Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóṣúà JÓṢÚÀ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Jèhófà fún Jóṣúà níṣìírí (1-9) Máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka Òfin (8) Wọ́n ń múra láti sọdá Jọ́dánì (10-18) 2 Jóṣúà rán amí méjì lọ sí Jẹ́ríkò (1-3) Ráhábù fi àwọn amí pa mọ́ (4-7) Wọ́n ṣèlérí fún Ráhábù (8-21a) Okùn aláwọ̀ rírẹ̀dòdò máa jẹ́ àmì (18) Àwọn amí pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà (21b-24) 3 Ísírẹ́lì sọdá Jọ́dánì (1-17) 4 Àwọn òkúta tó máa jẹ́ ohun ìrántí (1-24) 5 Wọ́n dádọ̀dọ́ ní Gílígálì (1-9) Wọ́n ṣe Ìrékọjá; mánà ò rọ̀ mọ́ (10-12) Olórí àwọn ọmọ ogun Jèhófà (13-15) 6 Ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ (1-21) Wọ́n dá ẹ̀mí Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ sí (22-27) 7 Wọ́n ṣẹ́gun Ísírẹ́lì ní ìlú Áì (1-5) Àdúrà Jóṣúà (6-9) Ẹ̀ṣẹ̀ mú kí wọ́n ṣẹ́gun Ísírẹ́lì (10-15) Àṣírí Ákánì tú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta (16-26) 8 Jóṣúà ní kí wọ́n lúgọ láti gbéjà ko ìlú Áì (1-13) Wọ́n ṣẹ́gun ìlú Áì (14-29) Wọ́n ka Òfin ní Òkè Ébálì (30-35) 9 Àwọn ará Gíbíónì dọ́gbọ́n wá àlàáfíà (1-15) Àṣírí àwọn ará Gíbíónì tú (16-21) Àwọn ará Gíbíónì á máa ṣẹ́gi, wọ́n á sì máa pọnmi (22-27) 10 Ísírẹ́lì gbèjà Gíbíónì (1-7) Jèhófà jà fún Ísírẹ́lì (8-15) Òkúta yìnyín já bọ́ lu àwọn ọ̀tá tó ń sá lọ (11) Oòrùn dúró sójú kan (12-14) Wọ́n pa ọba márààrún tó gbéjà kò wọ́n (16-28) Wọ́n gba àwọn ìlú tó wà ní gúúsù (29-43) 11 Wọ́n gba àwọn ìlú tó wà ní àríwá (1-15) Àwọn ilẹ̀ tí Jóṣúà ṣẹ́gun (16-23) 12 Wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọba ìlà oòrùn Jọ́dánì (1-6) Wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọba ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì (7-24) 13 Àwọn ilẹ̀ tí wọn ò tíì gbà (1-7) Wọ́n pín ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (8-14) Ogún Rúbẹ́nì (15-23) Ogún Gádì (24-28) Ogún Mánásè ní ìlà oòrùn (29-32) Jèhófà ni ogún àwọn ọmọ Léfì (33) 14 Wọ́n pín ilẹ̀ tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì (1-5) Kélẹ́bù jogún Hébúrónì (6-15) 15 Ogún Júdà (1-12) Ọmọbìnrin Kélẹ́bù gba ilẹ̀ (13-19) Àwọn ìlú Júdà (20-63) 16 Ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù (1-4) Ogún Éfúrémù (5-10) 17 Ogún Mánásè ní ìwọ̀ oòrùn (1-13) Àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù tún gba ilẹ̀ míì (14-18) 18 Wọ́n pín ilẹ̀ tó kù ní Ṣílò (1-10) Ogún Bẹ́ńjámínì (11-28) 19 Ogún Síméónì (1-9) Ogún Sébúlúnì (10-16) Ogún Ísákà (17-23) Ogún Áṣérì (24-31) Ogún Náfútálì (32-39) Ogún Dánì (40-48) Ogún Jóṣúà (49-51) 20 Àwọn ìlú ààbò (1-9) 21 Àwọn ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì (1-42) Ìlú àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì (9-19) Ìlú àwọn ọmọ Kóhátì yòókù (20-26) Ìlú àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì (27-33) Ìlú àwọn ọmọ Mérárì (34-40) Àwọn ìlérí Jèhófà ṣẹ (43-45) 22 Àwọn ẹ̀yà tó wà ní ìlà oòrùn pa dà sílé (1-8) Wọ́n mọ pẹpẹ sí Jọ́dánì (9-12) Wọ́n ṣàlàyé ohun tí pẹpẹ náà túmọ̀ sí (13-29) Wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà (30-34) 23 Jóṣúà sọ̀rọ̀ ìdágbére fún àwọn olórí Ísírẹ́lì (1-16) Ìkankan nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà ò kùnà (14) 24 Jóṣúà sọ ìtàn Ísírẹ́lì (1-13) Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n sin Jèhófà (14-24) “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn” (15) Jóṣúà bá Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú (25-28) Jóṣúà kú, wọ́n sì sin ín (29-31) Wọ́n sin egungun Jósẹ́fù sí Ṣékémù (32) Élíásárì kú, wọ́n sì sin ín (33)