Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Róòmù RÓÒMÙ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìkíni (1-7) Ó wu Pọ́ọ̀lù láti lọ sí Róòmù (8-15) Ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo wà láàyè (16, 17) Àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kò ní àwíjàre (18-32) À ń rí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run nínú àwọn ohun tó dá (20) 2 Ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn Júù àti Gíríìkì (1-16) Bí ẹ̀rí ọkàn ṣe ń ṣiṣẹ́ (14, 15) Àwọn Júù àti Òfin (17-24) Ìkọlà ọkàn (25-29) 3 “Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́” (1-8) Àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ (9-20) Òdodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ (21-31) Gbogbo èèyàn kò kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run (23) 4 A pe Ábúráhámù ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́ (1-12) Ábúráhámù ni baba àwọn tó ní ìgbàgbọ́ (11) Ìlérí tí a gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ (13-25) 5 Èèyàn pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ Kristi (1-11) Ikú wá nípasẹ̀ Ádámù, ìyè wá nípasẹ̀ Kristi (12-21) Ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn (12) Ìwà òdodo kan (18) 6 Ìgbé ayé ọ̀tun nípasẹ̀ batisí sínú Kristi (1-11) Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jọba nínú ara yín (12-14) Láti ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ sí ẹrú Ọlọ́run (15-23) Èrè ẹ̀ṣẹ̀ ni ikú; Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè (23) 7 Àpèjúwe bí a ṣe dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ Òfin (1-6) Òfin fi ẹ̀ṣẹ̀ hàn (7-12) Ó ń bá ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀yá ìjà (13-25) 8 Ìyè àti òmìnira nípasẹ̀ ẹ̀mí (1-11) Ẹ̀mí ìsọdọmọ ń jẹ́rìí (12-17) Ìṣẹ̀dá ń dúró de òmìnira àwọn ọmọ Ọlọ́run (18-25) ‘Ẹ̀mí ń bá wa bẹ̀bẹ̀’ (26, 27) Ọlọ́run yàn wá ṣáájú (28-30) Ìfẹ́ Ọlọ́run mú kí a di aṣẹ́gun (31-39) 9 Pọ́ọ̀lù kẹ́dùn nítorí Ísírẹ́lì tara (1-5) Ọmọ Ábúráhámù tòótọ́ (6-13) Ohun tí Ọlọ́run bá yàn, kò sẹ́ni tó lè yí i pa dà (14-26) Ohun èlò ìrunú àti ti àánú (22, 23) Àṣẹ́kù nìkan la ó gbà là (27-29) Ísírẹ́lì kọsẹ̀ (30-33) 10 Bí ọwọ́ èèyàn ṣe lè tẹ òdodo Ọlọ́run (1-15) Ìkéde ní gbangba (10) Kíképe Jèhófà ń yọrí sí ìgbàlà (13) Ẹsẹ̀ àwọn oníwàásù rẹwà (15) Wọ́n kọ ìhìn rere (16-21) 11 Ọlọ́run ò kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ pátápátá (1-16) Àpèjúwe igi ólífì (17-32) Ọgbọ́n Ọlọ́run mà jinlẹ̀ o (33-36) 12 Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè (1, 2) Ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ ara kan náà (3-8) Ìmọ̀ràn lórí ìgbé ayé Kristẹni tòótọ́ (9-21) 13 Ìtẹríba fún àwọn aláṣẹ (1-7) Sísan owó orí (6, 7) Ìfẹ́ ni àkójá Òfin (8-10) Máa rìn bí ìgbà téèyàn ń rìn ní ọ̀sán (11-14) 14 Má ṣe dá ọmọnìkejì rẹ lẹ́jọ́ (1-12) Má ṣe mú ẹlòmíì kọsẹ̀ (13-18) Mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà (19-23) 15 Ẹ tẹ́wọ́ gba ara yín bí Kristi ti ṣe (1-13) Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè (14-21) Àwọn ibi tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ rìnrìn àjò lọ (22-33) 16 Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa Fébè tó jẹ́ òjíṣẹ́ (1, 2) Wọ́n ń kí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù (3-16) Ìkìlọ̀ pé kí wọ́n yẹra fún ìyapa (17-20) Àwọn tó ń bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ kí àwọn ará (21-24) A ti wá mọ àṣírí mímọ́ (25-27)