlọ́run tún ṣèlérí fún Ábúrámù (14-18) 14 Ábúrámù gba Lọ́ọ̀tì sílẹ̀ (1-16) Melikisédékì súre fún Ábúrámù (17-24) 15 Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúrámù dá (1-21) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìjìyà fún 400 ọdún (13) Ọlọ́run tún ṣèlérí fún Ábúrámù (18-21) 16 Hágárì àti Íṣímáẹ́lì (1-16) 17 Ábúráhámù yóò di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè (1-8) Orúkọ Ábúrámù yí pa dà sí Ábúráhámù (5) Májẹ̀mú nípa ìdádọ̀dọ́ (9-14) Orúkọ Sáráì yí pa dà sí Sérà (15-17) Ọlọ́run ṣèlérí pé yóò bí Ísákì (18-27) 18 Áńgẹ́lì mẹ́ta wá sọ́dọ̀ Ábúráhámù (1-8) Ó ṣèlérí pé Sérà yóò bímọ; Sérà rẹ́rìn-ín (9-15) Ábúráhámù ń bẹ̀bẹ̀ torí Sódómù (16-33) 19 Àwọn áńgẹ́lì wá sọ́dọ̀ Lọ́ọ̀tì (1-11) Wọ́n rọ Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ pé kí wọ́n kúrò nílùú (12-22) Sódómù àti Gòmórà pa run (23-29) Ìyàwó Lọ́ọ̀tì di ọwọ̀n iyọ̀ (26) Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ (30-38) Ibi tí àwọn ọmọ Móábù àti Ámónì ti wá (37, 38) 20 Ọlọ́run gba Sérà lọ́wọ́ Ábímélékì (1-18) 21 Wọ́n bí Ísákì (1-7) Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́ (8, 9) Ó lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ (10-21) Ábúráhámù bá Ábímélékì dá májẹ̀mú (22-34) 22 Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kó fi Ísákì rúbọ (1-19) Àwọn èèyàn yóò rí ìbùkún gbà torí àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù (15-18) Ìdílé Rèbékà (20-24) 23 Ikú Sérà àti ibi ìsìnkú (1-20) 24 Wọ́n bá Ísákì wá ìyàwó (1-58) Rèbékà lọ bá Ísákì (59-67) 25 Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì (1-6) Ábúráhámù kú (7-11) Àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì (12-18) Wọ́n bí Jékọ́bù àti Ísọ̀ (19-26) Ísọ̀ ta ogún ìbí rẹ̀ (27-34) 26 Ísákì àti Rèbékà ní Gérárì (1-11) Ọlọ́run fìdí ìlérí tó ṣe fún Ísákì múlẹ̀ (3-5) Wọ́n ń jà torí kànga (12-25) Ísákì àti Ábímélékì dá májẹ̀mú (26-33) Àwọn ọmọ Hétì méjì tí Ísọ̀ fẹ́ (34, 35) 27 Jékọ́bù gba ìbùkún lọ́dọ̀ Ísákì (1-29) Ísọ̀ fẹ́ gba ìbùkún àmọ́ kò ronú pìwà dà (30-40) Ísọ̀ di Jékọ́bù sínú (41-46) 28 Ísákì ní kí Jékọ́bù lọ sí Padani-árámù (1-9) Àlá tí Jékọ́bù lá ní Bẹ́tẹ́lì (10-22) Ọlọ́run tún ìlérí rẹ̀ sọ fún Jékọ́bù (13-15) 29 Jékọ́bù pàdé Réṣẹ́lì (1-14) Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì (15-20) Jékọ́bù fẹ́ Líà àti Réṣẹ́lì (21-29) Àwọn ọmọ mẹ́rin tí Líà bí fún Jékọ́bù: Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà (30-35) 30 Bílíhà bí Dánì àti Náfútálì (1-8) Sílípà bí Gádì àti Áṣérì (9-13) Líà bí Ísákà àti Sébúlúnì (14-21) Réṣẹ́lì bí Jósẹ́fù (22-24) Agbo ẹran Jékọ́bù ń pọ̀ sí i (25-43) 31 Jékọ́bù yọ́ lọ sí Kénáánì (1-18) Lábánì lé Jékọ́bù bá (19-35) Jékọ́bù àti Lábánì dá májẹ̀mú (36-55) 32 Àwọn áńgẹ́lì pàdé Jékọ́bù (1, 2) Jékọ́bù múra láti pàdé Ísọ̀ (3-23) Jékọ́bù bá áńgẹ́lì kan jìjàkadì (24-32) Orúkọ Jékọ́bù yí pa dà di Ísírẹ́lì (28) 33 Jékọ́bù lọ pàdé Ísọ̀ (1-16) Jékọ́bù lọ sí Ṣékémù (17-20) 34 Ṣékémù fipá bá Dínà lò pọ̀ (1-12) Àwọn ọmọ Jékọ́bù ṣẹ̀tàn (13-31) 35 Jékọ́bù mú àwọn ọlọ́run àjèjì kúrò (1-4) Jékọ́bù pa dà sí Bẹ́tẹ́lì (5-15) Réṣẹ́lì bí Bẹ́ńjámínì; Réṣẹ́lì kú (16-20) Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (21-26) Ísákì kú (27-29) 36 Àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ (1-30) Àwọn ọba àti àwọn séríkí Édómù (31-43) 37 Àwọn àlá Jósẹ́fù (1-11) Jósẹ́fù àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ òjòwú (12-24) Wọ́n ta Jósẹ́fù sí oko ẹrú (25-36) 38 Júdà àti Támárì (1-30) 39 Jósẹ́fù ní ilé Pọ́tífárì (1-6) Jósẹ́fù ò gbà fún ìyàwó Pọ́tífárì (7-20) Jósẹ́fù ṣẹ̀wọ̀n (21-23) 40 Jósẹ́fù túmọ̀ àlá àwọn ẹlẹ́wọ̀n (1-19) “Ọlọ́run ló ni ìtúmọ̀” (8) Àsè ọjọ́ ìbí Fáráò (20-23) 41 Jósẹ́fù túmọ̀ àlá Fáráò (1-36) Fáráò gbé Jósẹ́fù ga (37-46a) Jósẹ́fù ń bójú tó ọ̀rọ̀ oúnjẹ (46b-57) 42 Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì (1-4) Jósẹ́fù rí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó sì dán wọn wò (5-25) Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ Jékọ́bù nílé (26-38) 43 Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù pa dà sí Íjíbítì; pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì (1-14) Jósẹ́fù tún rí àwọn arákùnrin rẹ̀ (15-23) Jósẹ́fù jẹun pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ (24-34) 44 Wọ́n rí ife fàdákà Jósẹ́fù nínú àpò Bẹ́ńjámínì (1-17) Júdà bá Bẹ́ńjámínì bẹ̀bẹ̀ (18-34) 45 Jósẹ́fù jẹ́ kí wọ́n mọ òun (1-15) Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù pa dà lọ mú Jékọ́bù wá (16-28) 46 Jékọ́bù àti agbo ilé rẹ̀ kó lọ sí Íjíbítì (1-7) Orúkọ àwọn tó ń kó lọ sí Íjíbítì (8-27) Jósẹ́fù lọ pàdé Jékọ́bù ní Góṣénì (28-34) 47 Jékọ́bù lọ sọ́dọ̀ Fáráò (1-12) Jósẹ́fù fi ọgbọ́n darí nǹkan (13-26) Ísírẹ́lì ń gbé ní Góṣénì (27-31) 48 Jékọ́bù súre fún àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù méjèèjì (1-12) Ìbùkún Éfúrémù ló pọ̀ jù (13-22) 49 Jékọ́bù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú (1-28) Ṣílò yóò wá láti Júdà (10) Ìtọ́ni Jékọ́bù nípa ìsìnkú rẹ̀ (29-32) Jékọ́bù kú (33) 50 Jósẹ́fù sin Jékọ́bù sí Kénáánì (1-14) Jósẹ́fù fi dá àwọn arákùnrin rẹ̀ lójú pé òun ti dárí jì wọ́n (15-21) Jósẹ́fù darúgbó, ó sì kú (22-26) Àṣẹ tí Jósẹ́fù pa nípa àwọn egungun rẹ̀ (25)