Ohun Èèlò Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Kan Tí Ó Ṣe Pàtàkì
Mẹ́ḿbà ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè Sri Lanka kọ̀wé sí “Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe ‘Jí!’” Lẹ́tà rẹ̀ ni a tẹ̀ sí ìsàlẹ̀ yìí:
“Alàgbà Ọ̀wọ́n,
“Mo ní láti sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé ìròyìn Jí! tí ẹ ń ṣe jáde kéré, ó ṣe pàtàkì, ó sì ń bọ́ sásìkò gan-an. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ń ran àwọn èwe òde òní lọ́wọ́ láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú.
“Mo ti ka gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Ohun tí ó sì tẹ̀ mọ́ mi lọ́kàn ni pé ó yẹ kí gbogbo àwọn olùkọ́, akẹ́kọ̀ọ́, àti àwọn òbí sọ ọ́ di dandan láti máa ka ìwé ìròyìn yìí.
“Mo mọrírì iṣẹ́ ribiribi tí ẹ ń ṣe. Mo dàníyàn pé kí àwọn ìsapá yín máa kẹ́sẹ járí nìṣó.”
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀dà mílíọ̀nù 16 tí a ń tẹ̀ jáde ní èdè 78 nínú ìtẹ̀jáde Jí! kọ̀ọ̀kan. Àwọn ènìyàn yíká ayé mọ ìwé ìròyìn náà sí ohun èèlò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó ṣe pàtàkì. Ìwọ pẹ̀lú yóò jàǹfààní nínú rẹ̀ nípa kíkà á. Bí o bá fẹ́ mọ bí o ṣe lè rí ẹ̀dà kan gbà tàbí tí ó bá fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.