Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Míkà MÍKÀ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Samáríà àti Júdà (1-16) Ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀tẹ̀ ló fa wàhálà náà (5) 2 Àwọn tó ń ni ẹlòmíì lára gbé! (1-11) Ọlọ́run tún mú kí Ísírẹ́lì wà ní ìṣọ̀kan (12, 13) Ariwo àwọn èèyàn yóò gba ilẹ̀ náà kan (12) 3 Ọlọ́run bá àwọn olórí àti àwọn wòlíì wí (1-12) Ẹ̀mí Jèhófà fún Míkà ní agbára (8) Àwọn àlùfáà ń gba owó kí wọ́n tó kọ́ni (11) Jerúsálẹ́mù yóò di àwókù ilé (12) 4 Òkè Jèhófà yóò ga ju àwọn yòókù lọ (1-5) Wọ́n á fi idà rọ ohun ìtúlẹ̀ (3) “Àwa yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà” (5) Ọlọ́run yóò mú kí Síónì pa dà di alágbára (6-13) 5 Alákòóso kan yóò lágbára ní gbogbo ayé (1-6) Alákòóso náà yóò wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù (2) Àwọn tó ṣẹ́ kù yóò dà bí ìrì àti bíi kìnnìún (7-9) Ọlọ́run máa fọ ilẹ̀ náà mọ́ (10-15) 6 Ọlọ́run pe Ísírẹ́lì lẹ́jọ́ (1-5) Kí ni Jèhófà fẹ́? (6-8) Ìdájọ́ òdodo, ìṣòtítọ́, ìrẹ̀lẹ̀ (8) Ẹ̀bi Ísírẹ́lì àti ìyà tí wọ́n máa jẹ (9-16) 7 Ìwàkiwà Ísírẹ́lì (1-6) “Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni” (6) “Màá dúró de Ọlọ́run” (7) Ọlọ́run dá àwọn èèyàn rẹ̀ láre (8-13) Míkà gbàdúrà, ó sì yin Ọlọ́run (14-20) Jèhófà dáhùn (15-17) ‘Ta ló dà bíi Jèhófà?’ (18)