Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jémíìsì JÉMÍÌSÌ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìkíni (1) Ìfaradà ń jẹ́ ká láyọ̀ (2-15) A máa ń dán ìgbàgbọ́ wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó (3) Ẹ máa fi ìgbàgbọ́ béèrè (5-8) Ìfẹ́ ọkàn máa ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú (14, 15) Gbogbo ẹ̀bùn rere wá láti òkè (16-18) Olùgbọ́ àti olùṣe ọ̀rọ̀ náà (19-25) Ẹni tó ń wo ara rẹ̀ nínú dígí (23, 24) Ìjọsìn tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin (26, 27) 2 Ojúsàájú jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ (1-13) Ìfẹ́ ni ọba òfin (8) Ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú (14-26) Àwọn ẹ̀mí èṣù gbà, jìnnìjìnnì sì bò wọ́n (19) A pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ Jèhófà (23) 3 Bí a ṣe lè kápá ahọ́n (1-12) Kí ọ̀pọ̀ má ṣe di olùkọ́ (1) Ọgbọ́n tó wá láti òkè (13-18) 4 Ẹ má ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé (1-12) Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù (7) Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run (8) Ìkìlọ̀ pé ká má ṣe gbéra ga (13-17) “Tí Jèhófà bá fẹ́” (15) 5 Ìkìlọ̀ fún àwọn ọlọ́rọ̀ (1-6) Ọlọ́run ń bù kún àwọn tó ní sùúrù àti ìfaradà (7-11) Ẹ jẹ́ kí “bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni (12) Àdúrà ìgbàgbọ́ lágbára (13-18) Ran ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ kó lè yí pa dà (19, 20)