ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 2 Pétérù 1:1-3:18
  • 2 Pétérù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2 Pétérù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Pétérù

ÌWÉ KEJÌ PÉTÉRÙ

1 Símónì Pétérù, ẹrú àti àpọ́sítélì Jésù Kristi, sí ẹ̀yin tí ẹ ti ní irú ìgbàgbọ́ tó ṣeyebíye tí àwa náà ní,* nípasẹ̀ òdodo Ọlọ́run wa àti Jésù Kristi Olùgbàlà:

2 Kí ìmọ̀ tó péye + nípa Ọlọ́run àti Jésù Olúwa wa mú kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà pọ̀ sí i fún yín, 3 torí agbára rẹ̀ tó wá láti ọ̀run ti jẹ́ ká ní gbogbo ohun tó mú ká lè ní ìyè àti ìfọkànsìn Ọlọ́run* látinú ìmọ̀ tó péye nípa Ẹni tó fi ògo àti ìwà mímọ́ rẹ̀ pè wá.+ 4 Àwọn nǹkan yìí ló fi jẹ́ ká ní àwọn ìlérí tó ṣeyebíye, tó sì jẹ́ àgbàyanu gan-an,*+ kí ẹ lè tipasẹ̀ wọn nípìn-ín nínú àwọn ohun ti ọ̀run,+ nígbà tí ẹ ti bọ́ lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́ ayé tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* máa ń fà.

5 Nítorí èyí, ẹ sa gbogbo ipá yín+ láti fi ìwà mímọ́ kún ìgbàgbọ́ yín,+ ìmọ̀ kún ìwà mímọ́ yín,+ 6 ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀ yín, ìfaradà kún ìkóra-ẹni-níjàánu yín,+ ìfọkànsin Ọlọ́run+ kún ìfaradà yín, 7 ìfẹ́ ará kún ìfọkànsin Ọlọ́run yín, ìfẹ́ kún ìfẹ́ ará yín.+ 8 Torí bí àwọn nǹkan yìí bá wà nínú yín, tí ẹ sì ní wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, wọn ò ní jẹ́ kí ẹ di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso+ ní ti ìmọ̀ tó péye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.

9 Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní àwọn nǹkan yìí jẹ́ afọ́jú, ó ti di ojú rẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀,*+ ó sì ti gbàgbé pé a wẹ òun mọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀+ tó ti dá tipẹ́tipẹ́. 10 Torí náà, ẹ̀yin ará, ẹ túbọ̀ ṣe gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe, kí pípè+ àti yíyàn yín lè dá yín lójú, torí tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ẹ ò ní kùnà láé.+ 11 Ní tòótọ́, èyí á mú kí ẹ wọlé fàlàlà* sínú Ìjọba ayérayé+ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.+

12 Ìdí nìyí tó fi wù mí kí n máa rán yín létí àwọn nǹkan yìí nígbà gbogbo, bí ẹ tiẹ̀ mọ̀ wọ́n, tí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́ tó wà nínú yín. 13 Àmọ́ mo rí i pé ó dáa, tí mo bá ṣì wà nínú àgọ́* yìí,+ láti máa rán yín létí kí n lè ta yín jí,+ 14 bí mo ṣe mọ̀ pé màá tó bọ́ àgọ́ mi kúrò, bí Olúwa wa Jésù Kristi ṣe jẹ́ kí n mọ̀ kedere.+ 15 Màá ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nígbà gbogbo, kó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, ẹ̀yin fúnra yín á lè rántí* àwọn nǹkan yìí.

16 Ó dájú pé kì í ṣe àwọn ìtàn èké tí a dọ́gbọ́n hùmọ̀ la tẹ̀ lé nígbà tí a jẹ́ kí ẹ mọ agbára Olúwa wa Jésù Kristi àti ìgbà tó máa wà níhìn-ín, àmọ́ a fi ojú ara wa rí ọlá ńlá rẹ̀.+ 17 Torí ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba, nígbà tí ògo ọlá ńlá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún un* pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́ mi, ẹni tí èmi fúnra mi tẹ́wọ́ gbà.”+ 18 Àní, ọ̀rọ̀ yìí la gbọ́ láti ọ̀run nígbà tí a wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè mímọ́.

19 Torí náà, a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mú kó túbọ̀ dá wa lójú, ẹ sì ń ṣe dáadáa bí ẹ ṣe ń fiyè sí i bíi fìtílà+ tó ń tàn níbi tó ṣókùnkùn (títí ilẹ̀ fi máa mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́+ sì máa yọ) nínú ọkàn yín. 20 Nítorí ẹ kọ́kọ́ mọ̀ pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó wá látinú èrò* ara ẹni èyíkéyìí. 21 Torí a ò fìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípasẹ̀ ìfẹ́ èèyàn,+ àmọ́ àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.*+

2 Àmọ́ o, àwọn wòlíì èké tún wà láàárín àwọn èèyàn náà, bí àwọn olùkọ́ èké ṣe máa wà láàárín ẹ̀yin náà.+ Àwọn yìí máa dọ́gbọ́n mú àwọn ẹ̀ya ìsìn tó ń fa ìparun wọlé, wọ́n tiẹ̀ máa sẹ́ ẹni tó rà wọ́n pàápàá,+ wọ́n á sì mú ìparun wá sórí ara wọn ní kíákíá. 2 Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ máa hu ìwà àìnítìjú*+ bíi tiwọn, àwọn èèyàn sì máa sọ̀rọ̀ àbùkù sí ọ̀nà òtítọ́ nítorí wọn.+ 3 Bákan náà, torí wọ́n jẹ́ olójúkòkòrò, wọ́n máa fi àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn kó yín nífà. Àmọ́ ìdájọ́ wọn tí a ti ṣe tipẹ́tipẹ́+ ò falẹ̀, ìparun wọn ò sì ní yẹ̀.*+

4 Ó dájú pé Ọlọ́run kò fawọ́ sẹ́yìn láti fìyà jẹ àwọn áńgẹ́lì tó ṣẹ̀,+ àmọ́ ó jù wọ́n sínú Tátárọ́sì,*+ ó fi wọ́n sí ìdè* òkùnkùn biribiri de ìdájọ́.+ 5 Kò sì fawọ́ sẹ́yìn láti fìyà jẹ ayé ìgbàanì,+ àmọ́ ó dá ẹ̀mí Nóà, oníwàásù òdodo sí+ pẹ̀lú àwọn méje míì  + nígbà tó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+ 6 Ó mú kí ìlú Sódómù àti Gòmórà jóná di eérú, ó tipa bẹ́ẹ̀ dá wọn lẹ́bi,+ ìyẹn sì jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+ 7 Ó gba Lọ́ọ̀tì olódodo là,+ ẹni tó banú jẹ́ gidigidi nítorí ìwà àìnítìjú* àwọn arúfin èèyàn— 8 torí ojoojúmọ́ ni ọkùnrin olódodo yẹn ń mú kí ọkàn* rẹ̀ gbọgbẹ́ nítorí ohun tó rí àti ohun tó gbọ́ tí àwọn arúfin yẹn ń ṣe nígbà tó ń gbé láàárín wọn. 9 Torí náà, Jèhófà* mọ bó ṣe ń gba àwọn èèyàn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àdánwò,+ síbẹ̀ ó mọ bó ṣe máa fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ìparun* ní ọjọ́ ìdájọ́,+ 10 ní pàtàkì àwọn tó ń wá bí wọ́n ṣe máa sọ ẹran ara àwọn míì di aláìmọ́,+ tí wọn ò sì ka àwọn aláṣẹ sí.*+

Wọ́n gbójúgbóyà, wọ́n jẹ́ aṣetinú-ẹni, wọn ò sì bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo láìdáa, 11 bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn áńgẹ́lì, tí wọ́n tiẹ̀ ní okun àti agbára jù wọ́n lọ, kì í sọ̀rọ̀ àbùkù nípa wọn tí wọ́n bá ń fẹ̀sùn kàn wọ́n, torí wọ́n bọ̀wọ̀ fún* Jèhófà.*+ 12 Àmọ́ àwọn èèyàn yìí ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa àwọn ohun tí wọn ò mọ̀,+ wọ́n dà bí àwọn ẹranko tí kì í ronú, tí wọ́n kàn máa ń ṣe ohun tí a dá mọ́ wọn, wọ́n wà* ká lè mú wọn, ká sì pa wọ́n. Ọ̀nà ìparun tí wọ́n ń tọ̀ máa mú ìparun wá sórí wọn, 13 àwọn ìwà burúkú tí wọ́n ń hù sì máa kóyà jẹ wọ́n.

Kódà ní ojúmọmọ, wọ́n ka ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ sí ìgbádùn.+ Èérí àti àbààwọ́n ni wọ́n, wọ́n ń gbádùn* àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń tanni jẹ, bí wọ́n ṣe ń bá yín jẹ àsè.+ 14 Àgbèrè ló kún ojú wọn,+ wọn ò lè jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì ń tan àwọn* tí kò dúró ṣinṣin jẹ. Wọ́n ti fi ojúkòkòrò kọ́ ọkàn wọn. Ọmọ ègún ni wọ́n. 15 Wọ́n pa ọ̀nà tó tọ́ tì, a sì ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ṣe bíi ti Báláámù,+ ọmọ Béórì, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ èrè ìwà àìtọ́,+ 16 àmọ́ a bá a wí torí ó ṣe ohun tí kò tọ́.+ Ẹran akẹ́rù tí kò lè sọ̀rọ̀ tó sọ̀rọ̀ bí èèyàn, kò jẹ́ kí wòlíì náà ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu.+

17 Wọ́n jẹ́ ìsun tí kò lómi àti ìkùukùu tí ìjì líle ń fẹ́ kiri, a sì ti fi òkùnkùn biribiri pa mọ́ dè wọ́n.+ 18 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà tí kò nítumọ̀. Wọ́n ń fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara+ àti ìwà àìnítìjú* tan àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń fi ẹ̀ṣẹ̀ ṣomi mu.+ 19 Wọ́n ń ṣèlérí òmìnira fún wọn, àmọ́ ẹrú ìwà ìbàjẹ́ làwọn fúnra wọn;+ torí ẹnikẹ́ni tí ẹlòmíì bá borí jẹ́ ẹrú ẹni tó borí rẹ̀.*+ 20 Ó dájú pé, lẹ́yìn tí ìmọ̀ tó péye nípa Jésù Kristi Olúwa àti Olùgbàlà bá ti mú kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbin ayé,+ tí wọ́n bá tún pa dà sí àwọn nǹkan yìí tó sì borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn ti burú ju ìbẹ̀rẹ̀ wọn.+ 21 Torí ì bá sàn kí wọ́n má mọ ọ̀nà òdodo lọ́nà tó péye ju pé lẹ́yìn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n kí wọ́n yí pa dà kúrò nínú àṣẹ mímọ́ tí wọ́n ti gbà.+ 22 Ohun tí òwe tòótọ́ náà sọ ti ṣẹlẹ̀ sí wọn: “Ajá ti pa dà sídìí èébì rẹ̀, abo ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀ ti ń yíra mọ́lẹ̀ nínú ẹrẹ̀.”+

3 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, lẹ́tà kejì tí màá kọ sí yín nìyí, bíi ti àkọ́kọ́, mò ń rán yín létí kí n lè ta yín jí láti ronú jinlẹ̀,+ 2 kí ẹ máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ṣáájú* àti àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì yín. 3 Lákọ̀ọ́kọ́, kí ẹ mọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn tó ń fini ṣẹlẹ́yà máa wá, wọ́n á máa fini ṣẹlẹ́yà, wọ́n á máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn,+ 4 wọ́n á máa sọ pé: “Ṣebí ó ṣèlérí pé òun máa wà níhìn-ín, òun wá dà?+ Ó ṣe tán, bí nǹkan ṣe rí gẹ́lẹ́ láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, bẹ́ẹ̀ náà ló rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá.”+

5 Torí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ gbójú fo òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí, pé nígbà àtijọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ọ̀run àti ayé dúró digbí látinú omi, kí ó sì wà láàárín omi;+ 6 ìyẹn la sì fi pa ayé ìgbà yẹn run nígbà tí ìkún omi bò ó mọ́lẹ̀.+ 7 Ọ̀rọ̀ yẹn kan náà la fi tọ́jú àwọn ọ̀run àti ayé tó wà báyìí pa mọ́ de iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+

8 Síbẹ̀, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má gbàgbé pé lójú Jèhófà* ọjọ́ kan dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún àti pé ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí ọjọ́ kan.+ 9 Jèhófà* kò fi ìlérí rẹ̀ falẹ̀,+ bí àwọn èèyàn kan ṣe rò pé ó ń fi falẹ̀, àmọ́ ó ń mú sùúrù fún yín torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.+ 10 Àmọ́ ọjọ́ Jèhófà*+ máa dé bí olè,+ nígbà yẹn àwọn ọ̀run máa kọjá lọ+ pẹ̀lú ariwo tó rinlẹ̀,* àmọ́ àwọn ohun ìpìlẹ̀ tó gbóná janjan máa yọ́, a sì máa tú ayé àti àwọn iṣẹ́ tó wà nínú rẹ̀ síta.+

11 Bí gbogbo nǹkan yìí ṣe máa yọ́ báyìí, ẹ ronú nípa irú ẹni tó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, 12 bí ẹ ti ń dúró de ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà*+ máa wà níhìn-ín, tí ẹ sì ń fi í sọ́kàn dáadáa,* nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run máa pa run  + nínú iná, tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ máa yọ́ nítorí ooru tó gbóná janjan! 13 Àmọ́ à ń retí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tó ṣèlérí,+ níbi tí òdodo á máa gbé.+

14 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe ń retí àwọn nǹkan yìí, ẹ sa gbogbo ipá yín kó lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín láìní èérí àti àbààwọ́n àti ní àlàáfíà.+ 15 Bákan náà, ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà, bí Pọ́ọ̀lù arákùnrin wa ọ̀wọ́n náà ṣe lo ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún un láti kọ̀wé sí yín,+ 16 ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí bó ti ṣe nínú gbogbo lẹ́tà rẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan kan nínú wọn ṣòroó lóye, àwọn nǹkan yìí sì ni àwọn aláìmọ̀kan* àti àwọn tí kò dúró ṣinṣin ń lọ́ po sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń ṣe sí àwọn ibi yòókù nínú Ìwé Mímọ́.

17 Torí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe mọ àwọn nǹkan yìí tẹ́lẹ̀, ẹ máa ṣọ́ra yín kí àṣìṣe àwọn arúfin má bàa ṣì yín lọ́nà pẹ̀lú wọn, tí ẹ ò sì ní dúró ṣinṣin* mọ́.+ 18 Àmọ́ ẹ túbọ̀ máa dàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi. Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ báyìí àti títí láé. Àmín.

Tàbí “ìgbàgbọ́ tí àǹfààní rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú tiwa.”

Tàbí “ti fún wa ní gbogbo ohun tó mú ká lè ní ìyè àti ìfọkànsìn Ọlọ́run lọ́fẹ̀ẹ́.”

Tàbí “fi fún wa ní àwọn ìlérí tó ṣeyebíye, tó sì jẹ́ àgbàyanu lọ́fẹ̀ẹ́.”

Tàbí “ìfẹ́ ọkàn.”

Tàbí kó jẹ́, “ó ti fọ́jú, kò ríran jìnnà.”

Tàbí “ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àǹfààní láti wọlé.”

Ìyẹn, ara tó ní lórí ilẹ̀ ayé.

Tàbí “sọ̀rọ̀ nípa.”

Ní Grk., “jẹ́ kó gbọ́ irú ohùn yìí.”

Tàbí “ìtúmọ̀.”

Ní Grk., “sún wọn; mú kí wọ́n gba ìmísí.”

Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·selʹgei·a tí wọ́n bá lò ó fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Grk., “ìparun wọn ò sì ní sùn.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “ọ̀gbun.”

Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “ìkékúrò.”

Tàbí “tí wọ́n sì fojú kéré ipò àṣẹ wọn.”

Tàbí “wọ́n ń fi ọ̀wọ̀ hàn níwájú.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “wọ́n bí wọn.”

Tàbí “wọ́n jẹ́ àwọn tí a bí sínú.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·selʹgei·a tí wọ́n bá lò ó fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ẹnikẹ́ni tí ohun kan bá borí rẹ̀ jẹ́ ẹrú ohun náà.”

Tàbí “ti sọ tẹ́lẹ̀.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ariwo tó ń yára kọjá lọ.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “tó sì ń wù yín gidigidi.” Ní Grk., “tí ẹ sì ń fẹ́ kó yára kánkán.”

Tàbí “aláìlẹ́kọ̀ọ́.”

Tàbí “fẹsẹ̀ múlẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́