Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kíróníkà 1 KÍRÓNÍKÀ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Látọ̀dọ̀ Ádámù dé ọ̀dọ̀ Ábúráhámù (1-27) Àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù (28-37) Àwọn ọmọ Édómù àti àwọn ọba wọn pẹ̀lú àwọn Séríkí wọn (38-54) 2 Àwọn ọmọ 12 tí Ísírẹ́lì bí (1, 2) Àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà (3-55) 3 Àwọn àtọmọdọ́mọ Dáfídì (1-9) Àwọn ọmọ tó wá láti ìdílé ọba Dáfídì (10-24) 4 Àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà tó ṣẹ́ kù (1-23) Jábésì àti àdúrà rẹ̀ (9, 10) Àwọn àtọmọdọ́mọ Síméónì (24-43) 5 Àwọn àtọmọdọ́mọ Rúbẹ́nì (1-10) Àwọn àtọmọdọ́mọ Gádì (11-17) Wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọmọ Hágárì (18-22) Ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè (23-26) 6 Àwọn àtọmọdọ́mọ Léfì (1-30) Àwọn akọrin inú tẹ́ńpìlì (31-47) Àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì (48-53) Àwọn ibi tí àwọn ọmọ Léfì gbé (54-81) 7 Àwọn àtọmọdọ́mọ Ísákà (1-5), ti Bẹ́ńjámínì (6-12), ti Náfútálì (13), ti Mánásè (14-19), ti Éfúrémù (20-29) àti ti Áṣérì (30-40) 8 Àwọn àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì (1-40) Ìlà ìdílé Sọ́ọ̀lù (33-40) 9 Àwọn orúkọ tó wà nínú àkọsílẹ̀ ìlà ìdílé lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn (1-34) A tún orúkọ àwọn tó wà nínú ìdílé Sọ́ọ̀lù kọ (35-44) 10 Ikú Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ (1-14) 11 Gbogbo Ísírẹ́lì fòróró yan Dáfídì ṣe ọba (1-3) Dáfídì gba Síónì (4-9) Àwọn jagunjagun Dáfídì tó lákíkanjú (10-47) 12 Àwọn tó ń ti ìjọba Dáfídì lẹ́yìn (1-40) 13 Wọ́n gbé Àpótí wá láti Kiriati-jéárímù (1-14) Ọlọ́run pa Úsà (9, 10) 14 Ọlọ́run fìdí ìjọba Dáfídì múlẹ̀ (1, 2) Ìdílé Dáfídì (3-7) Wọ́n ṣẹ́gun àwọn Filísínì (8-17) 15 Àwọn ọmọ Léfì gbé Àpótí lọ sí Jerúsálẹ́mù (1-29) Míkálì pẹ̀gàn Dáfídì (29) 16 Wọ́n gbé Àpótí náà sínú àgọ́ (1-6) Orin ìdúpẹ́ tí Dáfídì kọ (7-36) “Jèhófà ti di Ọba!” (31) Iṣẹ́ ìsìn níwájú Àpótí náà (37-43) 17 Dáfídì kò ní kọ́ tẹ́ńpìlì (1-6) Ọlọ́run bá Dáfídì dá májẹ̀mú ìjọba (7-15) Àdúrà ìdúpẹ́ tí Dáfídì gbà (16-27) 18 Àwọn tí Dáfídì ṣẹ́gun (1-13) Ìjọba Dáfídì (14-17) 19 Àwọn ọmọ Ámónì dójú ti àwọn òjíṣẹ́ Dáfídì (1-5) Wọ́n ṣẹ́gun Ámónì àti Síríà (6-19) 20 Wọ́n gba Rábà (1-3) Wọ́n pa àwọn òmìrán Filísínì (4-8) 21 Ìkànìyàn tí kò bófin mu tí Dáfídì ṣe (1-6) Ìyà tí Jèhófà fi jẹ wọ́n (7-17) Dáfídì mọ pẹpẹ (18-30) 22 Ètò tí Dáfídì ṣe sílẹ̀ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì (1-5) Dáfídì sọ ohun tí Sólómọ́nì máa ṣe fún un (6-16) Ó ní kí àwọn ìjòyè ran Sólómọ́nì lọ́wọ́ (17-19) 23 Dáfídì ṣètò àwọn ọmọ Léfì (1-32) A ya Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́tọ̀ (13) 24 Dáfídì ṣètò àwọn àlùfáà sí àwùjọ 24 (1-19) Àwọn iṣẹ́ míì tí a fún àwọn ọmọ Léfì (20-31) 25 Àwọn olórin àti àwọn akọrin ilé Ọlọ́run (1-31) 26 A pín àwọn aṣọ́bodè sí àwùjọ-àwùjọ (1-19) Àwọn olùtọ́jú ibi ìṣúra àti àwọn òṣìṣẹ́ míì (20-32) 27 Àwọn aláṣẹ nídìí iṣẹ́ ọba (1-34) 28 Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ lórí kíkọ́ tẹ́ńpìlì (1-8) Ó sọ ohun tí Sólómọ́nì máa ṣe; ó fún un ní àwòrán ìkọ́lé (9-21) 29 Ọrẹ fún tẹ́ńpìlì (1-9) Àdúrà Dáfídì (10-19) Inú àwọn èèyàn dùn; ìjọba Sólómọ́nì (20-25) Ikú Dáfídì (26-30)