SÍ TÍTÙ
1 Pọ́ọ̀lù, ẹrú Ọlọ́run àti àpọ́sítélì Jésù Kristi, tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ bá ti àwọn tí Ọlọ́run yàn mu, tó sì bá ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ àti ìfọkànsin Ọlọ́run mu, 2 èyí tó dá lórí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun+ tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè parọ́,+ ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́; 3 àmọ́ nígbà tí àkókò tó lójú rẹ̀, ó jẹ́ kí a mọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tó fi lé mi lọ́wọ́,+ èyí tí Olùgbàlà wa, Ọlọ́run pa láṣẹ; 4 sí Títù, ọmọ gidi tí a jọ jẹ́ onígbàgbọ́:
Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti ti Kristi Jésù Olùgbàlà wa máa wà pẹ̀lú rẹ.
5 Mo fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí o lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí kò tọ́,* kí o sì lè yan àwọn alàgbà láti ìlú dé ìlú, bí mo ṣe sọ fún ọ pé kí o ṣe: 6 bí ọkùnrin èyíkéyìí bá wà tí kò ní ẹ̀sùn lọ́rùn, tí kò ní ju ìyàwó kan lọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọn kò sì ní ẹ̀sùn lọ́rùn pé wọ́n jẹ́ oníwà pálapàla* tàbí ọlọ̀tẹ̀.+ 7 Torí pé alábòójútó jẹ́ ìríjú Ọlọ́run, kò gbọ́dọ̀ ní ẹ̀sùn lọ́rùn, kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń ṣe tinú ara rẹ̀,+ kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń tètè bínú,+ kó má ṣe jẹ́ ọ̀mùtípara, kó má ṣe jẹ́ oníwà ipá,* kó má sì jẹ́ ẹni tó máa ń wá èrè tí kò tọ́, 8 àmọ́ kó jẹ́ ẹni tó ń ṣe aájò àlejò,+ tó nífẹ̀ẹ́ ohun rere, tó ní àròjinlẹ̀,*+ tó jẹ́ olódodo, olóòótọ́,+ tó máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu,+ 9 ẹni tó ń di ọ̀rọ̀ òtítọ́* mú ṣinṣin nínú ọ̀nà tó ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́,*+ kó lè fi ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní*+ gbani níyànjú* kó sì bá àwọn tó ń ṣàtakò wí.+
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ọlọ̀tẹ̀ èèyàn ló wà, àwọn tó ń sọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́tàn, pàápàá àwọn tó ń rin kinkin mọ́ ìdádọ̀dọ́.*+ 11 Rí i dájú pé o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, torí àwọn èèyàn yìí ń ba ìgbàgbọ́ àwọn agbo ilé jẹ́ bí wọ́n ṣe ń kọ́ni ní àwọn ohun tí kò yẹ torí wọ́n ń wá èrè tí kò tọ́. 12 Ọ̀kan lára wọn tó jẹ́ wòlíì wọn sọ pé: “Òpùrọ́ paraku ni àwọn ará Kírétè, ẹranko ni wọ́n, ọ̀lẹ alájẹkì.”
13 Òótọ́ ni ẹ̀rí yìí. Torí náà, máa bá wọn wí lọ́nà tó múná, kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára, 14 kí wọ́n má ṣe fiyè sí ìtàn àròsọ àwọn Júù àti àṣẹ àwọn èèyàn tí wọ́n ti kúrò nínú òtítọ́. 15 Ohun gbogbo ni ó mọ́ fún àwọn tí ó mọ́.+ Àmọ́ fún àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìnígbàgbọ́, kò sí ohun tí ó mọ́, torí èrò inú wọn àti ẹ̀rí ọkàn wọn jẹ́ ẹlẹ́gbin.+ 16 Wọ́n sọ ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, àmọ́ iṣẹ́ wọn fi hàn pé wọ́n kọ̀ ọ́,+ torí wọ́n jẹ́ ẹni ìkórìíra àti aláìgbọràn, wọn kò sì yẹ fún iṣẹ́ rere kankan.
2 Àmọ́ ní tìrẹ, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ máa bá ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní* mu.+ 2 Kí àwọn àgbà ọkùnrin má ṣe jẹ́ aláṣejù, kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan, ẹni tó ní àròjinlẹ̀, tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára, tí ìfẹ́ rẹ̀ jinlẹ̀, tó sì ní ìfaradà. 3 Bákan náà, kí àwọn àgbà obìnrin jẹ́ ẹni tó ń bọ̀wọ̀ fúnni, kí wọ́n má ṣe jẹ́ abanijẹ́, kí wọ́n má ṣe jẹ́ ọ̀mùtí, kí wọ́n máa kọ́ni ní ohun rere, 4 kí wọ́n lè máa gba àwọn ọ̀dọ́bìnrin níyànjú* láti nífẹ̀ẹ́ ọkọ wọn, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, 5 láti jẹ́ aláròjinlẹ̀, oníwà mímọ́, ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ilé,* ẹni rere, tó ń tẹrí ba fún ọkọ,+ kí àwọn èèyàn má bàa sọ̀rọ̀ àbùkù sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
6 Bákan náà, máa gba àwọn ọ̀dọ́kùnrin níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ aláròjinlẹ̀.+ 7 Ní gbogbo ọ̀nà, jẹ́ àpẹẹrẹ nínú àwọn iṣẹ́ rere. Máa fọwọ́ pàtàkì mú kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí kò lábààwọ́n,*+ 8 máa lo ọ̀rọ̀ tó dáa* tí wọn kò lè ṣàríwísí rẹ̀;+ kí ojú lè ti àwọn alátakò, kí wọ́n má sì rí ohun tí kò dáa* sọ nípa wa.+ 9 Kí àwọn ẹrú máa tẹrí ba fún àwọn ọ̀gá wọn nínú ohun gbogbo,+ kí wọ́n máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọ́n má sì gbó wọn lẹ́nu, 10 kí wọ́n má ṣe jí nǹkan wọn,+ ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tí èèyàn lè fọkàn tán pátápátá, kí wọ́n lè túbọ̀ ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ọ̀nà.+
11 Nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ti hàn kedere, kí onírúurú èèyàn lè rí ìgbàlà.+ 12 Èyí ń kọ́ wa pé ká kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ìfẹ́ ayé sílẹ̀,+ ká sì máa fi àròjinlẹ̀, òdodo àti ìfọkànsìn Ọlọ́run gbé nínú ètò àwọn nǹkan yìí,*+ 13 bí a ti ń dúró de àwọn ohun aláyọ̀ tí à ń retí+ àti bí Ọlọ́run Olódùmarè ṣe máa fara hàn nínú ògo pẹ̀lú Olùgbàlà wa, Jésù Kristi, 14 ẹni tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ nítorí wa+ kó lè tú wa sílẹ̀*+ kúrò nínú gbogbo onírúurú ìwà tí kò bófin mu, kó sì wẹ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́, àwọn ohun ìní rẹ̀ pàtàkì, tí wọ́n ní ìtara fún iṣẹ́ rere.+
15 Máa sọ nǹkan wọ̀nyí, máa gbani níyànjú, kí o sì máa fi gbogbo àṣẹ tí o ní bá wọn wí.+ Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan fojú kéré rẹ.
3 Máa rán wọn létí pé kí wọ́n máa tẹrí ba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ, kí wọ́n máa ṣègbọràn sí wọn,+ kí wọ́n sì múra tán láti máa ṣe iṣẹ́ rere gbogbo, 2 kí wọ́n má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan láìdáa, kí wọ́n má ṣe jẹ́ oníjà, kí wọ́n máa fòye báni lò,+ kí wọ́n jẹ́ oníwà tútù sí gbogbo èèyàn.+ 3 Nítorí nígbà kan rí, àwa náà jẹ́ aláìnírònú, aláìgbọràn, ẹni tí wọ́n ṣì lọ́nà, tó sọ ara rẹ̀ di ẹrú oríṣiríṣi ìfẹ́ ọkàn àti adùn, tó ń hu ìwà búburú tó sì ń ṣe ìlara, àwọn èèyàn kórìíra wa, a sì kórìíra ọmọnìkejì wa.
4 Àmọ́ nígbà tí Olùgbàlà wa Ọlọ́run, fi inú rere+ àti ìfẹ́ tó ní sí aráyé hàn, 5 (kì í ṣe torí iṣẹ́ òdodo kankan tí a ṣe,+ ṣùgbọ́n torí àánú rẹ̀),+ ó gbà wá là nípasẹ̀ ìwẹ̀ tó mú ká ní ìyè+ àti bó ṣe sọ wá di tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+ 6 Ó tú ẹ̀mí yìí sórí wa ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́* nípasẹ̀ Jésù Kristi Olùgbàlà wa,+ 7 kó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ bá ti sọ wá di olódodo,+ a ó lè di ajogún+ ìyè àìnípẹ̀kun tí à ń retí.+
8 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbára lé, mo sì fẹ́ kí o máa tẹnu mọ́ nǹkan wọ̀nyí, kí àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ lè máa ronú lórí ṣíṣe iṣẹ́ rere nígbà gbogbo. Àwọn nǹkan yìí dára, wọ́n sì ń ṣeni láǹfààní.
9 Ṣùgbọ́n má ṣe bá ẹnikẹ́ni fa ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání àti ọ̀rọ̀ ìtàn ìdílé, má sì dá sí ìjiyàn àti ìjà lórí Òfin, torí wọn kò lérè, wọn kò sì wúlò.+ 10 Tí ẹnì kan bá ń gbé ẹ̀ya ìsìn lárugẹ,+ tí o sì ti kìlọ̀ fún un* lẹ́ẹ̀kíní àti lẹ́ẹ̀kejì,+ ṣe ni kí o yẹra fún un,+ 11 torí o mọ̀ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kúrò lójú ọ̀nà, ó sì ń dẹ́ṣẹ̀, ìwà rẹ̀ sì ti dá a lẹ́jọ́.
12 Nígbà tí mo bá rán Átémásì tàbí Tíkíkù + sí ọ, rí i pé o wá bá mi ní Nikopólísì, torí ibẹ̀ ni mo fẹ́ wà ní ìgbà òtútù. 13 Tún rí i pé o fún Sénásì, ẹni tó mọ Òfin dunjú àti Àpólò ní ohun tí wọ́n nílò kí wọ́n má bàa ṣaláìní ohunkóhun lẹ́nu ìrìn àjò wọn.+ 14 Àmọ́, ó yẹ kí àwọn èèyàn wa tún kẹ́kọ̀ọ́ láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kí wọ́n lè máa ṣèrànwọ́ nígbà tí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì bá wáyé,+ kí wọ́n bàa lè máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní.*+
15 Gbogbo àwọn tó wà lọ́dọ̀ mi kí ọ. Bá mi kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa tí a jọ jẹ́ onígbàgbọ́.
Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wà pẹ̀lú gbogbo yín.
Tàbí “tó jẹ́ àbùkù.”
Tàbí “ewèlè.”
Tàbí “aluni.”
Tàbí “làákàyè; ọgbọ́n.”
Tàbí “ọ̀rọ̀ tó ṣeé gbára lé.”
Tàbí “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.”
Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”
Tàbí “fúnni níṣìírí.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”
Tàbí “pe orí wọn wálé; kọ́ wọn.”
Tàbí “tọ́jú ilé.”
Tàbí kó jẹ́, “kíkọ́ni láìlábààwọ́n.”
Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”
Tàbí “ohun búburú.”
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “rà wá pa dà; gbà wá sílẹ̀.”
Tàbí “lọ́pọ̀lọpọ̀.”
Tàbí “bá a wí.”
Ní Grk., “má bàa di aláìléso.”