Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Tímótì 1 TÍMÓTÌ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìkíni (1, 2) Ìkìlọ̀ torí àwọn olùkọ́ èké (3-11) Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi hàn sí Pọ́ọ̀lù (12-16) Ọba ayérayé (17) ‘Máa ja ogun rere’ (18-20) 2 Gbàdúrà nítorí onírúurú èèyàn (1-7) Ọlọ́run kan, alárinà kan (5) Ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí fún gbogbo èèyàn (6) Àwọn ìtọ́ni fún tọkùnrin tobìnrin (8-15) Múra lọ́nà tó bójú mu (9, 10) 3 Ohun tí alábòójútó gbọ́dọ̀ dójú ìlà rẹ̀ (1-7) Ohun tí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ dójú ìlà rẹ̀ (8-13) Àṣírí mímọ́ ti ìfọkànsin Ọlọ́run (14-16) 4 Ẹ máa ṣọ́ra torí ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù (1-5) Bí o ṣe lè jẹ́ òjíṣẹ́ rere fún Kristi (6-10) Ìyàtọ̀ tó wà láàárín eré ìmárale àti ìfọkànsin Ọlọ́run (8) Máa kíyè sí ẹ̀kọ́ rẹ (11-16) 5 Bí o ṣe máa hùwà sí àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbà (1, 2) Máa ran àwọn opó lọ́wọ́ (3-16) Pèsè fún ìdílé rẹ (8) Bọlá fún àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára (17-25) ‘Máa mu wáìnì díẹ̀ torí inú rẹ’ (23) 6 Kí àwọn ẹrú máa bọlá fún ọ̀gá wọn (1, 2) Àwọn olùkọ́ èké àti ìfẹ́ owó (3-10) Àwọn ìtọ́ni fún èèyàn Ọlọ́run (11-16) Máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere (17-19) Máa ṣọ́ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ (20, 21)