Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù JÒHÁNÙ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara (1-18) Jòhánù Arinibọmi jẹ́rìí (19-28) Jésù ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run (29-34) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù kọ́kọ́ yàn (35-42) Fílípì àti Nàtáníẹ́lì (43-51) 2 Ìgbéyàwó ní Kánà; omi di wáìnì (1-12) Jésù fọ tẹ́ńpìlì mọ́ (13-22) Jésù mọ ohun tó wà nínú èèyàn (23-25) 3 Jésù àti Nikodémù (1-21) Àtúnbí (3-8) Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé (16) Ẹ̀rí tí Jòhánù jẹ́ gbẹ̀yìn nípa Jésù (22-30) Ẹni tó wá láti òkè (31-36) 4 Jésù àti obìnrin ará Samáríà (1-38) Jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” (23, 24) Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samáríà gba Jésù gbọ́ (39-42) Jésù wo ọmọkùnrin òṣìṣẹ́ ọba kan sàn (43-54) 5 Ó wo ọkùnrin kan sàn ní Bẹtisátà (1-18) Jésù gba àṣẹ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ (19-24) Àwọn òkú máa gbọ́ ohùn Jésù (25-30) Àwọn ẹ̀rí nípa Jésù (31-47) 6 Jésù bọ́ 5,000 èèyàn (1-15) Jésù rìn lórí omi (16-21) Jésù ni “oúnjẹ ìyè” (22-59) Ọ̀pọ̀ èèyàn kọsẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Jésù (60-71) 7 Jésù lọ síbi Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn (1-13) Jésù ń kọ́ni níbi àjọyọ̀ náà (14-24) Oríṣiríṣi ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nípa Kristi (25-52) 8 Baba ń jẹ́rìí nípa Jésù (12-30) Jésù ni “ìmọ́lẹ̀ ayé” (12) Àwọn ọmọ Ábúráhámù (31-41) ‘Òtítọ́ máa sọ yín di òmìnira’ (32) Àwọn ọmọ Èṣù (42-47) Jésù àti Ábúráhámù (48-59) 9 Jésù wo ọkùnrin tí wọ́n bí ní afọ́jú sàn (1-12) Àwọn Farisí ń bi ọkùnrin tó wò sàn ní ìbéèrè (13-34) Àwọn Farisí fọ́jú (35-41) 10 Olùṣọ́ àgùntàn àti ọgbà àgùntàn (1-21) Jésù ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà (11-15) “Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn” (16) Àwọn Júù ta ko Jésù níbi Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ (22-39) Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ò gbà gbọ́ (24-26) “Àwọn àgùntàn mi máa ń fetí sí ohùn mi” (27) Ọmọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba (30, 38) Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní òdìkejì Jọ́dánì gbà gbọ́ (40-42) 11 Ikú Lásárù (1-16) Jésù tu Màtá àti Màríà nínú (17-37) Jésù jí Lásárù dìde (38-44) Wọ́n gbìmọ̀ láti pa Jésù (45-57) 12 Màríà da òróró sí ẹsẹ̀ Jésù (1-11) Jésù gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnú ìlú (12-19) Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (20-37) Àìnígbàgbọ́ àwọn Júù mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ (38-43) Jésù wá gba ayé là (44-50) 13 Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (1-20) Jésù fi hàn pé Júdásì ló máa da òun (21-30) Àṣẹ tuntun (31-35) “Tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín” (35) Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun (36-38) 14 Nípasẹ̀ Jésù nìkan la fi lè dé ọ̀dọ̀ Baba (1-14) ‘Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè’ (6) Jésù ní òun máa rán ẹ̀mí mímọ́ (15-31) “Baba tóbi jù mí lọ” (28) 15 Àpèjúwe àjàrà tòótọ́ (1-10) Kristi pàṣẹ pé kí wọ́n ní irú ìfẹ́ tí òun ní (11-17) ‘Kò sí ìfẹ́ tó ju èyí lọ’ (13) Ayé kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù (18-27) 16 Wọ́n lè pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù (1-4a) Iṣẹ́ tí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣe (4b-16) Ìbànújẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn máa di ayọ̀ (17-24) Jésù ti ṣẹ́gun ayé (25-33) 17 Jésù gbàdúrà tó kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (1-26) Tí a bá wá mọ Ọlọ́run, ó máa yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun (3) Àwọn Kristẹni kì í ṣe apá kan ayé (14-16) “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ” (17) “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ” (26) 18 Júdásì da Jésù (1-9) Pétérù lo idà (10, 11) Wọ́n mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Ánásì (12-14) Ìgbà àkọ́kọ́ tí Pétérù sẹ́ (15-18) Jésù dé iwájú Ánásì (19-24) Pétérù sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì àti lẹ́ẹ̀kẹta (25-27) Jésù dé iwájú Pílátù (28-40) “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí” (36) 19 Wọ́n na Jésù, wọ́n sì fi ṣe yẹ̀yẹ́ (1-7) Pílátù tún bi Jésù léèrè ọ̀rọ̀ (8-16a) Wọ́n kan Jésù mọ́ òpó igi ní Gọ́gọ́tà (16b-24) Jésù ṣètò bí wọ́n ṣe máa bójú tó ìyá rẹ̀ (25-27) Ikú Jésù (28-37) Wọ́n sìnkú Jésù (38-42) 20 Ibojì ṣófo (1-10) Jésù fara han Màríà Magidalénì (11-18) Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (19-23) Tọ́másì ṣiyèméjì, àmọ́ ó pa dà dá a lójú (24-29) Ìdí tí wọ́n fi kọ àkájọ ìwé yìí (30, 31) 21 Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (1-14) Pétérù fi dá Jésù lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ (15-19) “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké” (17) Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù nífẹ̀ẹ́ (20-23) Ọ̀rọ̀ ìparí (24, 25)