ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 1 Pétérù 1:1-5:14
  • 1 Pétérù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1 Pétérù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Pétérù

ÌWÉ KÌÍNÍ PÉTÉRÙ

1 Pétérù, àpọ́sítélì+ Jésù Kristi, sí ẹ̀yin olùgbé fún ìgbà díẹ̀* tí ẹ wà káàkiri Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà,+ Éṣíà àti Bítíníà, sí ẹ̀yin àyànfẹ́ 2 gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọlọ́run tó jẹ́ Baba ti mọ̀ tẹ́lẹ̀,+ tí ẹ̀mí sọ di mímọ́,+ kí ẹ lè ṣègbọràn, kí a sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi sí yín lára:+

Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà yín máa pọ̀ sí i.

3 Ẹ yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, torí nínú àánú rẹ̀ tó pọ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun+ ká lè ní ìrètí tó wà láàyè+ nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi kúrò nínú ikú,+ 4 ká lè ní ogún tí kì í bà jẹ́, tí kò lábààwọ́n, tí kò sì lè ṣá.+ A tọ́jú rẹ̀ sí ọ̀run de ẹ̀yin+ 5 tí agbára Ọlọ́run dáàbò bò nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ fún ìgbàlà kan tí a ṣe tán láti ṣí payá ní àkókò ìkẹyìn. 6 Ẹ̀ ń yọ̀ gidigidi nítorí èyí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀, ó lè pọn dandan kí oríṣiríṣi àdánwò kó ìdààmú bá yín,+ 7 kí ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò+ ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó, èyí tó níye lórí gidigidi ju wúrà tó máa ń ṣègbé láìka pé a fi iná dá an wò* sí, lè jẹ́ orísun ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìfihàn Jésù Kristi.+ 8 Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i báyìí, síbẹ̀ ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, inú yín sì ń dùn gan-an, ayọ̀ yín kọjá àfẹnusọ, ó sì jẹ́ ológo, 9 bí ọwọ́ yín ṣe ń tẹ èrè ìgbàgbọ́ yín, ìgbàlà yín.*+

10 Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó jẹ́ tiyín, fara balẹ̀ wádìí, wọ́n sì fẹ̀sọ̀ wá a.+ 11 Wọn ò yéé wádìí àkókò náà gan-an tàbí ìgbà tí ẹ̀mí tó wà nínú wọn ń tọ́ka sí nípa Kristi,+ bó ṣe jẹ́rìí ṣáájú nípa àwọn ìyà tí Kristi máa jẹ+ àti ògo tó máa tẹ̀ lé e. 12 A ṣí i payá fún wọn pé wọ́n ń ṣe òjíṣẹ́, kì í ṣe fún ara wọn, àmọ́ fún yín, nípa àwọn ohun tí àwọn tó kéde ìhìn rere fún yín ti wá sọ fún yín nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ tó wá láti ọ̀run.+ Ó wu àwọn áńgẹ́lì gan-an pé kí wọ́n wo àwọn nǹkan yìí fínnífínní.

13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́;+ ẹ máa ronú bó ṣe tọ́ nígbà gbogbo;  + ẹ máa retí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a máa fún yín nígbà ìfihàn Jésù Kristi. 14 Bí ọmọ tó ń ṣègbọràn, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí tẹ́lẹ̀ torí àìmọ̀kan yín tún máa darí yín,* 15 àmọ́ bíi ti Ẹni Mímọ́ tó pè yín, kí ẹ̀yin náà di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín,+ 16 nítorí a ti kọ ọ́ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, torí èmi jẹ́ mímọ́.”+

17 Tí ẹ bá sì ń ké pe Baba tó ń fi iṣẹ́ ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣèdájọ́ láìṣe ojúsàájú,+ ẹ máa fi ìbẹ̀rù hùwà+ ní àkókò tí ẹ fi jẹ́ olùgbé fún ìgbà díẹ̀.* 18 Torí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe àwọn ohun tó lè bà jẹ́, bíi fàdákà tàbí wúrà la fi tú yín sílẹ̀,*+ kúrò nínú ìgbésí ayé asán tí àwọn baba ńlá yín fi lé yín lọ́wọ́.* 19 Ẹ̀jẹ̀ iyebíye ni,+ bí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò ní àbààwọ́n, tí kò sì ní èérí kankan,+ ìyẹn ẹ̀jẹ̀ Kristi.+ 20 Lóòótọ́, a ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀, ká tó fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀,+ àmọ́ nítorí yín, a wá fi hàn kedere ní ìparí àwọn àkókò.+ 21 Nípasẹ̀ rẹ̀ lẹ gba Ọlọ́run gbọ́,+ ẹni tó jí i dìde nínú ikú,+ tó sì fún un ní ògo,+ kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà nínú Ọlọ́run.

22 Ní báyìí tí ẹ ti fi ìgbọràn yín sí òtítọ́ wẹ ara yín* mọ́, tí èyí sì mú kí ẹ ní ìfẹ́ ará láìsí ẹ̀tàn,+ kí ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara yín látọkàn wá.+ 23 Torí a ti fún yín ní ìbí tuntun,+ kì í ṣe nípasẹ̀ irúgbìn* tó lè bà jẹ́, àmọ́ nípasẹ̀ irúgbìn tí kò lè bà jẹ́,+ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè, tó wà títí láé.+ 24 Torí “gbogbo ẹran ara* dà bíi koríko, gbogbo ògo rẹ̀ sì dà bí ìtànná àwọn ewéko; koríko máa ń gbẹ, òdòdó sì máa ń rẹ̀ dà nù, 25 àmọ́ ọ̀rọ̀* Jèhófà* wà títí láé.”+ “Ọ̀rọ̀”* yìí ni ìhìn rere tí a kéde rẹ̀ fún yín.+

2 Nítorí náà, ẹ jáwọ́ nínú gbogbo ìwà burúkú,+ ẹ̀tàn, àgàbàgebè àti owú, ẹ má sì sọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni láìdáa. 2 Bíi ti ìkókó,+ ẹ jẹ́ kí wàrà tí kò lábùlà* tó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà máa wù yín gan-an, kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀,+ 3 tí ẹ bá ti tọ́ ọ wò* pé onínúure ni Olúwa.

4 Bí ẹ ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tó jẹ́ òkúta ààyè tí àwọn èèyàn kọ̀ sílẹ̀,+ àmọ́ tó jẹ́ àyànfẹ́, tó sì ṣeyebíye lójú Ọlọ́run,+ 5 bí àwọn òkúta ààyè, à ń fi ẹ̀yin pẹ̀lú kọ́ ilé tẹ̀mí+ kí ẹ lè di ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́, kí ẹ lè máa rú àwọn ẹbọ ẹ̀mí+ tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ Jésù Kristi.+ 6 Torí Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Wò ó! Màá fi òkúta àyànfẹ́ kan lélẹ̀ ní Síónì, òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé tó ṣeyebíye, kò sì sí ẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ tí a máa já kulẹ̀.”*+

7 Nítorí náà, ẹ̀yin ló ṣe iyebíye fún, torí ẹ jẹ́ onígbàgbọ́; àmọ́ fún àwọn tí kò gbà gbọ́, “òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀,+ òun ló wá di olórí òkúta igun ilé”*+ 8 àti “òkúta ìkọ̀sẹ̀ kan àti àpáta agbéniṣubú.”+ Wọ́n ń kọsẹ̀ torí wọn ò ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà. Ìdí tí a fi yàn wọ́n nìyí. 9 Àmọ́ ẹ̀yin ni “àwọn èèyàn tí Ọlọ́run yàn, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́,+ àwùjọ àwọn èèyàn tó jẹ́ ohun ìní pàtàkì,+ kí ẹ lè kéde káàkiri àwọn ọlá ńlá”*+ Ẹni tó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.+ 10 Torí ẹ kì í ṣe àwùjọ èèyàn nígbà kan, àmọ́ ní báyìí ẹ ti di àwùjọ èèyàn Ọlọ́run;+ a kò ṣàánú yín nígbà kan, àmọ́ ní báyìí, a ti ṣàánú yín.+

11 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, mò ń gbà yín níyànjú, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀*+ pé kí ẹ máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara+ tó ń bá yín* jà.+ 12 Ẹ jẹ́ oníwà rere láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ kó lè jẹ́ pé tí wọ́n bá fẹ̀sùn ìwà ibi kàn yín, wọ́n á lè fojú ara wọn rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín,+ kí wọ́n sì torí ẹ̀ yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ àbẹ̀wò rẹ̀.

13 Nítorí Olúwa, ẹ fi ara yín sábẹ́ gbogbo ohun tí èèyàn dá sílẹ̀,*+ ì báà jẹ́ ọba+ torí pé ó jẹ́ aláṣẹ 14 tàbí àwọn gómìnà tó rán níṣẹ́ pé kí wọ́n fìyà jẹ àwọn aṣebi, kí wọ́n sì yin àwọn tó ń ṣe rere.+ 15 Torí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ fi ìwà rere yín pa àwọn aláìnírònú tó ń fi àìmọ̀kan sọ̀rọ̀ lẹ́nu mọ́.*+ 16 Ẹ wà lómìnira,+ kí ẹ má sì fi òmìnira yín bojú* láti máa hùwà burúkú,+ àmọ́ kí ẹ lò ó bí ẹrú Ọlọ́run.+ 17 Ẹ máa bọlá fún onírúurú èèyàn,+ ẹ máa nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará,*+ ẹ máa bẹ̀rù Ọlọ́run,+ ẹ bọlá fún ọba.+

18 Kí àwọn ìránṣẹ́ máa tẹrí ba fún àwọn ọ̀gá wọn pẹ̀lú ìbẹ̀rù tó yẹ,+ kì í ṣe fún àwọn tó jẹ́ ẹni rere, tó sì ń gba tẹni rò nìkan, àmọ́ fún àwọn tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn pẹ̀lú. 19 Torí ó dáa tí ẹnì kan bá fara da ìnira,* tó sì jìyà tí kò tọ́ sí i nítorí kó lè ní ẹ̀rí ọkàn rere lójú Ọlọ́run.+ 20 Àbí àǹfààní wo ló wà níbẹ̀ tí wọ́n bá lù yín torí pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ tí ẹ sì fara dà á?+ Àmọ́ tí ẹ bá fara da ìyà torí pé ẹ̀ ń ṣe rere, èyí dáa lójú Ọlọ́run.+

21 Kódà, ọ̀nà yìí la pè yín sí, torí Kristi pàápàá jìyà torí yín,+ ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.+ 22 Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan,+ kò sì sí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.+ 23 Nígbà tí wọ́n sọ̀rọ̀ àbùkù sí i,*+ kò sọ̀rọ̀ àbùkù sí wọn* pa dà.+ Nígbà tó ń jìyà,+ kò bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀, àmọ́ ó fi ara rẹ̀ sí ìkáwọ́ Ẹni tó ń dájọ́+ òdodo. 24 Ó fi ara rẹ̀ ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa+ lórí òpó igi,*+ ká lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀,* ká sì wà láàyè sí òdodo. Ẹ “sì rí ìwòsàn nítorí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀.”+ 25 Torí ẹ dà bí àwọn àgùntàn tó sọnù,+ àmọ́ ẹ ti wá pa dà sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn+ àti alábòójútó ọkàn* yín.

3 Bákan náà, kí ẹ̀yin aya máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ yín,+ kó lè jẹ́ pé, tí a bá rí ẹnikẹ́ni tí kò ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, a máa lè jèrè wọn nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn+ láìsọ ohunkóhun, 2 torí pé wọ́n fojú rí ìwà mímọ́ yín+ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀. 3 Kí ẹwà yín má ṣe jẹ́ ti òde ara, bí irun dídì, wíwọ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà+ tàbí wíwọ àwọn aṣọ olówó ńlá, 4 àmọ́ kó jẹ́ ti ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn, kí ẹ fi ìwà jẹ́jẹ́ àti ìwà tútù ṣe ọ̀ṣọ́ tí kò lè bà jẹ́,+ èyí tó níye lórí gan-an lójú Ọlọ́run. 5 Torí pé báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ tó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nígbà àtijọ́ ṣe máa ń ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, tí wọ́n sì ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn, 6 bí Sérà ṣe ń ṣègbọràn sí Ábúráhámù, tó ń pè é ní olúwa.+ Ẹ sì ti di ọmọ rẹ̀, tí ẹ bá ń ṣe ohun tó dáa, tí ẹ ò sì bẹ̀rù.+

7 Bákan náà, kí ẹ̀yin ọkọ máa fi òye bá wọn gbé.* Ẹ máa bọlá fún wọn+ bí ohun èlò ẹlẹgẹ́, tó jẹ́ abo, torí ẹ jọ jẹ́ ajogún+ ojúure ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.

8 Lákòótán, kí èrò gbogbo yín ṣọ̀kan,*+ kí ẹ máa bára yín kẹ́dùn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ ará, kí ẹ lójú àánú,+ kí ẹ sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.+ 9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú,+ ẹ má sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù san ọ̀rọ̀ àbùkù.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ máa súre,+ torí ọ̀nà yìí la pè yín sí, kí ẹ lè jogún ìbùkún.

10 Torí “ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn ìgbésí ayé rẹ̀, tó sì fẹ́ ẹ̀mí gígùn gbọ́dọ̀ ṣọ́ ahọ́n rẹ̀ kó má bàa sọ ohun búburú,+ kó má sì fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀tàn. 11 Kí ó jáwọ́ nínú ohun búburú,+ kó sì máa ṣe rere;+ kó máa wá àlàáfíà, kó sì máa lépa rẹ̀.+ 12 Nítorí ojú Jèhófà* wà lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn;+ àmọ́ Jèhófà* kọjú ìjà sí àwọn tó ń ṣe ohun búburú.”+

13 Lóòótọ́, ta ló máa ṣe yín léṣe tí ẹ bá ń fi ìtara ṣe ohun rere?+ 14 Síbẹ̀, tí ẹ bá tiẹ̀ jìyà nítorí òdodo, inú yín máa dùn.+ Àmọ́ ẹ má bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń bẹ̀rù,* ẹ má sì jáyà.+ 15 Ṣùgbọ́n ẹ gbà nínú ọkàn yín pé Kristi jẹ́ mímọ́, òun ni Olúwa, kí ẹ ṣe tán nígbà gbogbo láti gbèjà ara yín níwájú gbogbo ẹni tó bá béèrè ìdí tí ẹ fi ní ìrètí yìí, àmọ́ kí ẹ máa fi ìwà tútù+ àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.+

16 Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn rere,+ kó lè jẹ́ pé nínú ohunkóhun tí wọ́n bá ti sọ̀rọ̀ yín láìdáa, ìwà rere tí ẹ̀ ń hù torí ẹ jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi+ máa jẹ́ kí ojú ti àwọn tó ń sọ̀rọ̀ yín láìdáa.+ 17 Tó bá wu Ọlọ́run pé kó fàyè gbà á, ó sàn kí ẹ jìyà torí pé ẹ̀ ń ṣe rere,+ ju kó jẹ́ torí pé ẹ̀ ń ṣe ohun tó burú.+ 18 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀, Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún kú mọ́ láé,+ ó jẹ́ olódodo tó kú nítorí àwọn aláìṣòdodo,+ kó lè mú yín wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ Wọ́n pa á nínú ẹran ara,+ àmọ́ a sọ ọ́ di ààyè nínú ẹ̀mí.+ 19 Bẹ́ẹ̀ ló ṣe lọ wàásù fún àwọn ẹ̀mí tó wà lẹ́wọ̀n,+ 20 àwọn tó ṣàìgbọràn nígbà tí Ọlọ́run ń fi sùúrù dúró* ní àwọn ọjọ́ Nóà,+ lákòókò tí wọ́n ń kan ọkọ̀ áàkì,+ tí a fi gba àwọn èèyàn díẹ̀ là nígbà ìkún omi, ìyẹn ọkàn* mẹ́jọ.+

21 Ìrìbọmi tó tún ń gbà yín là báyìí fara jọ èyí, (kì í ṣe pé ó ń wẹ èérí ara kúrò, àmọ́ ó ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀rí ọkàn rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run),+ nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi. 22 Ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ torí ó lọ sí ọ̀run; a sì fi àwọn áńgẹ́lì, àwọn aláṣẹ àti àwọn agbára sí ìkáwọ́ rẹ̀.+

4 Níwọ̀n bí Kristi ti jìyà nínú ẹran ara,+ kí ẹ̀yin náà fi irú èrò kan náà gbára dì;* torí ẹni tó ti jìyà nínú ẹran ara ti jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀,+ 2 kó lè fi àkókò tó ṣẹ́ kù fún un láti gbé nínú ẹran ara ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run,+ kó má fi ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èèyàn mọ́.+ 3 Torí àkókò tó ti kọjá tí ẹ fi ṣe ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè ti tó yín,+ nígbà tí ẹ̀ ń hu ìwà àìnítìjú,* tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, tí ẹ̀ ń mu ọtí àmujù, ṣe àríyá aláriwo, ṣe ìdíje ọtí mímu àti àwọn ìbọ̀rìṣà tó jẹ́ ohun ìríra.+ 4 Ó ń yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ ò tún bá wọn lọ́wọ́ sí irú ìwà pálapàla tó ń buni kù bẹ́ẹ̀ mọ́, torí náà, wọ́n ń sọ̀rọ̀ yín láìdáa.+ 5 Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn yìí máa jíhìn fún ẹni tó ti ṣe tán láti ṣèdájọ́ àwọn tó wà láàyè àtàwọn tó ti kú.+ 6 Kódà, ìdí nìyẹn tí a fi kéde ìhìn rere fún àwọn òkú pẹ̀lú,+ kó lè jẹ́ pé bí a tiẹ̀ ṣèdájọ́ wọn nínú ẹran ara lójú àwọn èèyàn, wọ́n á lè wà láàyè nípa tẹ̀mí lójú Ọlọ́run.

7 Àmọ́ òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Torí náà, kí ẹ máa ronú jinlẹ̀,+ kí ẹ sì wà lójúfò,* kí ẹ lè máa gbàdúrà.+ 8 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín,+ torí ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.+ 9 Ẹ máa ṣe ara yín lálejò láìráhùn.+ 10 Bí kálukú bá ṣe ń rí ẹ̀bùn gbà, ẹ máa fi ṣe ìránṣẹ́ fún ara yín bí ìríjú àtàtà tó ń rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run gbà lóríṣiríṣi ọ̀nà.+ 11 Tí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kó sọ ọ́ bíi pé ó ń kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kó ṣe é bí ẹni tó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni;+ ká lè yin Ọlọ́run lógo nínú ohun gbogbo+ nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ògo àti agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.

12 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn àdánwò gbígbóná tó ń bá yín yà yín lẹ́nu,+ bíi pé nǹkan àjèjì ló ń ṣẹlẹ̀ sí yín. 13 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa yọ̀+ torí ibi tí ẹ lè bá Kristi jìyà dé,+ kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè yọ̀, kí ayọ̀ yín sì kún nígbà ìfihàn ògo rẹ̀.+ 14 Inú yín máa dùn tí wọ́n bá ń gàn yín* nítorí orúkọ Kristi,+ torí pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, ti bà lé yín.

15 Àmọ́ ká má ṣe rí ẹnikẹ́ni nínú yín tó ń jìyà torí pé ó jẹ́ apààyàn tàbí olè tàbí aṣebi tàbí torí ó ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀.+ 16 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá jìyà torí pé ó jẹ́ Kristẹni, kó má ṣe tijú,+ àmọ́ kó túbọ̀ máa yin Ọlọ́run lógo bó ṣe ń jẹ́ orúkọ yìí. 17 Torí àkókò tí ìdájọ́ máa bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run ti tó.+ Tó bá wá bẹ̀rẹ̀ lọ́dọ̀ wa,+ kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere Ọlọ́run?+ 18 “Tí kò bá ní rọrùn láti gba olódodo là, kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀?”+ 19 Nítorí náà, kí àwọn tó ń jìyà lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu máa fi ara* wọn lé Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ olóòótọ́ lọ́wọ́,* kí wọ́n sì máa ṣe rere.+

5 Torí náà, bí èmi náà ti jẹ́ alàgbà, tí mo fojú ara mi rí àwọn ìyà tí Kristi jẹ, tí mo sì máa pín nínú ògo tí a máa ṣí payá,+ mò ń rọ àwọn alàgbà tó wà láàárín yín* pé: 2 Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run+ tó wà níkàáwọ́ yín, kí ẹ máa ṣe alábòójútó,* kì í ṣe tipátipá àmọ́ kó jẹ́ tinútinú níwájú Ọlọ́run;  + kó má ṣe jẹ́ nítorí èrè tí kò tọ́,+ àmọ́ kí ẹ máa fi ìtara ṣe é látọkàn wá; 3 ẹ má ṣe jẹ ọ̀gá lórí àwọn tó jẹ́ ogún Ọlọ́run,+ àmọ́ kí ẹ jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.+ 4 Tí a bá sì fi olórí olùṣọ́ àgùntàn+ hàn kedere, ẹ máa gba adé ògo tí kì í ṣá.+

5 Bákan náà, kí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin máa tẹrí ba fún àwọn àgbà ọkùnrin.*+ Àmọ́ kí gbogbo yín gbé ìrẹ̀lẹ̀* wọ̀* nínú àjọṣe yín, torí Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.+

6 Torí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kó lè gbé yín ga ní àkókò tó yẹ,+ 7 ẹ máa kó gbogbo àníyàn* yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ torí ó ń bójú tó yín.*+ 8 Ẹ máa ronú bó ṣe tọ́, ẹ wà lójúfò!+ Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá yín ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù, ó ń wá bó ṣe máa pani jẹ.*+ 9 Àmọ́ ẹ kọjú ìjà sí i,+ kí ẹ dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ẹ mọ̀ pé irú ìyà kan náà ló ń jẹ gbogbo àwọn ará yín* nínú ayé.+ 10 Àmọ́ lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run onínúure àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo, ẹni tó pè yín sí ògo àìlópin rẹ̀+ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, máa fúnra rẹ̀ parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yín. Ó máa fún yín lókun,+ ó máa sọ yín di alágbára,+ ó sì máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in. 11 Kí agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.

12 Mo fi ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí mo kọ yìí ránṣẹ́ sí yín nípasẹ̀ Sílífánù,*+ arákùnrin olóòótọ́, kí n lè fún yín níṣìírí, kí n sì lè jẹ́rìí taratara pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tòótọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìyí. Ẹ dúró gbọn-in nínú rẹ̀. 13 Obìnrin tó wà ní Bábílónì, tó jẹ́ àyànfẹ́ bíi tiyín ń kí yín. Máàkù+ ọmọ mi náà ń kí yín. 14 Ẹ fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kí ara yín.

Kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi ní àlàáfíà.

Tàbí “àtìpó.”

Tàbí “yọ́ ọ mọ́.”

Tàbí “ìgbàlà ọkàn yín.”

Tàbí “tún máa sún yín ṣe nǹkan.”

Tàbí “àtìpó.”

Ní Grk., “la fi rà yín pa dà; dá yín nídè.”

Tàbí “tí ẹ jogún bá.”

Tàbí “ọkàn yín.”

Ìyẹn, irúgbìn tó lè méso jáde tàbí kó bí sí i.

Tàbí “gbogbo èèyàn.”

Ní Grk., “àsọjáde.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “Àsọjáde.”

Tàbí “ògidì wàrà.”

Tàbí “ti mọ̀.”

Ní Grk., “dójú tì.”

Ní Grk., “olórí igun.”

Ní Grk., “ìwà mímọ́,” ìyẹn àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ tó ń wúni lórí.

Tàbí “àtìpó.”

Tàbí “ọkàn yín.”

Tàbí “gbé kalẹ̀.”

Ní Grk., “mú kí àwọn aláìnírònú tó ń fi àìmọ̀kan sọ̀rọ̀ kó ẹnu wọn níjàánu.”

Tàbí “ṣe àwáwí.”

Ní Grk., “ẹgbẹ́ àwọn ará.”

Tàbí “ìbànújẹ́; ìrora.”

Tàbí “kẹ́gàn rẹ̀.”

Tàbí “kẹ́gàn wọn.”

Tàbí “igi.”

Tàbí “bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.”

Tàbí “ayé.”

Tàbí “máa gba tiwọn rò; máa fi ìmọ̀ bá wọn gbé.”

Tàbí “kí ẹ máa fi inú kan bá ara yín lò.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí kó jẹ́, “ẹ má bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn.”

0Ní Grk., “nígbà tí sùúrù Ọlọ́run ń dúró.”

0Tàbí “èèyàn.”

Tàbí “ṣèpinnu.”

Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·selʹgei·a tí wọ́n bá lò ó fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kí ẹ má sùn.”

Tàbí “sọ̀rọ̀ àbùkù sí yín.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “máa wá ìtẹ́wọ́gbà Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ olóòótọ́.”

Tàbí “gba àwọn alàgbà tó wà láàárín yín níyànjú.”

Tàbí “ẹ máa tọ́jú wọn dáadáa.”

Tàbí “àwọn alàgbà.”

Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”

Tàbí “fi ìrẹ̀lẹ̀ di ara yín lámùrè.”

Tàbí “ohun tó ń jẹ yín lọ́kàn; ìdààmú.”

Tàbí “ó bìkítà fún yín.”

Tàbí “ó ń wá ẹni tó máa pa jẹ.”

Ní Grk., “ẹgbẹ́ àwọn ará yín.”

Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́