Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kọ́ríńtì 2 KỌ́RÍŃTÌ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìkíni (1, 2) Ọlọ́run ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa (3-11) Ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù yí pa dà (12-24) 2 Ó ń wu Pọ́ọ̀lù láti mú kí wọ́n láyọ̀ (1-4) Ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n dárí jì, tí wọ́n sì gbà pa dà (5-11) Pọ́ọ̀lù lọ sí Tíróásì àti Makedóníà (12, 13) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ ìjáde àwọn tó ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun (14-17) A kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (17) 3 Lẹ́tà ìdámọ̀ràn (1-3) Àwọn òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun (4-6) Ògo májẹ̀mú tuntun ta yọ (7-18) 4 Ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere (1-6) Ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́ fọ́ (4) Ìṣúra nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe (7-18) 5 Gbígbé ibùgbé ọ̀run wọ̀ (1-10) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́ (11-21) Ẹ̀dá tuntun (17) Ikọ̀ fún Kristi (20) 6 Kí a má ṣi inú rere Ọlọ́run lò (1, 2) Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ṣe rí (3-13) Ẹ má fi àìdọ́gba so pọ̀ (14-18) 7 Ká wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀gbin (1) Inú Pọ́ọ̀lù dùn sí àwọn ará Kọ́ríńtì (2-4) Títù mú ìròyìn rere wá (5-7) Ìbànújẹ́ ní ọ̀nà Ọlọ́run àti ìrònúpìwàdà (8-16) 8 Wọ́n kó ọrẹ jọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà (1-15) Wọ́n fẹ́ rán Títù lọ sí Kọ́ríńtì (16-24) 9 Ó fún wọn níṣìírí láti máa fúnni (1-15) Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú (7) 10 Pọ́ọ̀lù gbèjà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ (1-18) Àwọn ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara (4, 5) 11 Pọ́ọ̀lù àti àwọn àpọ́sítélì adára-má-kù-síbì-kan (1-15) Àwọn ìṣòro Pọ́ọ̀lù bó ṣe jẹ́ àpọ́sítélì (16-33) 12 Àwọn ìran tí Pọ́ọ̀lù rí (1-7a) ‘Ẹ̀gún nínú ara’ Pọ́ọ̀lù (7b-10) Àwọn àpọ́sítélì adára-má-kù-síbìkan ò sàn jù ú lọ (11-13) Bí ọ̀rọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì ṣe jẹ Pọ́ọ̀lù lógún (14-21) 13 Ìkìlọ̀ ìkẹyìn àti ọ̀rọ̀ ìyànjú (1-14) “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́” (5) Ẹ máa ṣe ìyípadà; ẹ máa ronú níṣọ̀kan (11)