Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Éfésù ÉFÉSÙ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìkíni (1, 2) Àwọn ìbùkún tẹ̀mí (3-7) À ń kó ohun gbogbo jọ nínú Kristi (8-14) “Iṣẹ́ àbójútó kan” ní àwọn àkókò tí a ti yàn (10) A fi ẹ̀mí gbé èdìdì lé wọn gẹ́gẹ́ bí “àmì ìdánilójú” (13, 14) Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ìgbàgbọ́ àwọn ará Éfésù, ó sì gbàdúrà fún wọn (15-23) 2 Ọlọ́run sọ wọ́n di ààyè pẹ̀lú Kristi (1-10) A wó ògiri tó pààlà (11-22) 3 Àwọn Kèfèrí wọnú àṣírí mímọ́ (1-13) Àwọn Kèfèrí di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi (6) Ìpinnu ayérayé Ọlọ́run (11) Àdúrà pé kí àwọn ará Éfésù ní òye (14-21) 4 Ìṣọ̀kan nínú ara Kristi (1-16) Àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn (8) Ìwà àtijọ́ àti ìwà tuntun (17-32) 5 Ọ̀rọ̀ mímọ́ àti ìwà mímọ́ (1-5) Ẹ máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀ (6-14) Ẹ máa kún fún ẹ̀mí (15-20) Ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà to dára jù lọ (16) Ìmọ̀ràn fún àwọn ọkọ àti ìyàwó (21-33) 6 Ìmọ̀ràn fún àwọn ọmọ àti òbí (1-4) Ìmọ̀ràn fún àwọn ẹrú àti ọ̀gá (5-9) Gbogbo ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (10-20) Ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (21-24)