Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Àwọn Ọba 1 ÀWỌN ỌBA OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Dáfídì àti Ábíṣágì (1-4) Ádóníjà wá ọ̀nà láti gorí ìtẹ́ (5-10) Nátánì àti Bátí-ṣébà gbé ìgbésẹ̀ (11-27) Dáfídì pàṣẹ pé kí wọ́n fòróró yan Sólómọ́nì (28-40) Ádóníjà sá lọ sí ibi pẹpẹ (41-53) 2 Dáfídì fún Sólómọ́nì ní ìtọ́ni (1-9) Dáfídì kú; Sólómọ́nì gorí ìtẹ́ (10-12) Ọ̀tẹ̀ Ádóníjà yọrí sí ikú fún un (13-25) Ọba lé Ábíátárì kúrò lẹ́nu iṣẹ́; ó pa Jóábù (26-35) Wọ́n pa Ṣíméì (36-46) 3 Sólómọ́nì fẹ́ ọmọ Fáráò (1-3) Jèhófà fara han Sólómọ́nì lójú àlá (4-15) Sólómọ́nì béèrè ọgbọ́n (7-9) Sólómọ́nì dá ẹjọ́ láàárín àwọn ìyá méjì (16-28) 4 Ìjọba Sólómọ́nì (1-19) Àwọn èèyàn láásìkí nígbà àkóso Sólómọ́nì (20-28) Àwọn èèyàn wà láàbò lábẹ́ àjàrà àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ (25) Ọgbọ́n Sólómọ́nì àti àwọn òwe rẹ̀ (29-34) 5 Ọba Hírámù pèsè àwọn ohun èlò ìkọ́lé (1-12) Àwọn tí Sólómọ́nì ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun (13-18) 6 Sólómọ́nì kọ́ tẹ́ńpìlì (1-38) Yàrá inú lọ́hùn-ún (19-22) Àwọn kérúbù (23-28) Àwọn ohun gbígbẹ́, àwọn ilẹ̀kùn, àgbàlá inú (29-36) Iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì parí ní nǹkan bí ọdún méje (37, 38) 7 Ààfin Sólómọ́nì (1-12) Hírámù tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ran Sólómọ́nì lọ́wọ́ (13-47) Àwọn òpó bàbà méjì (15-22) Òkun tí a fi irin rọ (23-26) Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́wàá àti àwọn bàsíà bàbà (27-39) Wọ́n parí àwọn ohun èlò tí wọ́n fi wúrà ṣe (48-51) 8 Wọ́n gbé Àpótí wọnú tẹ́ńpìlì (1-13) Sólómọ́nì bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ (14-21) Àdúrà tí Sólómọ́nì fi ya tẹ́ńpìlì sí mímọ́ (22-53) Sólómọ́nì súre fún àwọn èèyàn náà (54-61) Àwọn ẹbọ àti àjọyọ̀ ìyàsímímọ́ (62-66) 9 Jèhófà tún fara han Sólómọ́nì (1-9) Ẹ̀bùn tí Sólómọ́nì fún Ọba Hírámù (10-14) Oríṣiríṣi iṣẹ́ ìkọ́lé tí Sólómọ́nì ṣe (15-28) 10 Ọbabìnrin Ṣébà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Sólómọ́nì (1-13) Ọrọ̀ rẹpẹtẹ tí Sólómọ́nì ní (14-29) 11 Àwọn ìyàwó Sólómọ́nì yí i lọ́kàn pa dà (1-13) Àwọn alátakò dìde sí Sólómọ́nì (14-25) Ọlọ́run ṣèlérí ẹ̀yà mẹ́wàá fún Jèróbóámù (26-40) Sólómọ́nì kú; wọ́n fi Rèhóbóámù jọba (41-43) 12 Ìdáhùn líle tí Rèhóbóámù fún àwọn èèyàn (1-15) Ẹ̀yà mẹ́wàá yapa (16-19) Wọ́n fi Jèróbóámù jẹ ọba Ísírẹ́lì (20) Ọlọ́run ní kí Rèhóbóámù má ṣe bá Ísírẹ́lì jà (21-24) Ìjọsìn ère ọmọ màlúù tí Jèróbóámù gbé kalẹ̀ (25-33) 13 Àsọtẹ́lẹ̀ sórí pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì (1-10) Pẹpẹ là sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ (5) Èèyàn Ọlọ́run ṣàìgbọràn (11-34) 14 Àsọtẹ́lẹ̀ tí Áhíjà sọ sórí Jèróbóámù (1-20) Rèhóbóámù ṣàkóso lórí Júdà (21-31) Ṣíṣákì ya wọ Jerúsálẹ́mù (25, 26) 15 Ábíjámù di ọba Júdà (1-8) Ásà di ọba Júdà (9-24) Nádábù di ọba Ísírẹ́lì (25-32) Bááṣà di ọba Ísírẹ́lì (33, 34) 16 Ìdájọ́ Jèhófà lórí Bááṣà (1-7) Élà di ọba Ísírẹ́lì (8-14) Símírì di ọba Ísírẹ́lì (15-20) Ómírì di ọba Ísírẹ́lì (21-28) Áhábù di ọba Ísírẹ́lì (29-33) Híélì tún Jẹ́ríkò kọ́ (34) 17 Wòlíì Èlíjà sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀dá máa wà (1) Àwọn ẹyẹ ìwò bọ́ Èlíjà (2-7) Èlíjà dé sọ́dọ̀ opó kan ní Sáréfátì (8-16) Ọmọ opó náà kú, ó sì jíǹde (17-24) 18 Èlíjà pàdé Ọbadáyà àti Áhábù (1-18) Èlíjà àti àwọn wòlíì Báálì ní Kámẹ́lì (19-40) ‘Wọ́n ń ṣiyèméjì’ (21) Ọ̀dá ọlọ́dún mẹ́ta àti ààbọ̀ dópin (41-46) 19 Èlíjà sá lọ nítorí ìbínú Jésíbẹ́lì (1-8) Jèhófà fara han Èlíjà ní Hórébù (9-14) Ọlọ́run ní kí Èlíjà fòróró yan Hásáẹ́lì, Jéhù àti Èlíṣà (15-18) Ọlọ́run yan Èlíṣà sí ipò Èlíjà (19-21) 20 Àwọn ará Síríà gbógun ti Áhábù (1-12) Áhábù ṣẹ́gun àwọn ará Síríà (13-34) Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Áhábù (35-43) 21 Ọgbà àjàrà Nábótì wọ Áhábù lójú (1-4) Jésíbẹ́lì fa ikú Nábótì (5-16) Iṣẹ́ tí Èlíjà jẹ́ fún Áhábù (17-26) Áhábù rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ (27-29) 22 Àjọṣe Jèhóṣáfátì àti Áhábù (1-12) Mikáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣẹ́gun Áhábù (13-28) Ẹ̀mí tó máa tan Áhábù (21, 22) Wọ́n pa Áhábù ní Ramoti-gílíádì (29-40) Jèhóṣáfátì ṣàkóso lórí Júdà (41-50) Ahasáyà di ọba Ísírẹ́lì (51-53)