SÍ ÀWỌN ARÁ ÉFÉSÙ
1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, sí àwọn ẹni mímọ́ tó wà ní Éfésù,+ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nínú Kristi Jésù:
2 Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa.
3 Ìyìn ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, torí ó ti fi gbogbo ìbùkún tẹ̀mí ní àwọn ibi ọ̀run jíǹkí wa nínú Kristi,+ 4 bí ó ṣe yàn wá láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀* ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé, kí a lè jẹ́ mímọ́, kí a sì wà láìní àbààwọ́n+ níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́. 5 Nítorí ó ti yàn wá ṣáájú+ kí ó lè sọ wá dọmọ+ nípasẹ̀ Jésù Kristi, torí ohun tí ó wù ú tí ó sì fẹ́ nìyẹn,+ 6 kí a lè yìn ín nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ ológo+ tó fi jíǹkí wa nípasẹ̀ àyànfẹ́ rẹ̀.+ 7 Ipasẹ̀ ìràpadà tó fi ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ san ni a fi rí ìtúsílẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa,+ nítorí ọlá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.
8 Ó mú kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí pọ̀ gidigidi fún wa nínú gbogbo ọgbọ́n àti òye* 9 bó ṣe jẹ́ ká mọ àṣírí mímọ́+ nípa ìfẹ́ rẹ̀. Èyí bá ohun tó ń wù ú mu, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣètò 10 iṣẹ́ àbójútó kan* láti kó ohun gbogbo jọ nínú Kristi nígbà tí àwọn àkókò tí a yàn bá tó, àwọn ohun tó wà ní ọ̀run àti àwọn ohun tó wà ní ayé.+ Bẹ́ẹ̀ ni, nínú ẹni 11 tí a wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, tí a sì yàn wá láti jẹ́ ajogún pẹ̀lú rẹ̀,+ ní ti pé a ti yàn wá ṣáájú nítorí ohun tí ẹni tó ń ṣe ohun gbogbo fẹ́, bí ó ṣe ń pinnu ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, 12 kí iṣẹ́ ìsìn àwa tí a kọ́kọ́ nírètí nínú Kristi lè yìn ín lógo. 13 Àmọ́ ẹ̀yin náà nírètí nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́, ìyẹn ìhìn rere nípa ìgbàlà yín. Lẹ́yìn tí ẹ gbà á gbọ́, a fi ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí gbé èdìdì lé yín+ nípasẹ̀ rẹ̀, 14 ẹ̀mí mímọ́ yìí jẹ́ àmì ìdánilójú* ogún tí à ń retí,+ kí àwọn èèyàn* Ọlọ́run lè rí ìtúsílẹ̀+ nípasẹ̀ ìràpadà,+ sí ìyìn àti ògo rẹ̀.
15 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé látìgbà tí èmi náà ti gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ tí ẹ ní nínú Jésù Olúwa àti nípa ìfẹ́ tí ẹ fi hàn sí gbogbo àwọn ẹni mímọ́, 16 mi ò yéé dúpẹ́ nítorí yín. Mo sì ń dárúkọ yín nínú àdúrà mi, 17 pé kí Ọlọ́run Olúwa wa Jésù Kristi, Baba ògo, fún yín ní ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti ìfihàn nínú ìmọ̀ tó péye nípa rẹ̀.+ 18 Ó ti la ojú inú* yín, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó pè yín láti ní, kí ẹ lè mọ ọrọ̀ ológo tó fẹ́ fi ṣe ogún fún àwọn ẹni mímọ́+ 19 àti bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ lórí àwa onígbàgbọ́ lọ́nà tó ta yọ.+ Èyí hàn nínú bí agbára ńlá rẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́, 20 nígbà tó lò ó láti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú, tó sì mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀+ ní àwọn ibi ọ̀run, 21 tí ó ga ju gbogbo ìjọba àti àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa àti gbogbo orúkọ tí à ń pè,+ kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan yìí* nìkan, àmọ́ nínú èyí tó ń bọ̀ pẹ̀lú. 22 Ó tún fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀,+ ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo nínú ìjọ,+ 23 èyí tó jẹ́ ara rẹ̀,+ tó sì jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tó ń fi ohun gbogbo kún inú ohun gbogbo.
2 Síwájú sí i, Ọlọ́run sọ yín di ààyè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àṣemáṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ yín,+ 2 nínú èyí tí ẹ ti rìn nígbà kan rí lọ́nà ti ètò àwọn nǹkan* ayé yìí,+ lọ́nà ti ẹni tó ń darí àṣẹ afẹ́fẹ́,+ ẹ̀mí+ tó ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ aláìgbọràn. 3 Òótọ́ ni pé gbogbo wa ti wà láàárín wọn rí, tí à ń hùwà lọ́nà ti ara wa,+ tí à ń ṣe ohun tí ara wa fẹ́ àti èyí tí ọkàn wa rò,+ a sì jẹ́ ọmọ ìrunú+ bíi ti àwọn yòókù látìgbà tí wọ́n ti bí wa. 4 Àmọ́ Ọlọ́run, tí àánú rẹ̀ pọ̀,+ nítorí ìfẹ́ ńlá tó ní sí wa,+ 5 sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, kódà nígbà tí a kú nínú àwọn àṣemáṣe wa,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ mú kí ẹ rí ìgbàlà. 6 Yàtọ̀ síyẹn, ó gbé wa dìde pa pọ̀, ó sì mú wa jókòó pa pọ̀ ní àwọn ibi ọ̀run ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù,+ 7 pé nínú àwọn ètò àwọn nǹkan* tó ń bọ̀, kó lè fi ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ tí ó ta yọ hàn nínú oore ọ̀fẹ́* rẹ̀ sí wa nínú Kristi Jésù.
8 Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí ti mú kí ẹ rí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́,+ èyí kì í ṣe nípa agbára yín; ẹ̀bùn Ọlọ́run ni. 9 Bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe nípa iṣẹ́,+ kí ẹnì kankan má bàa ní ìdí láti máa yangàn. 10 Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ni wá,* ó dá wa+ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù+ ká lè ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí Ọlọ́run ti ṣètò sílẹ̀ fún wa láti máa ṣe.
11 Nítorí náà, ẹ rántí pé nígbà kan, ẹ̀yin tí ẹ wá látinú àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ni àwọn tó dádọ̀dọ́* nínú ara látọwọ́ èèyàn ń pè ní aláìdádọ̀dọ́.* 12 Lákòókò yẹn, ẹ ò ní Kristi, ẹ sì jẹ́ àjèjì sí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ísírẹ́lì, ẹ tún jẹ́ àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà;+ ẹ ò nírètí, ẹ ò sì ní Ọlọ́run nínú ayé.+ 13 Àmọ́ ní báyìí, tí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù, ẹ̀yin tí ẹ ti fìgbà kan jìnnà réré ti wá wà nítòsí nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi. 14 Nítorí òun ni àlàáfíà wa,+ ẹni tó ṣe àwùjọ méjèèjì ní ọ̀kan,+ tó sì wó ògiri tó pààlà sáàárín wọn.+ 15 Ó lo ẹran ara rẹ̀ láti fòpin sí ọ̀tá náà, ìyẹn, Òfin tí àwọn àṣẹ àti ìlànà wà nínú rẹ̀, kí ó lè mú kí àwùjọ méjèèjì ṣọ̀kan pẹ̀lú ara rẹ̀, kí wọ́n lè di ẹni tuntun kan,+ kí ó sì mú àlàáfíà wá 16 àti pé kí ó lè mú àwùjọ méjèèjì wá sínú ara kan láti pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ ní kíkún nípasẹ̀ òpó igi oró,*+ nítorí ó ti fúnra rẹ̀ pa ọ̀tá náà.+ 17 Ó sì wá kéde ìhìn rere àlàáfíà fún ẹ̀yin tí ẹ jìnnà réré àti àlàáfíà fún àwọn tó wà nítòsí, 18 torí ipasẹ̀ rẹ̀ ni àwa àwùjọ méjèèjì fi lè wọlé sọ́dọ̀ Baba nípasẹ̀ ẹ̀mí kan.
19 Nítorí náà, ẹ kì í ṣe àjèjì tàbí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè mọ́,+ àmọ́ ẹ jẹ́ aráàlú+ pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì jẹ́ ara agbo ilé Ọlọ́run,+ 20 a sì ti kọ́ yín sórí ìpìlẹ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn wòlíì,+ nígbà tí Kristi Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́ òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé.+ 21 Ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ilé náà, bó ṣe so pọ̀ di ọ̀kan,+ ń dàgbà di tẹ́ńpìlì mímọ́ fún Jèhófà.*+ 22 Ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, à ń kọ́ ẹ̀yin náà pa pọ̀ láti di ibi tí Ọlọ́run á máa gbé nípasẹ̀ ẹ̀mí.+
3 Nítorí èyí, èmi, Pọ́ọ̀lù, ẹlẹ́wọ̀n + Kristi Jésù nítorí yín, ẹ̀yin èèyàn orílẹ̀-èdè, 2 tó bá jẹ́ pé òótọ́ lẹ ti gbọ́ nípa iṣẹ́ ìríjú+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fún mi nítorí yín, 3 pé a jẹ́ kí n mọ àṣírí mímọ́ nípasẹ̀ ìfihàn, bí mo ṣe kọ̀wé ní ṣókí tẹ́lẹ̀. 4 Torí náà, nígbà tí ẹ bá ka ìwé yìí, ẹ máa mọ òye tí mo ní nípa àṣírí mímọ́+ Kristi. 5 Ní àwọn ìran ìṣáájú, a kò fi àṣírí yìí han àwọn ọmọ èèyàn bí a ṣe fi han àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí lásìkò yìí,+ 6 ìyẹn ni pé, nínú Kristi Jésù àti nípasẹ̀ ìhìn rere, kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lè di ajùmọ̀jogún, kí a jọ jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà,+ kí a sì jọ pín nínú ìlérí náà. 7 Mo di òjíṣẹ́ àṣírí mímọ́ yìí* nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. Ó fún mi ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nígbà tó fún mi ní agbára rẹ̀.+
8 Èmi, tí mo kéré ju ẹni tó kéré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́,+ la fún ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí,+ kí n lè kéde ìhìn rere nípa ọrọ̀ Kristi tí kò ṣeé díwọ̀n fún àwọn orílẹ̀-èdè, 9 kí n sì mú kí gbogbo èèyàn rí bí Ọlọ́run, ẹni tó dá ohun gbogbo, ṣe ń bójú tó àṣírí mímọ́+ tí a ti fi pa mọ́ tipẹ́tipẹ́. 10 Èyí rí bẹ́ẹ̀ kó lè jẹ́ pé ní báyìí, nípasẹ̀ ìjọ,+ kí a lè sọ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run fún àwọn alákòóso àti àwọn aláṣẹ ní àwọn ibi ọ̀run.+ 11 Èyí bá ìpinnu rẹ̀ ayérayé mu, tí ó ṣe ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi,+ Jésù Olúwa wa, 12 ẹni tó jẹ́ ká ní òmìnira yìí láti sọ̀rọ̀ fàlàlà, kí ọkàn wa sì balẹ̀ láti wọlé sọ́dọ̀ Ọlọ́run,+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀. 13 Nítorí náà, mo sọ fún yín pé kí ẹ má juwọ́ sílẹ̀ nítorí àwọn ìpọ́njú tí mo ní lórí yín, torí wọ́n ń yọrí sí ògo fún yín.+
14 Nítorí èyí, mo tẹ eékún mi ba fún Baba, 15 lọ́dọ̀ ẹni tí gbogbo ìdílé ní ọ̀run àti ní ayé ti gba orúkọ rẹ̀. 16 Mo gbàdúrà pé, nínú ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó jẹ́ kí a lè fi agbára ẹ̀mí rẹ̀ sọ yín di alágbára nínú ẹni tí ẹ jẹ́ ní inú,+ 17 àti pé nípa ìgbàgbọ́ yín, kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín pẹ̀lú ìfẹ́.+ Kí ẹ ta gbòǹgbò,+ kí ẹ sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà,+ 18 kí ẹ̀yin pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ lè lóye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn náà jẹ́, 19 kí ẹ sì mọ ìfẹ́ Kristi+ tó ré kọjá ìmọ̀, kí a lè fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń fúnni kún inú yín.
20 Ní báyìí, fún ẹni tó lè ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ju ohun tó ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn,+ gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ nínú wa,+ 21 òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ nípasẹ̀ ìjọ àti nípasẹ̀ Kristi Jésù títí dé gbogbo ìran láé àti láéláé. Àmín.
4 Nítorí náà, èmi, ẹlẹ́wọ̀n+ nínú Olúwa, pàrọwà fún yín láti máa rìn lọ́nà tó yẹ+ pípè tí a pè yín, 2 pẹ̀lú gbogbo ìrẹ̀lẹ̀*+ àti ìwà tútù, pẹ̀lú sùúrù,+ kí ẹ máa fara dà á fún ara yín nínú ìfẹ́,+ 3 kí ẹ máa sapá lójú méjèèjì láti pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.+ 4 Ara kan ló wà+ àti ẹ̀mí kan,+ bó ṣe jẹ́ pé ìrètí kan ṣoṣo + la pè yín sí; 5 Olúwa kan,+ ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan; 6 Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo èèyàn, tó wà lórí ohun gbogbo, tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ohun gbogbo àti nínú ohun gbogbo.
7 A fún kálukú wa ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí bí Kristi ṣe díwọ̀n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ náà fúnni.+ 8 Torí ó sọ pé: “Nígbà tó gòkè lọ sí ibi gíga, ó kó àwọn èèyàn lẹ́rú; ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.”+ 9 Tóò, kí ni gbólóhùn náà pé “ó gòkè” túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé ó ti kọ́kọ́ wá sísàlẹ̀, ìyẹn sí ayé. 10 Ẹni tó sọ̀ kalẹ̀ náà ni ẹni tó tún gòkè+ kọjá gbogbo ọ̀run,+ kí ó lè mú ohun gbogbo ṣẹ.
11 Ó fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bíi wòlíì,+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere,*+ àwọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́,+ 12 láti tọ́ àwọn ẹni mímọ́ sọ́nà,* fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, láti gbé ara Kristi ró,+ 13 títí gbogbo wa á fi ṣọ̀kan* nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé* ọkùnrin,+ tí a ó sì dàgbà dé ìwọ̀n kíkún ti Kristi. 14 Torí náà, kò yẹ ká jẹ́ ọmọdé mọ́, tí à ń gbá kiri bí ìgbì òkun ṣe ń gbá nǹkan kiri, tí gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn àwọn èèyàn sì ń gbá síbí sọ́hùn-ún+ nípasẹ̀ ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí a fi hùmọ̀ ẹ̀tàn. 15 Àmọ́ nípa sísọ òótọ́, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tó jẹ́ orí, ìyẹn Kristi.+ 16 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara+ ti para pọ̀ di ọ̀kan, tí a sì mú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tó ń pèsè ohun tí a nílò. Tí ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, èyí á mú kí ara máa dàgbà sí i bó ṣe ń gbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.+
17 Nítorí náà, ohun tí màá sọ, tí màá sì jẹ́rìí sí nínú Olúwa ni pé kí ẹ má ṣe rìn mọ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń rìn,+ torí inú èrò asán* ni wọ́n ti ń rìn.+ 18 Ìrònú wọn ti ṣókùnkùn, wọ́n sì ti di àjèjì sí ìyè tó jẹ́ ti Ọlọ́run, torí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan àti nítorí ọkàn wọn ti yigbì.* 19 Bí wọ́n ṣe wá kọjá gbogbo òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìnítìjú*+ láti máa fi ojúkòkòrò hu oríṣiríṣi ìwà àìmọ́.
20 Àmọ́, ẹ ò mọ Kristi sírú ẹni bẹ́ẹ̀, 21 tó bá jẹ́ pé òótọ́ lẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a sì tipasẹ̀ rẹ̀ kọ́ yín, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ṣe wà nínú Jésù. 22 Ẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kí ẹ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀,+ èyí tó bá ọ̀nà ìgbésí ayé yín ti tẹ́lẹ̀ mu, tí àwọn ìfẹ́ rẹ̀ tó ń tanni jẹ sì ń sọ di ìbàjẹ́.+ 23 Torí náà, ẹ máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú yín,*+ 24 kí ẹ sì gbé ìwà tuntun wọ̀,+ èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.
25 Torí náà, ní báyìí tí ẹ ti fi ẹ̀tàn sílẹ̀, kí kálukú yín máa bá ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́,+ nítorí ẹ̀yà ara kan náà ni wá.+ 26 Tí inú bá bí yín, ẹ má ṣẹ̀;+ ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ìbínú;+ 27 ẹ má gba Èṣù láyè.*+ 28 Kí ẹni tó ń jalè má jalè mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, kó máa ṣiṣẹ́ kára, kó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere,+ kó lè ní nǹkan tó máa fún ẹni tí kò ní.+ 29 Kí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́* má ṣe ti ẹnu yín jáde,+ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró nìkan ni kí ẹ máa sọ bó bá ṣe yẹ, kí ó lè ṣe àwọn tó ń gbọ́ yín láǹfààní.+ 30 Bákan náà, ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn ọkàn* bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run,+ èyí tí a fi gbé èdìdì lé+ yín fún ọjọ́ ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.+
31 Ẹ mú gbogbo inú burúkú,+ ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín,+ títí kan gbogbo ohun tó lè ṣeni léṣe.+ 32 Àmọ́ ẹ jẹ́ onínúure sí ara yín, kí ẹ máa ṣàánú,+ kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà bí Ọlọ́run náà ṣe tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.+
5 Nítorí náà, ẹ máa fara wé Ọlọ́run,+ bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ, 2 kí ẹ sì máa rìn nínú ìfẹ́,+ bí Kristi pẹ̀lú ṣe nífẹ̀ẹ́ wa,*+ tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún wa* bí ọrẹ àti ẹbọ, tó jẹ́ òórùn dídùn sí Ọlọ́run.+
3 Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ìṣekúṣe* àti ìwà àìmọ́ èyíkéyìí tàbí ojúkòkòrò láàárín yín,+ bí ó ṣe yẹ àwọn èèyàn mímọ́;+ 4 bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà àìnítìjú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ẹ̀fẹ̀ rírùn,+ àwọn ohun tí kò yẹ, dípò bẹ́ẹ̀ kí ẹ máa dúpẹ́.+ 5 Nítorí ẹ mọ èyí, ó sì ṣe kedere sí ẹ̀yin fúnra yín, pé kò sí oníṣekúṣe* kankan+ tàbí aláìmọ́ tàbí olójúkòkòrò,+ tó túmọ̀ sí jíjẹ́ abọ̀rìṣà, tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú Ìjọba Kristi àti ti Ọlọ́run.+
6 Ẹ má ṣe jẹ́ kí èèyàn kankan fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ, ìdí ni pé torí irú àwọn nǹkan yìí ni ìrunú Ọlọ́run ṣe ń bọ̀ lórí àwọn ọmọ aláìgbọràn. 7 Nítorí náà, ẹ má ṣe di alájọpín pẹ̀lú wọn; 8 nítorí pé ẹ jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí, àmọ́ ẹ ti di ìmọ́lẹ̀+ báyìí nínú Olúwa.+ Ẹ máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀, 9 nítorí pé oríṣiríṣi ohun rere àti òdodo àti òtítọ́ ló jẹ́ èso ìmọ́lẹ̀.+ 10 Ẹ máa wádìí dájú ohun tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà;+ 11 ẹ sì jáwọ́ nínú àwọn iṣẹ́ tí kò lérè tó jẹ́ ti òkùnkùn;+ ṣe ni kí ẹ tú wọn fó. 12 Torí pé àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe níkọ̀kọ̀ ń tini lójú láti sọ. 13 Gbogbo nǹkan tí à ń tú síta* ni ìmọ́lẹ̀ ń fi hàn kedere, torí pé gbogbo ohun tí à ń fi hàn kedere jẹ́ ìmọ́lẹ̀. 14 Torí náà la ṣe sọ pé: “Jí, ìwọ olóorun, sì dìde láti inú ikú,+ Kristi yóò sì tàn sórí rẹ.”+
15 Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, 16 kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ,*+ torí pé àwọn ọjọ́ burú. 17 Torí náà, ẹ yéé ṣe bí aláìnírònú, àmọ́ ẹ máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà* jẹ́.+ 18 Bákan náà, ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara,+ torí ó ń yọrí sí ìwà pálapàla,* àmọ́ ẹ máa kún fún ẹ̀mí. 19 Ẹ máa fi àwọn sáàmù àti ìyìn sí Ọlọ́run àti àwọn orin ẹ̀mí bá ara yín sọ̀rọ̀, kí ẹ máa kọrin+ sí Jèhófà,*+ kí ẹ sì máa fi ohùn orin+ gbè é nínú ọkàn yín, 20 ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo+ lọ́wọ́ Ọlọ́run, Baba wa lórí ohun gbogbo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi.+
21 Ẹ máa tẹrí ba fún ara yín+ nínú ìbẹ̀rù Kristi. 22 Kí àwọn aya máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ+ wọn bíi fún Olúwa, 23 nítorí ọkọ ni orí aya rẹ̀+ bí Kristi ṣe jẹ́ orí ìjọ,+ òun sì ni olùgbàlà ara yìí. 24 Kódà, bí ìjọ ṣe ń tẹrí ba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya máa ṣe fún àwọn ọkọ wọn nínú ohun gbogbo. 25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín,+ bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún un,+ 26 kí ó lè sọ ọ́ di mímọ́, kí ó fi omi wẹ̀ ẹ́ mọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà,+ 27 kí ó lè mú ìjọ wá síwájú ara rẹ̀ nínú ògo, láìní ìdọ̀tí kan tàbí ìhunjọ kan tàbí èyíkéyìí nínú irú àwọn nǹkan yìí,+ àmọ́ kí ó jẹ́ mímọ́ kí ó má sì lábààwọ́n.+
28 Lọ́nà kan náà, kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn bí ara wọn. Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, 29 torí pé kò sí èèyàn kankan tó jẹ́ kórìíra ara* rẹ̀, àmọ́ á máa bọ́ ara rẹ̀, á sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, bí Kristi ti ń ṣe sí ìjọ, 30 nítorí a jẹ́ ẹ̀yà ara rẹ̀.+ 31 “Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́* ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì á sì di ara kan.”+ 32 Àṣírí mímọ́+ yìí ga lọ́lá. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ nípa Kristi àti ìjọ ni mò ń sọ.+ 33 Síbẹ̀, kálukú yín gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀+ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; bákan náà, kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.+
6 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu+ nínú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo. 2 “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,”+ èyí ni àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: 3 “Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ,* kí o sì lè pẹ́ láyé.” 4 Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú,+ kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí+ àti ìmọ̀ràn* Jèhófà.*+
5 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn ọ̀gá yín* lẹ́nu,+ pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nínú òótọ́ ọkàn, gẹ́gẹ́ bíi sí Kristi, 6 kì í ṣe nígbà tí wọ́n bá ń wò yín nìkan, torí kí ẹ lè tẹ́ èèyàn lọ́rùn,*+ àmọ́ bí ẹrú Kristi, tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn.*+ 7 Ẹ máa hùwà rere bí ẹ ṣe ń ṣẹrú, bíi pé fún Jèhófà,*+ kì í ṣe fún èèyàn, 8 nítorí ẹ mọ̀ pé, ohun rere èyíkéyìí tí kálukú bá ṣe, ó máa gbà á pa dà lọ́dọ̀ Jèhófà,*+ onítọ̀hún ì báà jẹ́ ẹrú tàbí òmìnira. 9 Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa hùwà sí wọn lọ́nà kan náà, ẹ má ṣe máa halẹ̀ mọ́ wọn, torí ẹ mọ̀ pé Ọ̀gá wọn àti tiyín wà ní ọ̀run,+ kì í sì í ṣojúsàájú.
10 Paríparí rẹ̀, ẹ máa gba agbára+ nínú Olúwa àti nínú títóbi okun rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun+ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ lè dúró gbọn-in láti dojú kọ àwọn àrékérekè* Èṣù; 12 nítorí a ní ìjà* kan,+ kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, àmọ́ ó jẹ́ pẹ̀lú àwọn alákòóso, pẹ̀lú àwọn aláṣẹ, pẹ̀lú àwọn alákòóso ayé òkùnkùn yìí, pẹ̀lú agbo ọmọ ogun àwọn ẹ̀mí burúkú+ ní àwọn ibi ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀,+ kí ẹ lè jà ní ọjọ́ burúkú náà, lẹ́yìn tí ẹ bá sì ti ṣe ohun gbogbo parí, kí ẹ lè dúró gbọn-in.
14 Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ fi òtítọ́ di inú yín lámùrè,+ kí ẹ sì gbé àwo ìgbàyà òdodo wọ̀,+ 15 pẹ̀lú ẹsẹ̀ yín tí a wọ̀ ní bàtà, kí ẹ lè fi ìmúratán kéde ìhìn rere àlàáfíà.+ 16 Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan yìí, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́,+ tí ẹ ó fi lè paná gbogbo ọfà* oníná ti ẹni burúkú náà.+ 17 Bákan náà, ẹ gba akoto* ìgbàlà+ àti idà ẹ̀mí, ìyẹn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ 18 pẹ̀lú onírúurú àdúrà + àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, ẹ máa gbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.+ Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ wà lójúfò, kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo nítorí gbogbo àwọn ẹni mímọ́. 19 Ẹ máa gbàdúrà fún èmi náà, kí a lè fún mi lọ́rọ̀ sọ tí mo bá la ẹnu mi, kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tí mo bá ń sọ àṣírí mímọ́ ìhìn rere,+ 20 èyí tí mo torí rẹ̀ jẹ́ ikọ̀+ tí a fi ẹ̀wọ̀n dè, kí n lè máa fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bó ṣe yẹ.
21 Kí ẹ lè mọ̀ nípa mi àti bí mo ṣe ń ṣe sí, Tíkíkù,+ arákùnrin ọ̀wọ́n, tó tún jẹ́ òjíṣẹ́ olóòótọ́ nínú Olúwa, yóò sọ gbogbo rẹ̀ fún yín.+ 22 Torí èyí ni mo ṣe ń rán an sí yín, kí ẹ lè mọ bí a ṣe ń ṣe sí, kí ó sì lè tu ọkàn yín lára.
23 Kí àwọn ará ní àlàáfíà àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ Baba àti Jésù Kristi Olúwa. 24 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tó ní ìfẹ́ tí kò lè ṣá fún Olúwa wa Jésù Kristi.
Ìyẹn, Kristi.
Tàbí “làákàyè.”
Tàbí “láti máa bójú tó àwọn nǹkan.”
Tàbí “àsansílẹ̀; ìdánilójú (ẹ̀jẹ́) ohun tó ń bọ̀.”
Ní Grk., “ohun ìní.”
Ní Grk., “ojú ọkàn.”
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ipa ọ̀nà.”
Tàbí “àwọn àsìkò.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “inú rere.”
Tàbí “Àwa jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àfikún A5.
Ní Grk., “òjíṣẹ́ èyí.”
Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
Tàbí “akéde ìhìn rere.”
Tàbí “dá àwọn ẹni mímọ́ lẹ́kọ̀ọ́.”
Tàbí “wà ní ìrẹ́pọ̀.”
Tàbí “àgbà.”
Tàbí “òfo; òtúbáńtẹ́.”
Ní Grk., “gíràn-án.”
Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ipá tó ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́.” Ní Grk., “ẹ̀mí èrò inú yín.”
Tàbí “bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má fàyè sílẹ̀ fún Èṣù.”
Ní Grk., “ọ̀rọ̀ tó ti jẹrà.”
Tàbí “ìbànújẹ́.”
Tàbí kó jẹ́, “yín.”
Tàbí kó jẹ́, “yín.”
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
Tàbí “bá wí.”
Ní Grk., “máa ra àkókò pa dà.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “àìníjàánu.”
Wo Àfikún A5.
Ní Grk., “ẹran ara.”
Tàbí “dúró ti.”
Tàbí “Kí o lè láásìkí.”
Tàbí “ẹ̀kọ́; ìtọ́sọ́nà.” Ní Grk., “fífi ọkàn sí.”
Wo Àfikún A5.
Ní Grk., “ọ̀gá yín nípa tara.”
Ní Grk., “kì í ṣe àrójúṣe bíi ti àwọn tó máa ń fẹ́ wu èèyàn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ètekéte.”
Ní Grk., “gídígbò.”
Tàbí “ohun ọṣẹ́.”
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.