Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nehemáyà NEHEMÁYÀ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìròyìn wá láti Jerúsálẹ́mù (1-3) Àdúrà Nehemáyà (4-11) 2 Ọba rán Nehemáyà sí Jerúsálẹ́mù (1-10) Nehemáyà yẹ ògiri ìlú náà wò (11-20) 3 Wọ́n tún ògiri náà kọ́ (1-32) 4 Àtakò kò dá iṣẹ́ náà dúró (1-14) Àwọn òṣìṣẹ́ tó mú ohun ìjà dání ń bá iṣẹ́ ìkọ́lé náà lọ (15-23) 5 Nehemáyà fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ (1-13) Nehemáyà kò mọ tara rẹ̀ nìkan (14-19) 6 Àtakò lórí iṣẹ́ àtúnkọ́ náà kò dáwọ́ dúró (1-14) Ọjọ́ 52 ni wọ́n fi parí ògiri náà (15-19) 7 Àwọn ẹnubodè ìlú àti àwọn aṣọ́bodè (1-4) Orúkọ àwọn tó dé láti ìgbèkùn (5-69) Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì (46-56) Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì (57-60) Ọrẹ tí wọ́n ṣe fún iṣẹ́ náà (70-73) 8 Wọ́n ka ìwé Òfin, wọ́n sì ṣàlàyé rẹ̀ fáwọn èèyàn (1-12) Wọ́n ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà (13-18) 9 Àwọn èèyàn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn (1-38) Jèhófà, Ọlọ́run tó ń dárí jini (17) 10 Àwọn èèyàn náà gbà láti máa pa Òfin mọ́ (1-39) ‘A kò ní pa ilé Ọlọ́run wa tì’ (39) 11 Àwọn èèyàn pa dà wá ń gbé Jerúsálẹ́mù (1-36) 12 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì (1-26) Ayẹyẹ ṣíṣí ògiri ìlú náà (27-43) Wọ́n ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì (44-47) 13 Àwọn àtúnṣe míì tí Nehemáyà ṣe (1-31) Wọ́n ní kí wọ́n mú ìdá mẹ́wàá wá (10-13) Wọn ò gbọ́dọ̀ sọ Sábáàtì di aláìmọ́ (15-22) Ó bẹnu àtẹ́ lu bí àwọn àtàwọn ọmọ ilẹ̀ míì ṣe ń fẹ́ra wọn (23-28)