ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 2 Kọ́ríńtì 1:1-13:14
  • 2 Kọ́ríńtì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2 Kọ́ríńtì
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kọ́ríńtì

ÌWÉ KEJÌ SÍ ÀWỌN ARÁ KỌ́RÍŃTÌ

1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run àti Tímótì+ arákùnrin wa, sí ìjọ Ọlọ́run tó wà ní Kọ́ríńtì, títí kan gbogbo ẹni mímọ́ tó wà ní gbogbo Ákáyà:+

2 Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa.

3 Ìyìn ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi,+ Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́+ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,+ 4 ẹni tó ń tù wá nínú* nínú gbogbo àdánwò* wa,+ kí a lè fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀+ tu àwọn míì nínú+ lábẹ́ àdánwò* èyíkéyìí tí wọ́n bá wà. 5 Torí pé bí ìyà tí à ń jẹ nítorí Kristi ṣe pọ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni ìtùnú tí à ń rí gbà nípasẹ̀ Kristi ṣe pọ̀. 6 Nígbà náà, tí a bá dojú kọ àdánwò,* torí ìtùnú àti ìgbàlà yín ni; tí a bá sì ń tù wá nínú, torí kí ẹ lè rí ìtùnú ni, èyí tó máa jẹ́ kí ẹ lè fara da ìyà kan náà tí à ń jẹ. 7 Ìrètí wa lórí yín dájú, nítorí a mọ̀ pé bí ẹ ṣe ń jìyà bíi tiwa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ máa rí ìtùnú bíi tiwa.+

8 Ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa ìpọ́njú tó bá wa ní ìpínlẹ̀ Éṣíà.+ A wà nínú ìdààmú tó lé kenkà, kódà ó kọjá agbára wa, a ò tiẹ̀ mọ̀ pé ẹ̀mí wa ò ní bọ́.+ 9 Ká sòótọ́, ṣe ló ń ṣe wá bíi pé a ti gba ìdájọ́ ikú. Èyí jẹ́ kí a má bàa gbẹ́kẹ̀ lé ara wa, àmọ́ ká lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run+ tó ń gbé òkú dìde. 10 Ó gbà wá sílẹ̀ látinú irú ewu ikú tó lágbára bẹ́ẹ̀, ó sì máa gbà wá sílẹ̀, òun la gbẹ́kẹ̀ lé pé á máa gbà wá sílẹ̀ nìṣó.+ 11 Ẹ̀yin náà lè máa fi ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yín ràn wá lọ́wọ́,+ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè máa dúpẹ́ nítorí wa pé a rí inú rere gbà, èyí tó jẹ́ ìdáhùn àdúrà ọ̀pọ̀ èèyàn.*+

12 Nítorí ohun tí a fi ń yangàn nìyí, ẹ̀rí ọkàn wa ń jẹ́rìí pé a ti fi ìjẹ́mímọ́ àti òótọ́ inú lọ́nà ti Ọlọ́run hùwà nínú ayé, pàápàá sí yín, kì í ṣe pẹ̀lú ọgbọ́n ti ara,+ àmọ́ pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. 13 Lóòótọ́, àwọn nǹkan tí ẹ lè kà kí ẹ sì* lóye nìkan là ń kọ ránṣẹ́ sí yín, mo sì retí pé ẹ̀ẹ́ túbọ̀ lóye àwọn nǹkan yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,* 14 bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀ dé àyè kan pé a wà lára ohun tí ẹ lè fi yangàn, bí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe máa jẹ́ fún wa ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù.

15 Torí náà, pẹ̀lú ìdánilójú yìí, mo fẹ́ kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ lè ní ìdí láti dunnú lẹ́ẹ̀kan sí i;* 16 torí mo fẹ́ bẹ̀ yín wò tí mo bá ń lọ sí Makedóníà, kí n sì tún pa dà sọ́dọ̀ yín tí mo bá ń bọ̀ láti Makedóníà, lẹ́yìn náà kí ẹ sìn mí dé ọ̀nà Jùdíà.+ 17 Tóò, nígbà tí mo ní irú nǹkan yìí lọ́kàn, mi ò fojú kékeré wo ọ̀rọ̀ náà, àbí mo ṣe bẹ́ẹ̀? Àbí ẹran ara ló mú kí n fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, tí mo wá ń sọ pé “Bẹ́ẹ̀ ni, bẹ́ẹ̀ ni” àmọ́ tí mo tún ń sọ pé “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”? 18 Àmọ́ Ọlọ́run ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pé ohun tí a sọ fún yín kì í ṣe “bẹ́ẹ̀ ni” kó tún wá jẹ́ “bẹ́ẹ̀ kọ́.” 19 Nítorí Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Kristi, tí a wàásù rẹ̀ láàárín yín, ìyẹn nípasẹ̀ èmi àti Sílífánù* pẹ̀lú Tímótì,+ kò di “bẹ́ẹ̀ ni” kó tún wá jẹ́ “bẹ́ẹ̀ kọ́,” àmọ́ “bẹ́ẹ̀ ni” ti di “bẹ́ẹ̀ ni” nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀. 20 Nítorí bó ṣe wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di “bẹ́ẹ̀ ni” nípasẹ̀ rẹ̀.+ Torí náà, ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ni à ń ṣe “Àmín” sí Ọlọ́run,+ èyí tó ń fi ògo fún un nípasẹ̀ wa. 21 Àmọ́ Ọlọ́run ni ẹni tó ń mú kó dájú pé àwa àti ẹ̀yin jẹ́ ti Kristi, òun ló sì yàn wá.+ 22 Ó tún fi èdìdì rẹ̀ sórí wa,+ ó sì ti fún wa ní àmì ìdánilójú ohun tó ń bọ̀,* ìyẹn ẹ̀mí+ tó wà nínú ọkàn wa.

23 Mo fi Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ara* mi pé torí kí n má bàa tún kó ẹ̀dùn ọkàn bá yín ni mi ò ṣe tíì wá sí Kọ́ríńtì. 24 Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín,+ àmọ́ a jọ ń ṣiṣẹ́ kí ẹ lè máa láyọ̀, torí ìgbàgbọ́ yín ló mú kí ẹ dúró.

2 Mo ti pinnu lọ́kàn mi pé mi ò ní wá sọ́dọ̀ yín nínú ìbànújẹ́ mọ́. 2 Torí tí mo bá bà yín nínú jẹ́, ta ló máa múnú mi dùn tí kì í bá ṣe ẹni tí mo bà nínú jẹ́? 3 Ìdí tí mo fi kọ ìwé tí mo kọ sí yín ni pé, tí mo bá dé mi ò ní banú jẹ́ lórí àwọn tó yẹ kí n máa yọ̀ nítorí wọn, torí ó dá mi lójú pé ohun tó ń fún mi láyọ̀ ń fún gbogbo yín náà láyọ̀. 4 Nítorí nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú àti ìdààmú ọkàn ni mo kọ̀wé sí yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ omijé, kì í ṣe láti bà yín nínú jẹ́,+ àmọ́ ó jẹ́ láti mú kí ẹ mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.

5 Tí ẹnikẹ́ni bá ti fa ìbànújẹ́,+ èmi kọ́ ló bà nínú jẹ́, gbogbo yín ni dé àyè kan. Mi ò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi le koko jù. 6 Ìbáwí tó múná tí èyí tó pọ̀ jù lára yín ti fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó; 7 ní báyìí, ṣe ló yẹ kí ẹ dárí jì í tinútinú, kí ẹ sì tù ú nínú,+ kí ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù má bàa bò ó mọ́lẹ̀.*+ 8 Torí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ jẹ́ kó mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ òun.+ 9 Ìdí nìyí tí mo tún fi kọ̀wé sí yín: kí n lè mọ̀ bóyá ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ jẹ́ onígbọràn nínú ohun gbogbo. 10 Tí ẹ bá dárí ohunkóhun ji ẹnikẹ́ni, èmi náà ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, ohunkóhun tí mo bá ti dárí rẹ̀ jini (ìyẹn tí mo bá ti dárí ohunkóhun jini) ó jẹ́ nítorí yín níwájú Kristi, 11 kí Sátánì má bàa fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n* borí wa,+ nítorí a mọ àwọn ọgbọ́n* rẹ̀.+

12 Nígbà tí mo dé Tíróásì+ láti kéde ìhìn rere nípa Kristi, tí ilẹ̀kùn kan sì ṣí fún mi nínú Olúwa, 13 ẹ̀mí mi ò lélẹ̀ torí mi ò rí Títù + arákùnrin mi. Torí náà, mo dágbére fún wọn, mo sì forí lé Makedóníà.+

14 Àmọ́ ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tó máa ń darí wa nínu ìjáde àwọn tó ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun pẹ̀lú Kristi, tó sì ń tipasẹ̀ wa mú kí òórùn ìmọ̀ nípa rẹ̀ ta sánsán* dé ibi gbogbo! 15 Nítorí lójú Ọlọ́run, a jẹ́ òórùn dídùn ti Kristi, tó ń ta sánsán láàárín àwọn tó ń rí ìgbàlà àti láàárín àwọn tó ń ṣègbé; 16 lójú àwọn tó ń ṣègbé, a jẹ́ òórùn* ikú tó ń yọrí sí ikú,+ lójú àwọn tó ń rí ìgbàlà, a jẹ́ òórùn dídùn ti ìyè tó ń yọrí sí ìyè. Ta ló sì kúnjú ìwọ̀n fún nǹkan wọ̀nyí? 17 Àwa ni, nítorí a kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run*+ bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe jẹ́, àmọ́ à ń fi òótọ́ inú sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe rán wa, àní, níwájú Ọlọ́run àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi.

3 Ṣé ká tún bẹ̀rẹ̀ sí í dámọ̀ràn ara wa ni? Àbí, ṣé a tún nílò lẹ́tà ìdámọ̀ràn sí yín tàbí látọ̀dọ̀ yín bíi ti àwọn kan ni? 2 Ẹ̀yin fúnra yín ni lẹ́tà wa,+ tí a kọ sára ọkàn wa, tí gbogbo aráyé mọ̀, tí wọ́n sì ń kà. 3 Nítorí ó ṣe kedere pé ẹ jẹ́ lẹ́tà Kristi tí àwa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ kọ,+ kì í ṣe yíǹkì la fi kọ ọ́, ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè ni, kì í sì í ṣe ara wàláà òkúta la kọ ọ́ sí,+ ara wàláà ti ẹran ara ni, ìyẹn sára ọkàn.+

4 A ní irú ìgbọ́kànlé yìí nínú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. 5 Kì í ṣe pé àwa fúnra wa kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ohunkóhun, Ọlọ́run ló ń mú ká kúnjú ìwọ̀n,+ 6 ẹni tó mú ká kúnjú ìwọ̀n lóòótọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun kan,+ kì í ṣe ti àkọsílẹ̀ òfin,+ àmọ́ ó jẹ́ ti ẹ̀mí; torí àkọsílẹ̀ òfin ń dáni lẹ́bi ikú,+ àmọ́ ẹ̀mí ń sọni di ààyè.+

7 Ní báyìí, tí àkójọ òfin tó ń mú ikú wá, tí a fi àwọn lẹ́tà fín sára àwọn òkúta+ bá wá pẹ̀lú ògo tó pọ̀ débi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò lè wo ojú Mósè nítorí ògo ojú rẹ̀,+ ògo tó jẹ́ pé ó máa dópin, 8 ṣé iṣẹ́ tí ẹ̀mí ń ṣe+ kò ní ní ògo tó pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ ni?+ 9 Nítorí tí àkójọ òfin tó ń mú ìdálẹ́bi+ wá bá ní ògo,+ ǹjẹ́ iṣẹ́ tó ń mú ká pe àwọn èèyàn ní olódodo kò ní ní ògo tó jù bẹ́ẹ̀ lọ?+ 10 Kódà, èyí tí a ti ṣe lógo tẹ́lẹ̀ ti pàdánù ògo rẹ̀ nítorí ògo tó ju tirẹ̀ lọ.+ 11 Nítorí tí a bá mú èyí tó máa dópin wá pẹ̀lú ògo,+ ǹjẹ́ ògo èyí tí á máa wà nìṣó kò ní pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ?+

12 Torí pé a ní irú ìrètí yìí,+ a lẹ́nu ọ̀rọ̀, 13 a kò sì ṣe bíi ti Mósè nígbà tó ń fi nǹkan bo ojú rẹ̀,+ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì má bàa tẹjú mọ́ òpin ohun tó máa pa rẹ́. 14 Àmọ́ èrò inú wọn ò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́.+ Nítorí títí di òní yìí, a kò ká ìbòjú yẹn kúrò tí a bá ń ka májẹ̀mú láéláé,+ torí ipasẹ̀ Kristi nìkan la fi ń mú un kúrò.+ 15 Kódà, títí di òní, nígbàkigbà tí wọ́n bá ń ka ìwé Mósè,+ ìbòjú máa ń bo ọkàn wọn.+ 16 Àmọ́ nígbà tẹ́nì kan bá yíjú sí Jèhófà,* ìbòjú náà á ká kúrò.+ 17 Jèhófà* ni Ẹ̀mí náà,+ ibi tí ẹ̀mí Jèhófà* bá sì wà, òmìnira á wà níbẹ̀.+ 18 Bí a ṣe ń fi ojú tí a kò fi nǹkan bò gbé ògo Jèhófà* yọ bíi dígí, gbogbo wa ni à ń pa lára dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, bí Jèhófà* tó jẹ́ Ẹ̀mí náà* ti ṣe gẹ́lẹ́.+

4 Nígbà náà, torí pé ipasẹ̀ àánú tí a fi hàn sí wa la fi rí iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí gbà, a kò juwọ́ sílẹ̀. 2 Àmọ́ a ti kọ àwọn ohun ìtìjú tí kò ṣeé gbọ́ sétí sílẹ̀ pátápátá, a kò rin ìrìn ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣe àbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run;+ àmọ́ bí a ṣe ń fi òtítọ́ hàn kedere, à ń dámọ̀ràn ara wa fún ẹ̀rí ọkàn gbogbo èèyàn níwájú Ọlọ́run.+ 3 Tí ìhìn rere tí à ń kéde bá wà lábẹ́ ìbòjú lóòótọ́, á jẹ́ pé ó wà lábẹ́ ìbòjú láàárín àwọn tó ń ṣègbé, 4 láàárín àwọn tí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí*+ ti fọ́ ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́,+ kí ìmọ́lẹ̀* ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run,+ má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.+ 5 Nítorí kì í ṣe ara wa là ń wàásù rẹ̀, Jésù Kristi là ń wàásù gẹ́gẹ́ bí Olúwa, a sì ń sọ pé a jẹ́ ẹrú yín nítorí Jésù. 6 Torí Ọlọ́run ni ẹni tó sọ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn,”+ ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa+ láti mú kí ìmọ̀ ológo nípa Ọlọ́run mọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ojú Kristi.

7 Àmọ́ ṣá o, a ní ìṣúra yìí+ nínú àwọn ohun èlò* tí a fi amọ̀ ṣe,+ kí agbára tó kọjá ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kó má sì jẹ́ látọ̀dọ̀ wa.+ 8 Wọ́n há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, àmọ́ kò le débi tí a ò fi lè yíra; ọkàn wa dà rú, àmọ́ kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbáyọ rárá;*+ 9 wọ́n ṣe inúnibíni sí wa, àmọ́ a ò pa wá tì;+ wọ́n gbé wa ṣánlẹ̀, àmọ́ a ò pa run.+ 10 Nínú ara wa, ìgbà gbogbo là ń fara da ìyà àti ewu ikú tí Jésù dojú kọ,+ kí ìgbésí ayé Jésù lè hàn kedere lára wa. 11 Nítorí ìgbà gbogbo ni wọ́n ń mú kí àwa tí a wà láàyè fojú kojú pẹ̀lú ikú+ nítorí Jésù, kí ìgbésí ayé Jésù lè hàn kedere nínú ara kíkú wa. 12 Torí náà, ikú wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú wa, àmọ́ ìyè wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú yín.

13 Ní báyìí, torí a ní ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, irú èyí tí a kọ nípa rẹ̀ pé: “Mo ní ìgbàgbọ́, torí náà mo sọ̀rọ̀”;+ àwa náà ní ìgbàgbọ́, torí náà a sọ̀rọ̀, 14 bí a ṣe mọ̀ pé Ẹni tó gbé Jésù dìde máa gbé àwa náà dìde pẹ̀lú Jésù, ó sì máa mú àwa pẹ̀lú yín wá síwájú rẹ̀.+ 15 Gbogbo èyí jẹ́ nítorí yín, kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó ń pọ̀ sí i lè túbọ̀ pọ̀ gidigidi, nítorí àwọn púpọ̀ sí i tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ń fi ògo fún un.+

16 Nítorí náà, a kò juwọ́ sílẹ̀, kódà bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro, ó dájú pé ẹni tí a jẹ́ ní inú ń di ọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́. 17 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìpọ́njú* náà jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, kò sì lágbára, ó ń yọrí sí ògo fún wa, ògo tí ó tóbi* gan-an, tí ó sì jẹ́ ti ayérayé;+ 18 bí a ṣe ń tẹ ojú wa mọ́ àwọn ohun tí a kò rí dípò àwọn ohun tí à ń rí.+ Nítorí àwọn ohun tí à ń rí wà fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ àwọn ohun tí a kò rí máa wà títí ayérayé.

5 Nítorí a mọ̀ pé tí ilé wa ní ayé bá wó,*+ ìyẹn àgọ́ yìí, Ọlọ́run máa fún wa ní ilé míì, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́,+ tó jẹ́ ti ayérayé ní ọ̀run. 2 Nítorí à ń kérora nínú ilé* yìí lóòótọ́, ó sì ń wù wá gan-an pé ká gbé èyí tó wà fún wa* láti ọ̀run* wọ̀,+ 3 kí ó lè jẹ́ pé, nígbà tí a bá gbé e wọ̀, a ò ní wà ní ìhòòhò. 4 Kódà, àwa tí a wà nínú àgọ́ yìí ń kérora, ìdààmú bò wá mọ́lẹ̀, torí pé a ò fẹ́ bọ́ èyí kúrò, àmọ́ a fẹ́ gbé èkejì wọ̀,+ kí ìyè lè gbé èyí tó lè kú mì.+ 5 Ọlọ́run ni ẹni tó múra wa sílẹ̀ fún ohun yìí gan-an,+ ó fún wa ní ẹ̀mí láti fi ṣe àmì ìdánilójú ohun tó ń bọ̀.*+

6 Nítorí náà, a jẹ́ onígboyà nígbà gbogbo, a sì mọ̀ pé nígbà tí ilé wa ṣì wà nínú ara yìí, a kò sí lọ́dọ̀ Olúwa,+ 7 nítorí à ń rìn nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa ohun tí à ń rí. 8 A jẹ́ onígboyà, ó sì tẹ́ wa lọ́rùn pé kí a má ṣe wà nínú ara, kí a sì fi ọ̀dọ̀ Olúwa ṣe ilé wa.+ 9 Torí náà, bóyá a wà nílé pẹ̀lú rẹ̀ àbí a ò sí lọ́dọ̀ rẹ̀, ohun tí a fẹ́ ni pé kó tẹ́wọ́ gbà wá. 10 Nítorí gbogbo wa ló máa fara hàn* níwájú ìjókòó ìdájọ́ Kristi, kí kálukú lè gba èrè àwọn ohun tó ṣe nígbà tó wà nínú ara, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.*+

11 Torí náà, nígbà tí a ti mọ ohun tí ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́, à ń yí àwọn èèyàn lérò pa dà, àmọ́ Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa.* Síbẹ̀, mo lérò pé ẹ̀rí ọkàn ẹ̀yin náà mọ̀ wá dáadáa.* 12 Kì í ṣe pé a tún ń dámọ̀ràn ara wa fún yín, àmọ́ à ń fún yín ní ohun tí á mú kí ẹ máa fi wá yangàn, kí ẹ lè rí nǹkan sọ fún àwọn tó ń fi ohun tó wà lóde yangàn,+ tí kì í ṣe ohun tó wà nínú ọkàn. 13 Tí orí wa bá yí,+ nítorí Ọlọ́run ni; tí orí wa bá pé, nítorí tiyín ni. 14 Nítorí ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di dandan fún wa, torí ohun tí a ti pinnu nìyí, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo èèyàn;+ nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo wọn ti kú. 15 Ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́,+ bí kò ṣe fún ẹni tó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.

16 Nítorí náà, láti ìsinsìnyí lọ, a ò fojú tara wo ẹnikẹ́ni mọ́.+ Bí a tilẹ̀ ń fojú tara wo Kristi tẹ́lẹ̀, ó dájú pé a ò fojú yẹn wò ó mọ́.+ 17 Nítorí náà, tí ẹnikẹ́ni bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, ó ti di ẹ̀dá tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ;+ wò ó! àwọn ohun tuntun ti dé. 18 Àmọ́ ohun gbogbo wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tó tipasẹ̀ Kristi mú wa pa dà bá ara rẹ̀ rẹ́,+ tó sì fún wa ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́,+ 19 ìyẹn ni pé Ọlọ́run mú ayé kan pa dà bá ara rẹ̀ rẹ́ nípasẹ̀ Kristi,+ kò ka àwọn àṣemáṣe wọn sí wọn lọ́rùn,+ ó sì fi ọ̀rọ̀ ìpadàrẹ́ sí ìkáwọ́ wa.+

20 Nítorí náà, a jẹ́ ikọ̀+ tó ń dípò fún Kristi,+ bíi pé Ọlọ́run ń pàrọwà nípasẹ̀ wa. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń dípò fún Kristi, a bẹ̀bẹ̀ pé: “Ẹ pa dà bá Ọlọ́run rẹ́.” 21 Ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀+ ni ó sọ di ẹ̀ṣẹ̀* fún wa, kí a lè di olódodo lójú Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀.+

6 Bí a ṣe ń bá a ṣiṣẹ́,+ à ń rọ̀ yín pé kí ẹ má ṣe gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kí ẹ sì pàdánù ohun tó wà fún.+ 2 Nítorí ó sọ pé: “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.”+ Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.

3 A ò ṣe ohun tó lè fa ìkọ̀sẹ̀ lọ́nàkọnà, kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa má bàa ní àbùkù;+ 4 àmọ́ ní gbogbo ọ̀nà, à ń dámọ̀ràn ara wa bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run,+ nínú ọ̀pọ̀ ìfaradà, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú ìṣòro,+ 5 nínú lílù, nínú ẹ̀wọ̀n,+ nínú rúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsùn, nínú àìrí oúnjẹ jẹ;+ 6 nínú jíjẹ́ mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú sùúrù,+ nínú inú rere,+ nínú ẹ̀mí mímọ́, nínú ìfẹ́ tí kò ní ẹ̀tàn,+ 7 nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run;+ nípasẹ̀ àwọn ohun ìjà òdodo+ lọ́wọ́ ọ̀tún* àti lọ́wọ́ òsì,* 8 nínú ògo àti àbùkù, nínú ìròyìn burúkú àti ìròyìn rere. Wọ́n kà wá sí ẹlẹ́tàn, síbẹ̀ a jẹ́ olóòótọ́, 9 bí ẹni tí a kò mọ̀, síbẹ̀ a dá wa mọ̀, bí ẹni tó ń kú lọ,* síbẹ̀, wò ó! a wà láàyè,+ bí ẹni tí wọ́n fìyà jẹ,* síbẹ̀ a kò fà wá lé ikú lọ́wọ́,+ 10 bí ẹni tó ń kárí sọ àmọ́ à ń yọ̀ nígbà gbogbo, bí aláìní àmọ́ à ń sọ ọ̀pọ̀ di ọlọ́rọ̀, bí ẹni tí kò ní nǹkan kan, síbẹ̀ a ní ohun gbogbo.+

11 A ti la ẹnu wa láti bá yín sọ̀rọ̀,* ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, a sì ti ṣí ọkàn wa sílẹ̀ pátápátá. 12 Ìfẹ́ tí a ní sí yín kò ní ààlà,*+ àmọ́ ẹ ti pààlà sí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ẹ ní sí wa. 13 Torí náà, mò ń bá yín sọ̀rọ̀ bí ẹni ń bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀, ẹ̀yin náà, ẹ ṣí ọkàn yín sílẹ̀ pátápátá.*+

14 Ẹ má fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú* àwọn aláìgbàgbọ́.+ Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà tí kò bófin mu ní?+ Tàbí kí ló pa ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn pọ̀?+ 15 Bákan náà, ìṣọ̀kan wo ló wà láàárín Kristi àti Bélíálì?*+ Àbí kí ló pa onígbàgbọ́* àti aláìgbàgbọ́ pọ̀?+ 16 Kí ló pa òrìṣà pọ̀ mọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run?+ Nítorí àwa jẹ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run alààyè;+ bí Ọlọ́run ṣe sọ pé: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn,+ èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì di èèyàn mi.”+ 17 “‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà* wí, ‘ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ mọ́’”;+ “‘màá sì gbà yín wọlé.’”+ 18 “‘Màá di bàbá yín,+ ẹ ó sì di ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi,’+ ni Jèhófà,* Olódùmarè wí.”

7 Nítorí náà, ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, nígbà tí a ti gba àwọn ìlérí yìí,+ ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí,+ kí a jẹ́ mímọ́ pátápátá nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

2 Ẹ fàyè gbà wá nínú ọkàn yín.+ A kò ṣe àìtọ́ sí ẹnì kankan, a kò sọ ẹnì kankan dìbàjẹ́, a kò sì yan ẹnì kankan jẹ.+ 3 Mi ò sọ èyí láti dá yín lẹ́bi. Nítorí mo ti sọ ṣáájú pé ẹ wà lọ́kàn wa, bóyá a kú àbí a wà láàyè. 4 Mo lè bá yín sọ̀rọ̀ fàlàlà. Mò ń fi yín yangàn púpọ̀. Ara tù mí gan-an, kódà ayọ̀ mi kún nínú gbogbo ìpọ́njú wa.+

5 Ní tòótọ́, nígbà tí a dé Makedóníà,+ ara* ò tù wá rárá, ṣe ni wọ́n ń fìyà jẹ wá ní gbogbo ọ̀nà—ìjà wà lóde, ìbẹ̀rù wà nínú. 6 Àmọ́ Ọlọ́run tó ń tu àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá nínú,+ ti tù wá nínú bí Títù ṣe wà pẹ̀lú wa; 7 síbẹ̀, kì í ṣe bó ṣe wà pẹ̀lú wa nìkan, àmọ́ bó ṣe rí ìtùnú gbà nítorí yín, tó sọ fún wa pé ó ń wù yín láti rí mi, bí ẹ ṣe ń kẹ́dùn púpọ̀ àti bí ọ̀rọ̀ mi ṣe jẹ yín lọ́kàn;* torí náà, ṣe ni ayọ̀ mi pọ̀ sí i.

8 Nítorí ká ní mo tiẹ̀ fi lẹ́tà mi bà yín nínú jẹ́,+ mi ò kábàámọ̀ rẹ̀. Ká tiẹ̀ ní mo kọ́kọ́ kábàámọ̀ rẹ̀, (bí mo ṣe rí i pé lẹ́tà yẹn bà yín nínú jẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,) 9 ní báyìí, inú mi ń dùn, kì í kàn ṣe torí pé a bà yín nínú jẹ́, àmọ́ torí pé ìbànújẹ́ yìí mú kí ẹ ronú pìwà dà. A bà yín nínú jẹ́ ní ọ̀nà Ọlọ́run, kí ẹ má bàa fara pa nítorí wa. 10 Nítorí ìbànújẹ́ ní ọ̀nà Ọlọ́run ń múni ronú pìwà dà, ó sì ń yọrí sí ìgbàlà láìfi àbámọ̀ kún un;+ àmọ́ ìbànújẹ́ ti ayé ń mú ikú wá. 11 Ẹ wo bí ìbànújẹ́ tó bá yín ní ọ̀nà Ọlọ́run ṣe mú kí ẹ túbọ̀ máa fìtara ṣe nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni, ó mú kí ẹ wẹ ara yín mọ́, ó múnú bí yín sí àìtọ́ tó wáyé, ó mú kí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ó mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run wà lọ́kàn yín, ó mú kí ẹ nítara, ó sì mú kí ẹ ṣe àtúnṣe sí àìtọ́ náà!+ Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ ti fi hàn pé ẹ jẹ́ mímọ́* nínú ọ̀ràn yìí. 12 Òótọ́ ni pé mo kọ̀wé sí yín, àmọ́ kì í ṣe torí ẹni tó ṣe àìtọ́ ni mo ṣe kọ ọ́+ tàbí torí ẹni tí wọ́n ṣe àìtọ́ sí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí kó lè hàn kedere láàárín yín pé ẹ̀ ń fìtara ṣe nǹkan tí a sọ fún yín níwájú Ọlọ́run. 13 Ìdí nìyẹn tí a fi rí ìtùnú gbà.

Àmọ́ yàtọ̀ sí ìtùnú tí a rí gbà, ìdùnnú wa tún pọ̀ sí i lórí ayọ̀ tí Títù ní, nítorí gbogbo yín mára tu ẹ̀mí rẹ̀. 14 Mo ti fi yín yangàn lójú rẹ̀, ojú ò sì tì mí; bí gbogbo ohun tí a sọ fún yín ṣe jẹ́ òótọ́, bẹ́ẹ̀ ni bí a ṣe fi yín yangàn níwájú Títù ṣe jẹ́ òótọ́. 15 Bákan náà, ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó ní sí yín ń pọ̀ sí i bó ṣe ń rántí ìgbọràn gbogbo yín,+ bí ẹ ṣe gbà á pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì. 16 Inú mi dùn pé ní gbogbo ọ̀nà, mo lè fọkàn tán yín.*

8 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ̀ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fún àwọn ìjọ tó wà ní Makedóníà.+ 2 Nígbà tí àdánwò ńlá pọ́n wọn lójú, ayọ̀ tó gba ọkàn wọn bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ òtòṣì paraku fi hàn pé wọ́n ní ọrọ̀ nípa tẹ̀mí, torí pé wọ́n lawọ́ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.* 3 Bí agbára wọn ṣe gbé e tó ni,+ bẹ́ẹ̀ ni, mo jẹ́rìí sí i, kódà ó kọjá agbára wọn,+ 4 ṣe ni wọ́n lo ìdánúṣe, tí wọ́n ń bẹ̀ wá taratara pé kí a fún wọn láǹfààní láti ṣe ọrẹ, kí wọ́n lè ní ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìrànwọ́ fún àwọn ẹni mímọ́.+ 5 Kì í ṣe bí a ṣe retí nìkan, àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n fi ara wọn fún Olúwa àti fún àwa nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run. 6 Torí náà, a fún Títù+ ní ìṣírí pé, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí láàárín yín, kó parí gbígba àwọn ọrẹ yìí lọ́dọ̀ yín. 7 Síbẹ̀ náà, bí ẹ ṣe pọ̀ nínú ohun gbogbo, nínú ìgbàgbọ́ àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ àti nínú fífi ìtara ṣe gbogbo nǹkan àti nínú ìfẹ́ tí a ní fún yín, kí ẹ pọ̀ nínú bí ẹ ṣe ń fúnni ní ọrẹ.+

8 Kì í ṣe láti pàṣẹ fún yín ni mo ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ó jẹ́ kí ẹ lè mọ bí àwọn míì ṣe ń fi ìtara ṣe nǹkan àti pé kí n lè dán ìfẹ́ yín wò láti mọ bó ṣe jinlẹ̀ tó. 9 Nítorí ẹ mọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wa, pé bó tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀, ó di aláìní nítorí yín,+ kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ àìní rẹ̀.

10 Mo sọ èrò mi lórí èyí pé:+ Àǹfààní yín ni èyí wà fún, bó ṣe jẹ́ pé lọ́dún kan sẹ́yìn, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é, àmọ́ kì í ṣe ìyẹn nìkan, ẹ tún fi hàn pé ó wù yín láti ṣe é. 11 Torí náà, ní báyìí, ẹ parí ohun tí ẹ ti bẹ̀rẹ̀, kó lè jẹ́ pé bó ṣe yá yín lára nígbà tí ẹ bẹ̀rẹ̀ náà ló ń yá yín lára títí ẹ ó fi parí rẹ̀, bí agbára yín ṣe gbé e tó. 12 Nítorí tó bá ti jẹ́ pé ó yá èèyàn lára, á túbọ̀ ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ìyẹn tó bá jẹ́ ohun tí èèyàn ní ló fi ṣe é,+ kì í ṣe ohun tí èèyàn kò ní. 13 Nítorí mi ò fẹ́ kó rọrùn fún àwọn míì, kó wá nira fún ẹ̀yin; 14 ṣùgbọ́n kí nǹkan lè dọ́gba, kí ohun tó ṣẹ́ kù lọ́dọ̀ yín ní báyìí dí àìní wọn, kí ohun tó ṣẹ́ kù lọ́dọ̀ wọn sì dí àìtó yín, ìyẹn á jẹ́ kí nǹkan lè dọ́gba. 15 Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹni tó ní púpọ̀, ohun tó ní kò pọ̀ jù, ẹni tó sì ní díẹ̀, ohun tó ní kò kéré jù.”+

16 Tóò, ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run tó fi irú ìtara tí a ní fún yín sínú ọkàn Títù,+ 17 torí pé ó ti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìṣírí tó rí gbà lóòótọ́, ó sì ń wù ú gan-an ni, kódà òun fúnra rẹ̀ ló pinnu láti wá sọ́dọ̀ yín. 18 Àmọ́ à ń rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀, ẹni tí òkìkí rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìhìn rere ti kàn dé gbogbo ìjọ. 19 Kì í ṣe ìyẹn nìkan, àwọn ìjọ tún yàn án pé kó máa bá wa rìnrìn àjò bí a ṣe ń pín àwọn ọrẹ yìí fún ògo Olúwa, tí a sì ń fi ẹ̀rí hàn pé a múra tán láti ṣèrànwọ́. 20 Nípa báyìí, à ń kíyè sára kí ẹnikẹ́ni má bàa rí àléébù nínú wa lórí bí a ṣe ń pín ọrẹ àtinúwá tí àwọn èèyàn ṣe.+ 21 Nítorí à ‘ń fi òótọ́ inú ṣe ohun gbogbo, kì í ṣe níwájú Jèhófà* nìkan, àmọ́ níwájú àwọn èèyàn pẹ̀lú.’+

22 Yàtọ̀ síyẹn, à ń rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí a ti dán wò lọ́pọ̀ ìgbà, tí a sì ti rí i pé ó já fáfá nínú ọ̀pọ̀ nǹkan, àmọ́ ní báyìí, ó ti túbọ̀ já fáfá torí ìgbọ́kànlé tó lágbára tó ní nínú yín. 23 Tí ohunkóhun bá wà tó ń kọ yín lóminú nípa Títù, alábàákẹ́gbẹ́* mi ni, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ fún ire yín; tí ohunkóhun bá sì wà tó ń kọ yín lóminú nípa àwọn arákùnrin wa, àpọ́sítélì àwọn ìjọ ni wọ́n, wọ́n sì ń fi ògo fún Kristi. 24 Nítorí náà, ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn,+ kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ìjọ mọ ìdí tí a fi ń fi yín yangàn.

9 Ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà fún àwọn ẹni mímọ́,+ kò pọn dandan kí n kọ̀wé sí yín, 2 torí mo mọ bó ṣe ń yá yín lára, mo sì fi ń yangàn lójú àwọn ará Makedóníà, pé ó ti pé ọdún kan báyìí tí Ákáyà ti múra tán, ìtara yín sì ti mú kí èyí tó pọ̀ jù nínú wọn gbára dì. 3 Àmọ́ mò ń rán àwọn arákùnrin náà sí yín, kí gbogbo bí a ṣe ń fi yín yangàn má bàa já sí asán nínú ọ̀ràn yìí, kí ẹ sì lè múra tán lóòótọ́, bí mo ṣe sọ pé ẹ máa ṣe. 4 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, tí àwọn ará Makedóníà bá bá mi wá, tí wọ́n sì rí i pé ẹ ò múra sílẹ̀, ìtìjú á bá wa, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ẹ̀yin, torí pé a fọkàn tán yín. 5 Nítorí náà, mo wò ó pé ó ṣe pàtàkì láti fún àwọn arákùnrin náà ní ìṣírí pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ yín ṣáájú àkókò, kí wọ́n sì múra ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣèlérí sílẹ̀, kí èyí lè wà nílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí èèyàn fipá gbà.

6 Àmọ́ ní ti èyí, ẹni tó bá ń fúnrúgbìn díẹ̀ máa kórè díẹ̀, ẹni tó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu máa kórè yanturu.+ 7 Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe,*+ nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.+

8 Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run lè mú kí gbogbo inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ pọ̀ gidigidi fún yín, kí ẹ lè máa ní ànító ohun gbogbo nígbà gbogbo, kí ẹ sì tún ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ fún iṣẹ́ rere gbogbo.+ 9 (Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ó ti pín nǹkan fún àwọn èèyàn káàkiri,* ó ti fún àwọn aláìní. Òdodo rẹ̀ wà títí láé.”+ 10 Ẹni tó ń pèsè irúgbìn lọ́pọ̀ yanturu fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún jíjẹ máa pèsè irúgbìn, ó máa sọ ọ́ di púpọ̀ fún yín láti gbìn, á sì mú èso òdodo yín pọ̀ sí i.) 11 Ọlọ́run ti bù kún yín ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ lè máa fúnni lóríṣiríṣi ọ̀nà, èyí sì ń mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; 12 nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn èèyàn kì í ṣe láti fún àwọn ẹni mímọ́ ní ohun tí wọ́n nílò nìkan,+ ó tún máa mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run. 13 Ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìrànwọ́ yìí ń ṣe jẹ́ ẹ̀rí, èyí sì ń mú kí wọ́n máa yin Ọlọ́run lógo torí pé ẹ̀ ń ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Kristi, bí ẹ ṣe kéde fún àwọn èèyàn, tí ẹ sì jẹ́ ọ̀làwọ́ nínú ọrẹ tí ẹ̀ ń ṣe fún wọn àti fún gbogbo èèyàn.+ 14 Wọ́n fi ìfẹ́ hàn sí yín bí wọ́n ṣe ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún yín, torí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ tó wà lórí yín.

15 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí kò ṣeé ṣàpèjúwe.

10 Èmi fúnra mi, Pọ́ọ̀lù, fi ìwà tútù àti inú rere Kristi bẹ̀ yín,+ torí ẹ̀ ń fojú ẹni yẹpẹrẹ wò mí tí a bá ríra lójúkojú,+ àmọ́ ẹ̀ ń fojú ẹni tó le wò mí tí mi ò bá sí lọ́dọ̀ yín.+ 2 Mo bẹ̀bẹ̀ pé tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín, mi ò ní nílò láti fi ọwọ́ líle tí mo gbà pé ó yẹ mú àwọn tí wọ́n rò pé à ń rìn nípa ti ara. 3 Bí a tiẹ̀ ń rìn nípa ti ara, kì í ṣe ohun tí a jẹ́ nínú ara la fi ń jagun. 4 Nítorí àwọn ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara,+ àmọ́ Ọlọ́run ti mú kí wọ́n lágbára+ láti borí àwọn nǹkan tó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. 5 Nítorí à ń borí àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga tí kò bá ìmọ̀ Ọlọ́run mu,+ a sì ń mú gbogbo ìrònú lẹ́rú kí ó lè ṣègbọràn sí Kristi; 6 a ti múra tán láti fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ṣàìgbọràn,+ ní gbàrà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀.

7 Ẹ̀ ń wo àwọn nǹkan bí wọ́n ṣe rí lójú. Bí ẹnikẹ́ni bá dá ara rẹ̀ lójú pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó rántí òtítọ́ yìí pé: Bí òun ṣe jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà ṣe jẹ́ ti Kristi. 8 Nítorí ká tiẹ̀ sọ pé mo yangàn díẹ̀ jù nípa àṣẹ tí Olúwa fún wa láti gbé yín ró, tí kì í ṣe láti fà yín lulẹ̀,+ ìtìjú ò ní bá mi. 9 Nítorí mi ò fẹ́ kó dà bíi pé mò ń fi àwọn lẹ́tà mi dẹ́rù bà yín. 10 Wọ́n ń sọ pé: “Àwọn lẹ́tà rẹ̀ le, wọ́n sì lágbára, àmọ́ tí òun fúnra rẹ̀ bá dé, bí ẹni tí kò lókun nínú ló rí, ọ̀rọ̀ kò sì dá lẹ́nu rẹ̀.” 11 Kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbà pé ohun tí a sọ* nínú àwọn lẹ́tà wa nígbà tí a kò sí lọ́dọ̀ yín náà la máa ṣe* nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ yín.+ 12 Nítorí a ò jẹ́ ka ara wa mọ́ àwọn tó ń dámọ̀ràn ara wọn, a ò sì fara wé wọn.+ Bí wọ́n ṣe ń gbé ara wọn yẹ̀ wò, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wéra, fi hàn pé wọn kò ní òye.+

13 Síbẹ̀, a ò ní yangàn kọjá ààlà àwọn ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wa, inú ààlà agbègbè tí Ọlọ́run pín* fún wa, tó sì mú kó lọ jìnnà, kódà dé ọ̀dọ̀ yín la máa wà.+ 14 Ní ti gidi, a ò kọjá àyè wa nígbà tí a wá sọ́dọ̀ yín, torí àwa la kọ́kọ́ mú ìhìn rere nípa Kristi dé ọ̀dọ̀ yín.+ 15 Kì í ṣe pé à ń yangàn kọjá ààlà àwọn ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wa lórí iṣẹ́ ẹlòmíì, àmọ́ a retí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ṣe ń lágbára sí i, ohun tí a ṣe náà á máa pọ̀ sí i láàárín ìpínlẹ̀ wa. Nígbà náà, a máa túbọ̀ pọ̀ sí i, 16 kí a lè kéde ìhìn rere fún àwọn ìlú tó wà ní ìkọjá ọ̀dọ̀ yín, kí a má bàa máa fi iṣẹ́ tí ẹlòmíì ti ṣe ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ yangàn. 17 “Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fẹ́ yangàn, kí ó máa fi Jèhófà* yangàn.”+ 18 Nítorí kì í ṣe ẹni tó ń dámọ̀ràn ara rẹ̀ ni a tẹ́wọ́ gbà,+ bí kò ṣe ẹni tí Jèhófà* dámọ̀ràn.+

11 Ó wù mí kí ẹ máa fara dà á bó bá tiẹ̀ jọ pé mo dà bí aláìnírònú. Àmọ́, ká sòótọ́, ẹ ti ń fara dà á fún mi! 2 Mò ń jowú torí yín lọ́nà ti Ọlọ́run,* nítorí èmi fúnra mi ti fẹ́ yín sílẹ̀ de ọkọ kan, kí n lè mú yín wá fún Kristi bíi wúńdíá oníwà mímọ́.*+ 3 Àmọ́ ẹ̀rù ń bà mí pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ṣe fi ẹ̀tàn fa ojú Éfà mọ́ra,+ a lè sọ ìrònú yín dìbàjẹ́, tí ẹ ó sì yà kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́* tó yẹ Kristi.+ 4 Torí ní báyìí, tí ẹnì kan bá wá, tó sì wàásù Jésù kan yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù tàbí tí ẹ bá gba ẹ̀mí kan tó yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí tí ẹ gba ìhìn rere kan tó yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà,+ ẹ̀ ń gba onítọ̀hún láyè láìjanpata. 5 Mo rò pé kò sí ohun kankan tó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì yín adára-má-kù-síbìkan sàn jù mí lọ.+ 6 Àmọ́ ká tiẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ kò dá ṣáká lẹ́nu mi,+ ó dájú pé mi ò rí bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀; ní tòótọ́, a jẹ́ kó ṣe kedere sí yín ní gbogbo ọ̀nà àti nínú ohun gbogbo.

7 Àbí, ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá ni bí mo ṣe rẹ ara mi sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, tí mo fi ayọ̀ kéde ìhìn rere Ọlọ́run fún yín lọ́fẹ̀ẹ́?+ 8 Mo fi nǹkan du àwọn ìjọ míì* bí mo ṣe gba àwọn nǹkan* lọ́wọ́ wọn kí n lè ṣe ìránṣẹ́ fún yín.+ 9 Síbẹ̀, nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín, tí mo sì nílò àwọn nǹkan kan, mi ò di ẹrù sí ẹnikẹ́ni lọ́rùn, torí àwọn arákùnrin tó wá láti Makedóníà pèsè àwọn nǹkan tí mo nílò lọ́pọ̀ yanturu.+ Bẹ́ẹ̀ ni, mo kíyè sára ní gbogbo ọ̀nà kí n má bàa di ẹrù sí yín lọ́rùn, màá sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.+ 10 Bó ṣe dájú pé òtítọ́ Kristi wà nínú mi, mi ò ní ṣíwọ́ láti máa yangàn  + ní àwọn agbègbè Ákáyà. 11 Nítorí kí ni? Ṣé torí mi ò nífẹ̀ẹ́ yín ni? Ọlọ́run mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ yín.

12 Àmọ́ ohun tí mò ń ṣe ni màá máa ṣe lọ,+ kí n lè fòpin sí àwáwí àwọn tó ń wá bí wọ́n á ṣe rí ohun* tí wọ́n á fi sọ pé àwọn jẹ́ bákan náà pẹ̀lú wa nínú àwọn nǹkan* tí wọ́n fi ń yangàn. 13 Nítorí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èké àpọ́sítélì, àwọn oníṣẹ́ ẹ̀tàn, tí wọ́n ń díbọ́n pé àpọ́sítélì Kristi ni àwọn.+ 14 Kò sì yani lẹ́nu, torí Sátánì fúnra rẹ̀ máa ń díbọ́n pé áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀ ni òun.+ 15 Nítorí náà, kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ náà bá ń díbọ́n pé òjíṣẹ́ òdodo ni àwọn. Àmọ́ òpin wọn máa rí bí iṣẹ́ wọn.+

16 Mo tún sọ pé: Kí ẹnikẹ́ni má rò pé mi ò nírònú. Àmọ́ ká tiẹ̀ ní ẹ rò bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí bí aláìnírònú, kí èmi náà lè yangàn díẹ̀. 17 Ní báyìí, mi ò sọ̀rọ̀ bí ẹni tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Olúwa, àmọ́ mò ń sọ̀rọ̀ bí aláìnírònú tó dá ara rẹ̀ lójú tó sì ń fọ́nnu. 18 Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ń yangàn nípa ti ara,* èmi náà á yangàn. 19 Níbi tí ẹ “nírònú” dé, tayọ̀tayọ̀ lẹ̀ ń fara dà á fún àwọn aláìnírònú. 20 Kódà, ẹ̀ ń fara dà á fún ẹni tó bá mú yín lẹ́rú, ẹni tó bá gba ohun ìní yín, ẹni tó bá já nǹkan yín gbà, ẹni tó bá jẹ gàba lé yín lórí àti ẹni tó bá gbá yín lójú.

21 Ohun tí mò ń sọ yìí jẹ́ ìtìjú fún wa, torí ó lè dà bíi pé a jẹ́ aláìlera lójú yín.

Àmọ́ tí àwọn míì bá ń ṣàyà gbàǹgbà, mò ń sọ̀rọ̀ bí aláìnírònú, èmi náà á ṣàyà gbàǹgbà. 22 Ṣé Hébérù ni wọ́n? Hébérù lèmi náà.+ Ṣé ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n? Ọmọ Ísírẹ́lì lèmi náà. Ṣé ọmọ* Ábúráhámù ni wọ́n? Ọmọ Ábúráhámù lèmi náà.+ 23 Ṣé òjíṣẹ́ Kristi ni wọ́n? Mo fèsì bí ayírí, mo jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi lọ́nà tó ta wọ́n yọ: mo ti ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ,+ wọ́n ti jù mí sẹ́wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà,+ wọ́n ti lù mí láìmọye ìgbà, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́.+ 24 Ìgbà márùn-ún ni àwọn Júù nà mí ní ẹgba mọ́kàndínlógójì (39),+ 25 ìgbà mẹ́ta ni wọ́n ti fi ọ̀pá nà mí,+ wọ́n sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan,+ ìgbà mẹ́ta ni mo ti wọkọ̀ tó rì,+ mo sì ti lo ọ̀sán kan àti òru kan lórí agbami òkun; 26 nínú ìrìn àjò lọ́pọ̀ ìgbà, nínú ewu odò, nínú ewu dánàdánà, nínú ewu látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tèmi,+ nínú ewu látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ nínú ewu láàárín ìlú,+ nínú ewu láàárín aginjù, nínú ewu lójú òkun, nínú ewu láàárín àwọn èké arákùnrin, 27 nínú òpò* àti làálàá, nínú àìlèsùn lóru lọ́pọ̀ ìgbà,+ nínú ebi àti òùngbẹ,+ nínú àìsí oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà,+ nínú òtútù àti àìrí aṣọ wọ̀.*

28 Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tó jẹ́ ti òde yìí, nǹkan míì tún wà tó ń rọ́ lù mí láti ọjọ́ dé ọjọ́:* àníyàn lórí gbogbo ìjọ.+ 29 Ta ló jẹ́ aláìlera, témi náà ò di aláìlera? Ta ló kọsẹ̀, tí mi ò sì gbaná jẹ?

30 Tí mo bá tiẹ̀ máa yangàn, màá fi àwọn nǹkan tó fi hàn pé mo jẹ́ aláìlera yangàn. 31 Ọlọ́run àti Baba Jésù Olúwa, Ẹni tí àá máa yìn títí láé, mọ̀ pé mi ò parọ́. 32 Ní Damásíkù, gómìnà tó wà lábẹ́ Ọba Árétásì ń ṣọ́ ìlú àwọn ará Damásíkù kí ó lè gbá mi mú, 33 àmọ́ wọ́n fi apẹ̀rẹ̀* sọ̀ mí kalẹ̀ gba ojú fèrèsé* ara ògiri ìlú,+ mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

12 Mo ní láti yangàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ṣàǹfààní, màá kọjá lọ sínú àwọn ìran tó ju ti ẹ̀dá lọ+ àti àwọn ìfihàn Olúwa.+ 2 Mo mọ ọkùnrin kan nínú Kristi, ẹni tí a gbà lọ sí ọ̀run kẹta lọ́dún mẹ́rìnlá (14) sẹ́yìn, bóyá nínú ara tàbí lóde ara, mi ò mọ̀, àmọ́ Ọlọ́run mọ̀. 3 Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, bóyá nínú ara tàbí láìsí ara, mi ò mọ̀; àmọ́ Ọlọ́run mọ̀, 4 ẹni tí a gbà lọ sínú párádísè, tí ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣeé sọ, tí kò sì bófin mu fún èèyàn láti sọ. 5 Màá fi irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ yangàn, àmọ́ mi ò ní fi ara mi yangàn, àfi àwọn àìlera mi. 6 Ká tiẹ̀ ní mo fẹ́ yangàn, mi ò ní jẹ́ aláìnírònú, torí òtítọ́ ni màá sọ. Àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má bàa gbóríyìn fún mi ju ohun tó rí tí mò ń ṣe tàbí ohun tó gbọ́ tí mò ń sọ, 7 lórí pé mo gba àwọn ìfihàn tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

Kí n má bàa ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ, a fi ẹ̀gún kan sínú ara mi,+ áńgẹ́lì Sátánì, láti máa gbá mi ní àbàrá,* kí n má bàa ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ. 8 Ẹ̀ẹ̀mẹta ni mo bẹ Olúwa nípa èyí kó lè kúrò lára mi. 9 Àmọ́, ó sọ fún mi pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ, torí à ń sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.”+ Nítorí náà, ṣe ni màá kúkú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, tí màá sì máa fi àìlera mi yangàn, kí agbára Kristi lè máa wà lórí mi bí àgọ́. 10 Torí náà, mò ń láyọ̀ nínú àìlera, nínú ìwọ̀sí, ní àkókò àìní, nínú inúnibíni àti ìṣòro, nítorí Kristi. Torí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, ìgbà náà ni mo di alágbára.+

11 Mo ti di aláìnírònú. Ẹ̀yin lẹ sì sọ mí di bẹ́ẹ̀, torí ó yẹ kí ẹ ti dámọ̀ràn mi. Nítorí kò sí ohun kankan tó fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì yín adára-má-kù-síbìkan sàn jù mí lọ, ká tiẹ̀ ní mi ò já mọ́ nǹkan kan.+ 12 Ní tòótọ́, ẹ ti rí àwọn àmì tó fi hàn pé mo jẹ́ àpọ́sítélì nínú ọ̀pọ̀ ìfaradà,+ nínú àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* àti àwọn iṣẹ́ agbára.+ 13 Nítorí ọ̀nà wo ni àǹfààní tí ẹ ní gbà kéré sí ti àwọn ìjọ yòókù, yàtọ̀ sí pé èmi fúnra mi ò sọ ara mi di ẹrù sí yín lọ́rùn?+ Ẹ dárí jì mí tinútinú lórí àìtọ́ yìí.

14 Ẹ wò ó! Ìgbà kẹta nìyí tí mo ti ṣe tán láti wá sọ́dọ̀ yín, mi ò sì ní sọ ara mi di ẹrù sí yín lọ́rùn. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ni mò ń wá, kì í ṣe àwọn ohun ìní yín;+ torí a kò retí pé kí àwọn ọmọ+ máa to nǹkan jọ fún àwọn òbí wọn, àwọn òbí ni kó máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. 15 Ní tèmi, tayọ̀tayọ̀ ni màá ná gbogbo ohun tí mo ní, màá sì ná ara mi tán pátápátá fún yín.*+ Tó bá jẹ́ pé báyìí ni mo nífẹ̀ẹ́ yín tó, ṣé ó yẹ kí ìfẹ́ tí ẹ ní fún mi kéré sí tèmi? 16 Àmọ́ bó ti wù kó rí, mi ò sọ ara mi di ẹrù sí yín lọ́rùn.+ Síbẹ̀, ẹ̀ ń sọ pé, mo jẹ́ “ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́,” mo sì ń fi “ẹ̀tàn” mú yín. 17 Mi ò fi ìkankan nínú àwọn tí mo rán sí yín yàn yín jẹ, àbí mo ṣe bẹ́ẹ̀? 18 Mo rọ Títù pé kó wá sọ́dọ̀ yín, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀. Títù ò yàn yín jẹ rárá, àbí ó ṣe bẹ́ẹ̀?+ Irú ẹ̀mí kan náà la ní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ipa ọ̀nà kan náà la sì ń rìn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

19 Ṣé ohun tí ẹ̀ ń rò látìgbà yìí wá ni pé à ń gbèjà ara wa níwájú yín? Iwájú Ọlọ́run la ti ń sọ̀rọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi. Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, ká lè gbé yín ró la fi ń ṣe gbogbo ohun tí à ń ṣe. 20 Ẹ̀rù ń bà mí pé tí mo bá dé, mo lè má bá yín bí mo ṣe fẹ́, mo sì lè má rí bí ẹ ṣe rò, dípò bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ wàhálà, owú, ìbínú ńlá, awuyewuye, sísọ̀rọ̀ ẹni láìdáa, ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,* ìgbéraga àti rúdurùdu ni màá bá nílẹ̀. 21 Ó sì tún lè jẹ́ pé tí mo bá dé, Ọlọ́run mi á dójú tì mí níwájú yín, kó sì di pé màá ṣọ̀fọ̀ lórí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí wọn ò ronú pìwà dà kúrò nínú ìwà àìmọ́ àti ìṣekúṣe* pẹ̀lú ìwà àìnítìjú* tí wọ́n hù.

13 Ìgbà kẹta nìyí tí màá wá sọ́dọ̀ yín. “Nípa ẹ̀rí* ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.”+ 2 Bí mi ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín báyìí, ṣe ló dà bíi pé mo wà pẹ̀lú yín lẹ́ẹ̀kejì, mo sì ti kìlọ̀ fún àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti fún gbogbo àwọn yòókù pé, tí mo bá tún pa dà wá, mi ò ní ṣàìbá wọn wí, 3 bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀ ń wá ẹ̀rí tó fi hàn pé Kristi, tí kì í ṣe aláìlera nínú ọ̀rọ̀ yín àmọ́ tó jẹ́ alágbára láàárín yín, ló ń gbẹnu mi sọ̀rọ̀. 4 Ní tòótọ́, wọ́n kàn án mọ́gi* nítorí àìlera, àmọ́ ó wà láàyè nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run.+ Lóòótọ́, àwa náà jẹ́ aláìlera pẹ̀lú rẹ̀, àmọ́ a máa wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀+ nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run tó wà lórí yín.+

5 Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.+ Àbí ẹ ò mọ̀ pé Jésù Kristi wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín? Àfi tí a ò bá tẹ́wọ́ gbà yín. 6 Lóòótọ́, mo retí pé ẹ máa mọ̀ pé a kì í ṣe ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà.

7 Ní báyìí, àdúrà wa sí Ọlọ́run ni pé kí ẹ má ṣe ohun tí kò tọ́, kì í ṣe torí kó lè hàn pé ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni wá, àmọ́ ó jẹ́ torí kí ẹ lè máa ṣe ohun tó dáa, kódà tó bá tiẹ̀ dà bíi pé a kì í ṣe ẹni ìtẹ́wọ́gbà. 8 Nítorí a ò lè ṣe nǹkan kan láti rẹ́yìn òtítọ́, àfi ká ṣe nǹkan láti ti òtítọ́ lẹ́yìn. 9 Inú wa máa ń dùn nígbàkigbà tí a bá jẹ́ aláìlera àmọ́ tí ẹ̀yin jẹ́ alágbára. Ohun tí a sì ń gbàdúrà fún nìyí, pé kí ẹ ṣàtúnṣe. 10 Ìdí nìyẹn tí mo fi kọ àwọn nǹkan yìí nígbà tí mi ò sí lọ́dọ̀ yín, kó lè jẹ́ pé nígbà tí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, mi ò ní le koko tí mo bá ń lo àṣẹ tí Olúwa fún mi,+ láti gbéni ró, tí kì í ṣe láti yani lulẹ̀.

11 Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ máa yọ̀, ẹ máa ṣe ìyípadà, ẹ máa gba ìtùnú,+ ẹ máa ronú níṣọ̀kan,+ ẹ máa gbé ní àlàáfíà;+ Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà+ yóò sì wà pẹ̀lú yín. 12 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. 13 Gbogbo àwọn ẹni mímọ́ kí yín.

14 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa àti ìfẹ́ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ tí à ń jọlá rẹ̀ wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Tàbí “tó ń fún wa níṣìírí.”

Tàbí “ìpọ́njú.”

Tàbí “ìpọ́njú.”

Tàbí “ìpọ́njú.”

Tàbí “nítorí ọ̀pọ̀ àwọn tó tẹ́wọ́ àdúrà.”

Tàbí kó jẹ́, “tí ẹ ti mọ̀ dáadáa, tí ẹ sì.”

Ní Grk., “títí dé òpin.”

Tàbí kó jẹ́, “kí ẹ lè jàǹfààní lẹ́ẹ̀mejì.”

Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.

Tàbí “àsansílẹ̀; ìdánilójú (ẹ̀jẹ́) ohun tó ń bọ̀.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “gbé e mì.”

Tàbí “ọgbọ́n àyínìke.”

Tàbí “èrò ọkàn; ète.”

Tàbí “gbalẹ̀ kan.”

Tàbí “òórùn dídùn.”

Tàbí “a kò fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe òwò; a kò fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ èrè.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí kó jẹ́, “gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí Jèhófà.”

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “iná.”

Tàbí “ìṣà.”

Tàbí kó jẹ́, “kì í ṣe pé ó tojú sú wa.”

Tàbí “àdánwò.”

Ní Grk., “tẹ̀wọ̀n.”

Tàbí “yọ́.”

Tàbí “ibùgbé.”

Tàbí “gbé ibùgbé wa.”

Tàbí “ibùgbé wa ọ̀run.”

Tàbí “àsansílẹ̀; ìdánilójú (ẹ̀jẹ́) ohun tó ń bọ̀.”

Tàbí “fara hàn kedere.”

Tàbí “ibi.”

Tàbí “a ò pa mọ́ fún Ọlọ́run.”

Tàbí “a ò pa mọ́ fún ẹ̀rí ọkàn ẹ̀yin náà.”

Tàbí “ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ fún ìjà.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ fún ààbò.

Tàbí “ẹni tí wọ́n gbà pé ikú tọ́ sí.”

Tàbí “bá wí.”

Tàbí “A ti bá yín sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.”

Tàbí “Àyè kò há mọ́ wa láti fìfẹ́ hàn sí yín.”

Tàbí “ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín pọ̀ sí i.”

Tàbí “so mọ́.”

Látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Tí Kò Dára fún Ohunkóhun.” Ó ń tọ́ka sí Sátánì.

Tàbí “olóòótọ́.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “ẹran ara.”

Ní Grk., “ìtara yín fún mi.”

Tàbí “pé ìwà yín mọ́; pé ọwọ́ yín mọ́.”

Tàbí kó jẹ́, “ní ìgboyà nítorí yín.”

Tàbí “lọ́pọ̀lọpọ̀.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “alájọpín.”

Tàbí “àìfẹ́ṣe.”

Tàbí “fàlàlà.”

Ní Grk., “ohun tí a jẹ́ nínú ọ̀rọ̀.”

Ní Grk., “a máa jẹ́ nínú ìṣe.”

Tàbí “wọ̀n.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “pẹ̀lú ìtara Ọlọ́run.”

Tàbí “mímọ́.”

Tàbí “ìjẹ́mímọ́.”

Ní Grk., “ja àwọn ìjọ míì lólè.”

Tàbí “ìtìlẹ́yìn.”

Tàbí “àwáwí.”

Tàbí “ipò.”

Ìyẹn, lójú ti èèyàn.

Ní Grk., “èso.”

Tàbí “iṣẹ́ àṣekára.”

Ní Grk., “ìhòòhò.”

Tàbí “ìdààmú ń bá mi lójoojúmọ́.”

Tàbí “agbọ̀n.”

Tàbí “wíńdò.”

Tàbí “máa lù mí.”

Tàbí “àwọn àmì.”

Tàbí “fún ọkàn yín.”

Tàbí “òfófó.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Grk., “Láti ẹnu.”

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́