Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóòbù JÓÒBÙ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìwà títọ́ Jóòbù àti ọrọ̀ rẹ̀ (1-5) Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù (6-12) Jóòbù pàdánù ohun ìní rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ (13-19) Jóòbù ò dá Ọlọ́run lẹ́bi (20-22) 2 Sátánì tún fẹ̀sùn kan Jóòbù (1-5) Ọlọ́run fàyè gba Sátánì pé kó kọlu ara Jóòbù (6-8) Ìyàwó Jóòbù sọ pé: “Sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, kí o sì kú!” (9, 10) Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta dé (11-13) 3 Jóòbù ń kábàámọ̀ ọjọ́ tí wọ́n bí i (1-26) Ó béèrè ohun tó fa ìyà òun (20, 21) 4 Ọ̀rọ̀ tí Élífásì kọ́kọ́ sọ (1-21) Ó bẹnu àtẹ́ lu ìwà títọ́ Jóòbù (7, 8) Ó sọ ohun tí ẹ̀mí kan bá a sọ (12-17) ‘Ọlọ́run ò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀’ (18) 5 Élífásì ń bá ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ sọ lọ (1-27) ‘Ọlọ́run ń mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wọn’ (13) ‘Kí Jóòbù má ṣe kọ ìbáwí Ọlọ́run’ (17) 6 Jóòbù fèsì (1-30) Ó sọ pé òun ò jẹ̀bi bí òun ṣe ń ké jáde (2-6) Ọ̀dàlẹ̀ ni àwọn tó ń tù ú nínú (15-18) “Òótọ́ ọ̀rọ̀ kì í dunni!” (25) 7 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-21) Ìgbésí ayé dà bí iṣẹ́ àṣekára tó pọn dandan (1, 2) “Kí ló dé tí o dájú sọ mí?” (20) 8 Ọ̀rọ̀ tí Bílídádì kọ́kọ́ sọ (1-22) Ó sọ pé àwọn ọmọ Jóòbù ti ṣẹ̀ (4) ‘Tí o bá mọ́, Ọlọ́run máa dáàbò bò ọ́’ (6) Ó sọ pé Jóòbù kò mọ Ọlọ́run (13) 9 Jóòbù fèsì (1-35) Ẹni kíkú ò lè bá Ọlọ́run fà á (2-4) ‘Ọlọ́run ń ṣe àwọn ohun àwámáridìí’ (10) Èèyàn ò lè bá Ọlọ́run jiyàn (32) 10 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-22) ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run fi ń bá mi jà?’ (2) Ọlọ́run yàtọ̀ sí Jóòbù tó jẹ́ ẹni kíkú (4-12) ‘Kí ara tù mí díẹ̀’ (20) 11 Ọ̀rọ̀ tí Sófárì kọ́kọ́ sọ (1-20) Ó sọ pé ọ̀rọ̀ Jóòbù kò nítumọ̀ (2, 3) Ó ní kí Jóòbù má ṣe ohun tí kò dáa (14) 12 Jóòbù fèsì (1-25) “Mi ò kéré sí yín” (3) ‘Mo wá di ẹni tí wọ́n fi ń ṣe ẹlẹ́yà’ (4) ‘Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run’ (13) Ọlọ́run ga ju àwọn adájọ́ àti ọba lọ (17, 18) 13 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-28) ‘Màá kúkú bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀’ (3) ‘Oníṣègùn tí kò wúlò ni yín’ (4) “Mo mọ̀ pé èmi ni mo jàre” (18) Ó fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi ka òun sí ọ̀tá (24) 14 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-22) Èèyàn jẹ́ ọlọ́jọ́ kúkúrú, wàhálà tó bá a pọ̀ gan-an (1) “Ìrètí wà fún igi pàápàá” (7) “Ká ní o lè fi mí pa mọ́ sínú Isà Òkú ni” (13) “Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè?” (14) Ó máa wu Ọlọ́run gan-an pé kó rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ (15) 15 Ìgbà kejì tí Élífásì sọ̀rọ̀ (1-35) Ó sọ pé Jóòbù ò bẹ̀rù Ọlọ́run (4) Ó ní Jóòbù ń gbéra ga (7-9) ‘Ọlọ́run ò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀’ (15) ‘Ẹni burúkú ló ń jìyà’ (20-24) 16 Jóòbù fèsì (1-22) ‘Olùtùnú tó ń dani láàmú ni yín!’ (2) Ó ní Ọlọ́run dájú sọ òun (12) 17 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-16) “Àwọn tó ń fini ṣe yẹ̀yẹ́ yí mi ká” (2) “Ó ti sọ mí di ẹni ẹ̀gàn” (6) “Isà Òkú máa di ilé mi” (13) 18 Ìgbà kejì tí Bílídádì sọ̀rọ̀ (1-21) Ó sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (5-20) Ó ń dọ́gbọ́n sọ pé Jóòbù kò mọ Ọlọ́run (21) 19 Jóòbù fèsì (1-29) Ó kọ ìbáwí àwọn “ọ̀rẹ́” rẹ̀ (1-6) Ó ní wọ́n pa òun tì (13-19) “Olùràpadà mi wà láàyè”(25) 20 Ìgbà kejì tí Sófárì sọ̀rọ̀ (1-29) Ó wò ó pé Jóòbù sọ̀rọ̀ sí òun (2, 3) Ó dọ́gbọ́n sọ pé ẹni burúkú ni Jóòbù (5) Ó ní ẹ̀ṣẹ̀ ń dùn mọ́ Jóòbù (12, 13) 21 Jóòbù fèsì (1-34) ‘Kí ló dé tí nǹkan ń lọ dáadáa fún ẹni burúkú?’ (7-13) Ó sọ èrò ibi tó wà lọ́kàn àwọn tó ń tù ú nínú (27-34) 22 Ìgbà kẹta tí Élífásì sọ̀rọ̀ (1-30) ‘Ṣé èèyàn lè ṣe Ọlọ́run láǹfààní?’ (2, 3) Ó fẹ̀sùn kan Jóòbù pé ó ń jẹ èrè tí kò tọ́, ó sì ń rẹ́ni jẹ (6-9) ‘Pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, wàá sì pa dà sí àyè rẹ’ (23) 23 Jóòbù fèsì (1-17) Ó fẹ́ ro ẹjọ́ rẹ̀ níwájú Ọlọ́run (1-7) Ó ní òun ò rí Ọlọ́run (8, 9) “Mò ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ ṣáá, mi ò sì yà kúrò níbẹ̀” (11) 24 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-25) ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run ò yan àkókò?’ (1) Ó ní Ọlọ́run fàyè gba ìwà ibi (12) Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ fẹ́ràn òkùnkùn (13-17) 25 Ìgbà kẹta tí Bílídádì sọ̀rọ̀ (1-6) ‘Báwo ni èèyàn ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run?’ (4) Ó ní ìwà títọ́ èèyàn kò já mọ́ nǹkan kan (5, 6) 26 Jóòbù fèsì (1-14) “Wo bí o ṣe ran ẹni tí kò lágbára lọ́wọ́!” (1-4) ‘Ọlọ́run fi ayé rọ̀ sórí òfo’ (7) ‘Bíńtín lára àwọn ọ̀nà Ọlọ́run’ (14) 27 Jóòbù pinnu pé òun á máa pa ìwà títọ́ òun mọ́ (1-23) “Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀” (5) Ẹni tí kò mọ Ọlọ́run kò nírètí (8) “Kí ló dé tí ọ̀rọ̀ yín kò nítumọ̀ rárá?” (12) Ohunkóhun ò ní ṣẹ́ kù fáwọn ẹni burúkú (13-23) 28 Jóòbù fi àwọn ìṣúra ayé wé ọgbọ́n (1-28) Bí èèyàn ṣe ń sapá láti wa kùsà (1-11) Ọgbọ́n níye lórí ju péálì lọ (18) Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọgbọ́n tòótọ́ (28) 29 Jóòbù rántí bí nǹkan ṣe ń dùn kí àdánwò tó dé (1-25) Ó jẹ́ èèyàn pàtàkì ní ẹnubodè (7-10) Bó ṣe máa ń fi òdodo ṣèdájọ́ (11-17) Gbogbo èèyàn máa ń gbọ́ ìmọ̀ràn rẹ̀ (21-23) 30 Jóòbù sọ bí nǹkan ṣe wá yí pa dà fún òun (1-31) Àwọn tí kò ní láárí ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ (1-15) Ó jọ pé Ọlọ́run kò ràn án lọ́wọ́ (20, 21) “Awọ ara mi ti dúdú” (30) 31 Jóòbù gbèjà ìwà títọ́ rẹ̀ (1-40) “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú” (1) Ó ní kí Ọlọ́run wọn òun (6) Kì í ṣe alágbèrè (9-12) Kò nífẹ̀ẹ́ owó (24, 25) Kì í ṣe abọ̀rìṣà (26-28) 32 Élíhù tó kéré sí wọn dá sí ọ̀rọ̀ náà (1-22) Ó bínú sí Jóòbù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ (2, 3) Kò tètè sọ̀rọ̀ torí ó bọ̀wọ̀ fún wọn (6, 7) Ọjọ́ orí nìkan kọ́ ló ń sọ èèyàn di ọlọ́gbọ́n (9) Ó wu Élíhù pé kó sọ̀rọ̀ (18-20) 33 Élíhù bá Jóòbù wí torí ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀ (1-33) Ó rí ìràpadà (24) Kó pa dà ní okun ìgbà ọ̀dọ́ (25) 34 Élíhù gbé ìdájọ́ àtàwọn ọ̀nà Ọlọ́run ga (1-37) Jóòbù ní Ọlọ́run fi ìdájọ́ òdodo du òun (5) Ọlọ́run tòótọ́ kì í hùwà burúkú (10) Jóòbù ò ní ìmọ̀ (35) 35 Élíhù sọ àwọn èrò tí kò tọ́ tí Jóòbù ní (1-16) Jóòbù sọ pé òdodo òun ju ti Ọlọ́run lọ (2) Ọlọ́run ga lọ́la, ẹ̀ṣẹ̀ kò sì lè ṣe nǹkan fún un (5, 6) Kí Jóòbù dúró de Ọlọ́run (14) 36 Élíhù gbé Ọlọ́run ga, ó ní bó ṣe ga lọ́lá jẹ́ àwámáridìí (1-33) Nǹkan ń lọ dáadáa fún onígbọràn; a kò tẹ́wọ́ gba àwọn tí kò mọ Ọlọ́run (11-13) ‘Olùkọ́ wo ló dà bí Ọlọ́run?’ (22) Kí Jóòbù gbé Ọlọ́run ga (24) “Ọlọ́run tóbi ju bí a ṣe lè mọ̀” (26) Ọlọ́run ń darí òjò àti mànàmáná (27-33) 37 Àwọn ohun tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ bó ṣe tóbi tó (1-24) Ọlọ́run lè fòpin sáwọn ohun téèyàn ń ṣe (7) “Ronú nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run” (14) Ó kọjá agbára èèyàn láti lóye Ọlọ́run (23) Kí èèyàn kankan má rò pé òun gbọ́n (24) 38 Jèhófà jẹ́ ká mọ bí èèyàn ṣe kéré tó (1-41) ‘Ibo lo wà nígbà tí mo dá ayé?’ (4-6) Àwọn ọmọ Ọlọ́run hó yèè, wọ́n yìn ín (7) Ìbéèrè nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá (8-32) “Àwọn òfin tó ń darí ọ̀run” (33) 39 Àwọn ẹran tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn ò mọ nǹkan kan (1-30) Àwọn ewúrẹ́ orí òkè àti àgbọ̀nrín (1-4) Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó (5-8) Akọ màlúù inú igbó (9-12) Ògòǹgò (13-18) Ẹṣin (19-25) Àṣáǹwéwé àti idì (26-30) 40 Jèhófà tún bi í láwọn ìbéèrè (1-24) Jóòbù gbà pé òun ò ní nǹkan kan láti sọ (3-5) “Ṣé o máa sọ pé mi ò ṣèdájọ́ bó ṣe tọ́ ni?” (8) Ọlọ́run jẹ́ ká mọ bí Béhémótì ṣe lágbára tó (15-24) 41 Ọlọ́run jẹ́ ká mọ bí Léfíátánì ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀ (1-34) 42 Jóòbù dá Jèhófà lóhùn (1-6) Ọlọ́run bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta (7-9) Jèhófà pa dà bù kún Jóòbù (10-17) Àwọn ọmọ Jóòbù lọ́kùnrin àti lóbìnrin (13-15)