ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 2 Jòhánù 1-13
  • 2 Jòhánù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2 Jòhánù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Jòhánù

ÌWÉ KEJÌ JÒHÁNÙ

1 Àgbà ọkùnrin,* sí obìnrin tí Ọlọ́run yàn àti sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí mo nífẹ̀ẹ́ tọkàntọkàn. Èmi nìkan kọ́ ni mo nífẹ̀ẹ́ yín, gbogbo àwọn tó ti wá mọ òtítọ́ pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ yín, 2 torí òtítọ́ tó wà nínú wa, tó sì máa wà pẹ̀lú wa títí láé. 3 Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àánú àti àlàáfíà pẹ̀lú òtítọ́ àti ìfẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti Jésù Kristi Ọmọ Baba yóò wà pẹ̀lú wa.

4 Inú mi dùn gan-an torí mo rí lára àwọn ọmọ rẹ tó ń rìn nínú òtítọ́,+ bí Baba ṣe pa á láṣẹ fún wa. 5 Torí náà, mò ń rọ̀ ẹ́, ìwọ obìnrin, (àṣẹ tí a ní láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mò ń kọ̀wé rẹ̀ sí ọ, kì í ṣe àṣẹ tuntun), pé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa.+ 6 Èyí sì ni ohun tí ìfẹ́ jẹ́, pé ká máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ rẹ̀.+ Àṣẹ náà nìyí, bí ẹ ṣe gbọ́ ọ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí ẹ máa rìn nínú ìfẹ́. 7 Nítorí ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ti wà nínú ayé,+ àwọn tí kò gbà pé Jésù Kristi wá nínú ẹran ara.*+ Àwọn yìí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.+

8 Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ má bàa mú kí iṣẹ́ wa já sí asán, ṣùgbọ́n kí ẹ lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.+ 9 Ẹnikẹ́ni tó bá ń kọjá àyè rẹ̀ tí kò sì tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Kristi kì í ṣe ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.+ Ẹni tó bá ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ yìí ni ọ̀rẹ́ Baba àti Ọmọ.+ 10 Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín, tí kò sì mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má gbà á sílé,+ ẹ má sì kí i. 11 Nítorí ẹni tó bá kí i ti lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀.

12 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo fẹ́ bá yín sọ, mi ò fẹ́ fi ìwé àti yíǹkì kọ wọ́n sí yín, àmọ́ mò ń retí láti wá sọ́dọ̀ yín ká lè sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín lè kún rẹ́rẹ́.

13 Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ, ẹni tí Ọlọ́run yàn, ń kí ọ.

Tàbí “Alàgbà.”

Ní Grk., “wá nínú ara.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́