Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àwọn Onídàájọ́ ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Àwọn tí Júdà àti Síméónì ṣẹ́gun (1-20) Àwọn ará Jébúsì ò kúrò ní Jerúsálẹ́mù (21) Jósẹ́fù gba Bẹ́tẹ́lì (22-26) Wọn ò lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò tán (27-36) 2 Áńgẹ́lì Jèhófà kìlọ̀ fún wọn (1-5) Jóṣúà kú (6-10) Jèhófà yan àwọn onídàájọ́ tó máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ (11-23) 3 Jèhófà dán Ísírẹ́lì wò (1-6) Ótíníẹ́lì, onídàájọ́ àkọ́kọ́ (7-11) Éhúdù onídàájọ́ pa Ẹ́gílónì, ọba tó sanra (12-30) Ṣámúgárì onídàájọ́ (31) 4 Jábínì ọba Kénáánì fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (1-3) Dèbórà wòlíì obìnrin àti Bárákì onídàájọ́ (4-16) Jáẹ́lì pa Sísérà olórí ogun (17-24) 5 Dèbórà àti Bárákì kọrin ìṣẹ́gun (1-31) Àwọn ìràwọ̀ bá Sísérà jà (20) Ọ̀gbàrá Kíṣónì kún àkúnya (21) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dà bí oòrùn (31) 6 Mídíánì fìyà jẹ Ísírẹ́lì (1-10) Áńgẹ́lì kan fi dá Gídíónì Onídàájọ́ lójú pé Jèhófà máa ràn án lọ́wọ́ (11-24) Gídíónì wó pẹpẹ Báálì lulẹ̀ (25-32) Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé Gídíónì (33-35) Ó fi ìṣùpọ̀ irun àgùntàn wádìí ọ̀rọ̀ (36-40) 7 Gídíónì àti 300 ọkùnrin rẹ̀ (1-8) Àwọn ọmọ ogun Gídíónì ṣẹ́gun Mídíánì (9-25) “Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!” (20) Ibùdó Mídíánì dà rú (21, 22) 8 Àwọn èèyàn Éfúrémù bínú sí Gídíónì (1-3) Wọ́n lé àwọn ọba Mídíánì mú, wọ́n sì pa wọ́n (4-21) Gídíónì ò gbà kí wọ́n fi òun jọba (22-27) Àkópọ̀ ìtàn ìgbésí ayé Gídíónì (28-35) 9 Ábímélékì jọba ní Ṣékémù (1-6) Jótámù ṣe àkàwé (7-21) Ìjọba Ábímélékì ni àwọn èèyàn lára (22-33) Ábímélékì gbógun ja Ṣékémù (34-49) Obìnrin kan ṣe Ábímélékì léṣe, ó sì kú (50-57) 10 Tólà àti Jáírì onídàájọ́ (1-5) Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀, ó sì ronú pìwà dà (6-16) Àwọn ọmọ Ámónì halẹ̀ mọ́ Ísírẹ́lì (17, 18) 11 Wọ́n lé Jẹ́fútà onídàájọ́ jáde, àmọ́ wọ́n sọ ọ́ di olórí nígbà tó yá (1-11) Jẹ́fútà bá àwọn ọmọ Ámónì sọ̀rọ̀ (12-28) Ẹ̀jẹ́ tí Jẹ́fútà jẹ́ àti ọmọbìnrin rẹ̀ (29-40) Ọmọbìnrin náà ò lọ́kọ rárá (38-40) 12 Wọ́n bá àwọn ọmọ Éfúrémù jà (1-7) Wọ́n ní kí wọ́n pe Ṣíbólẹ́tì (6) Íbísánì, Élónì àti Ábídónì di onídàájọ́ (8-15) 13 Áńgẹ́lì kan wá sọ́dọ̀ Mánóà àti ìyàwó rẹ̀ (1-23) Wọ́n bí Sámúsìn (24, 25) 14 Sámúsìn onídàájọ́ fẹ́ fi ọmọ Filísínì ṣe aya (1-4) Ẹ̀mí Jèhófà mú kí Sámúsìn pa kìnnìún (5-9) Sámúsìn pa àlọ́ níbi ìgbéyàwó (10-19) Wọ́n fún ọkùnrin míì ní ìyàwó Sámúsìn (20) 15 Sámúsìn gbẹ̀san lára àwọn Filísínì (1-20) 16 Sámúsìn lọ sí Gásà (1-3) Sámúsìn àti Dẹ̀lílà (4-22) Sámúsìn gbẹ̀san, ó sì kú (23-31) 17 Àwọn ère Míkà àti àlùfáà rẹ̀ (1-13) 18 Àwọn ọmọ Dánì ń wá ilẹ̀ (1-31) Wọ́n kó àwọn ère Míkà, wọ́n sì mú àlùfáà rẹ̀ (14-20) Wọ́n gba Láíṣì, wọ́n sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Dánì (27-29) Wọ́n jọ́sìn ère ní Dánì (30, 31) 19 Ìṣekúṣe tí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ṣe ní Gíbíà (1-30) 20 Wọ́n gbógun ja àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì (1-48) 21 Wọ́n gba ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sílẹ̀ (1-25)