Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà 2 KÍRÓNÍKÀ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Sólómọ́nì béèrè ọgbọ́n (1-12) Ọrọ̀ Sólómọ́nì (13-17) 2 Ìmúrasílẹ̀ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì (1-18) 3 Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì (1-7) Ibi Mímọ́ Jù Lọ (8-14) Àwọn òpó bàbà méjì (15-17) 4 Pẹpẹ, Òkun àti àwọn bàsíà (1-6) Ọ̀pá fìtílà, tábìlì àti àgbàlá (7-11a) Bí wọ́n ṣe parí àwọn ohun tó wà nínú tẹ́ńpìlì (11b-22) 5 Ìmúrasílẹ̀ ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì (1-14) Wọ́n gbé Àpótí wọnú tẹ́ńpìlì (2-10) 6 Sólómọ́nì bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ (1-11) Àdúrà tí Sólómọ́nì fi ṣí tẹ́ńpìlì (12-42) 7 Ògo Jèhófà kún inú tẹ́ńpìlì (1-3) Ayẹyẹ ìṣílé (4-10) Jèhófà fara han Sólómọ́nì (11-22) 8 Àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé míì tí Sólómọ́nì ṣe (1-11) Ó ṣètò bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì (12-16) Àwọn ọkọ̀ òkun Sólómọ́nì (17, 18) 9 Ọbabìnrin Ṣébà wá sọ́dọ̀ Sólómọ́nì (1-12) Ọrọ̀ Sólómọ́nì (13-28) Ikú Sólómọ́nì (29-31) 10 Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí Rèhóbóámù (1-19) 11 Ìjọba Rèhóbóámù (1-12) Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin lọ sí Júdà (13-17) Ìdílé Rèhóbóámù (18-23) 12 Ṣíṣákì gbógun ti Jerúsálẹ́mù (1-12) Òpin ìjọba Rèhóbóámù (13-16) 13 Ábíjà di ọba Júdà (1-22) Ábíjà ṣẹ́gun Jèróbóámù (3-20) 14 Ikú Ábíjà (1) Ásà di ọba Júdà (2-8) Ásà ṣẹ́gun 1,000,000 àwọn ará Etiópíà (9-15) 15 Àwọn àtúnṣe tí Ásà ṣe (1-19) 16 Àdéhùn tí Ásà bá Síríà ṣe (1-6) Hánáánì bá Ásà wí (7-10) Ikú Ásà (11-14) 17 Jèhóṣáfátì di ọba Júdà (1-6) Wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn káàkiri (7-9) Ẹgbẹ́ ológun Jèhóṣáfátì (10-19) 18 Jèhóṣáfátì dara pọ̀ mọ́ Áhábù (1-11) Mikáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọn ò ní ṣẹ́gun (12-27) Wọ́n pa Áhábù ní Ramoti-gílíádì (28-34) 19 Jéhù bá Jèhóṣáfátì wí (1-3) Àwọn àtúnṣe tí Jèhóṣáfátì ṣe (4-11) 20 Àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Júdà ká gbógun tì í (1-4) Jèhóṣáfátì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ (5-13) Ìdáhùn tí Jèhófà fún un (14-19) Ọlọ́run gba Júdà là lọ́nà ìyanu (20-30) Òpin ìjọba Jèhóṣáfátì (31-37) 21 Jèhórámù di ọba Júdà (1-11) Èlíjà kọ̀wé ránṣẹ́ (12-15) Ìgbẹ̀yìn Jèhórámù kò dáa (16-20) 22 Ahasáyà di ọba Júdà (1-9) Ataláyà fipá gbàjọba (10-12) 23 Jèhóádà dá sí ọ̀rọ̀ náà; wọ́n fi Jèhóáṣì jọba (1-11) Wọ́n pa Ataláyà (12-15) Àwọn àtúnṣe tí Jèhóádà ṣe (16-21) 24 Ìjọba Jèhóáṣì (1-3) Jèhóáṣì tún tẹ́ńpìlì ṣe (4-14) Jèhóáṣì di apẹ̀yìndà (15-22) Wọ́n pa Jèhóáṣì (23-27) 25 Amasááyà di ọba Júdà (1-4) Ogun ja Édómù (5-13) Amasááyà bọ òrìṣà (14-16) Ogun ja Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì (17-24) Ikú Amasááyà (25-28) 26 Ùsáyà di ọba Júdà (1-5) Ohun tí ẹgbẹ́ ológun Ùsáyà gbé ṣe (6-15) Ùsáyà agbéraga di adẹ́tẹ̀ (16-21) Ikú Ùsáyà (22, 23) 27 Jótámù di ọba Júdà (1-9) 28 Áhásì di ọba Júdà (1-4) Síríà àti Ísírẹ́lì ṣẹ́gun rẹ̀ (5-8) Ódédì kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì (9-15) Ọlọ́run rẹ Júdà wálẹ̀ (16-19) Áhásì bọ̀rìṣà; ikú rẹ̀ (20-27) 29 Hẹsikáyà di ọba Júdà (1, 2) Àwọn àtúnṣe tí Hẹsikáyà ṣe (3-11) Ó fọ tẹ́ńpìlì mọ́ (12-19) Ó mú iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ (20-36) 30 Hẹsikáyà ṣe Ìrékọjá (1-27) 31 Hẹsikáyà mú ìbọ̀rìṣà kúrò (1) Àwọn èèyàn ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì lẹ́yìn bó ṣe yẹ (2-21) 32 Senakérúbù gbógun ti Jerúsálẹ́mù (1-8) Senakérúbù pẹ̀gàn Jèhófà (9-19) Áńgẹ́lì pa àwọn ọmọ ogun Ásíríà (20-23) Àìsàn tó ṣe Hẹsikáyà àti ìgbéraga rẹ̀ (24-26) Àwọn àṣeyọrí Hẹsikáyà àti ikú rẹ̀ (27-33) 33 Mánásè di ọba Júdà (1-9) Mánásè ronú pìwà dà ìwà búburú rẹ̀ (10-17) Ikú Mánásè (18-20) Ámọ́nì di ọba Júdà (21-25) 34 Jòsáyà di ọba Júdà (1, 2) Àwọn àtúnṣe tí Jòsáyà ṣe (3-13) Wọ́n rí Ìwé Òfin (14-21) Àsọtẹ́lẹ̀ Húlídà nípa àjálù (22-28) Jòsáyà ka ìwé náà fún àwọn èèyàn (29-33) 35 Jòsáyà ṣètò Ìrékọjá ńlá kan (1-19) Fáráò Nékò pa Jòsáyà (20-27) 36 Jèhóáhásì di ọba Júdà (1-3) Jèhóákímù di ọba Júdà (4-8) Jèhóákínì di ọba Júdà (9, 10) Sedekáyà di ọba Júdà (11-14) Ìparun Jerúsálẹ́mù (15-21) Àṣẹ tí Kírúsì pa pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì kọ́ (22, 23)