ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/8 ojú ìwé 20
  • Kí Ni Ìyàtọ̀ Tí Ó Wà Láàárín Òfófó àti Ìbanilórúkọjẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ìyàtọ̀ Tí Ó Wà Láàárín Òfófó àti Ìbanilórúkọjẹ́?
  • Jí!—1996
Jí!—1996
g96 4/8 ojú ìwé 20

Kí Ni Ìyàtọ̀ Tí Ó Wà Láàárín Òfófó àti Ìbanilórúkọjẹ́?

BI Ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfófó lè dà bí ohun tí kò lè pa ènìyàn lára ní ìgbà míràn (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè di ìbanilórúkọjẹ́ tàbí kí ó ṣamọ̀nà sí i), ìbanilórúkọjẹ́ sábà máa ń ba ènìyàn jẹ́, ó sì sábà máa ń fa ìpalára àti ìjà. Ó lè jẹ́ pé ó wá láti inú kèéta tàbí kí ó máà jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ní ọ̀nà méjèèjì, abanilórúkọjẹ́ náà ń fi ara rẹ̀ sínú ipò tí kò dára níwájú Ọlọrun, nítorí pé ‘dídá ìjà sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin’ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí Ọlọrun kórìíra. (Owe 6:16-19) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “abanilórúkọjẹ́” tàbí “afinisùn” ni di·aʹbo·los. A tún lo ọ̀rọ náà nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí àdàpè orúkọ fún Satani “Èṣù,” ẹni tí ó ba Ọlọrun lórúkọ jẹ́ jù lọ. (Johannu 8:44; Ìṣípayá 12:9, 10; Genesisi 3:2-5) Èyí fi orísun irú ìfinisùn tí ń bani jẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn.

Ìbanilórúkọjẹ́ máa ń jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, ní pàtàkì jù lọ, fún ẹni tí a ba orúkọ rẹ̀ jẹ́ náà. Òfin tí Ọlọrun fi fún Israeli pa á láṣẹ fún wọn pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sókè lọ sódò bí [abanilórúkọjẹ́] láàárín àwọn ènìyàn rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ró ti ẹ̀jẹ̀ ẹnì kejì rẹ.” (Lefitiku 19:16) A fi bí ìbanilórúkọjẹ́ ti léwu tó hàn níhìn-ín nípa títọ́ka sí i pé, nínú àwọn ọ̀ràn kan, píparọ́ mọ́ ènìyàn lè mú kí a pa ẹni tí ó parọ náà ní ti gidi. Àwọn ẹlẹ́rìí èké ti ṣokùnfà ikú àwọn ènìyàn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.—1 Ọba 21:8-13; Matteu 26:59, 60.

Nígbà míràn, àwọn ọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ èyí tí ó wà ní àṣírí, ṣùgbọ́n inú abanilórúkọjẹ́ máa ń dùn láti tú wọn fún àwọn ẹlòmíràn tí kò yẹ kí ó mọ̀ wọ́n. (Owe 11:13) Abanilórúkọjẹ́ máa ń rí ayọ̀ nínú títú àwọn nǹkan tí ó ń ru àwọn ènìyàn sókè. Ẹni tí ó bá ń tẹ́tí sílẹ̀ sí ìbanilórúkọjẹ́ pẹ̀lú ń ṣe ohun tí kò dára, ó sì ń ba ara rẹ̀ jẹ́. (Owe 20:19; 26:22) Àwọn ọ̀rọ̀ ìbanijẹ́ tí abanilórúkọjẹ́ kan sọ lè mú kí ẹnì kan yẹra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ìṣọ̀tá àti ìyapa sì lè bẹ̀rẹ̀.—Owe 16:28.

Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé pípọ̀ tí àwọn abanilórúkọjẹ́ yóò máa pọ̀ sí i yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àmì “ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Timoteu 3:1-3) Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, tí ó bá wà láàárín àwọn ènìyàn Ọlọrun, ni àwọn tí ó ní ẹ̀rù iṣẹ́ náà nínú ìjọ Kristian gbọ́dọ̀ bá wí, kí wọ́n sì tọ́ sọ́nà. (1 Timoteu 3:11; Titu 2:1-5; 3 Johannu 9, 10) Nítorí pé, ìbanilórúkọjẹ́ máa ń dá ìjà sílẹ̀ (Owe 16:28), ó máa ń fa àwọn “iṣẹ́ ti ẹran-ara” pàtó kan (irú bí ìkórìíra, ìjà, àti ìyapa) tí ó lè máà jẹ́ kí abanilórúkọjẹ́ náà àti àwọn ẹlòmíràn tí ó fà wọ inú ìwà àìtọ́ jogún Ìjọba Ọlọrun. (Galatia 5:19-21) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé abanilórúkọjẹ́ náà lè jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, kí ó sì jẹ́ atannijẹ, gbogbo ìṣe búburú rẹ̀ ni yóò tú jáde nínú ìjọ. (Owe 26:20-26) Jesu tú Judasi abanilórúkọjẹ́ náà fó (Johannu 6:70) fún àwọn aposteli rẹ̀, ó sì lé Judasi lọ kúrò lágbo rẹ̀ nígbà tí ó yá. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà náà ló fa ìparun Judasi.—Matteu 26:20-25; Johannu 13:21-27; 17:12.

Irú ìbanilórúkọjẹ́ kan ni kíkẹ́gàn ẹni, ìwà tí ó lè mú kí a yọ ẹnì kan kúrò nínú ìjọ Kristian, nítorí pé Ìwé Mímọ́ dá àwọn ẹlẹ́gàn lẹ́bi pé wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí ìwàláàyè. (1 Korinti 5:11; 6:9, 10) Ìbanilórúkọjẹ́ àti ìkẹ́gàn ẹni máa ń wé mọ́ ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun tàbí sí àwọn tí ó fi ọlá àṣẹ yàn láti máa ṣàkóso ìjọ àwọn ènìyàn rẹ̀. Irú àpẹẹrẹ kan ni ti Kora àti àwọn àṣọmọgbè rẹ̀, tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọjẹ́ sí Mose àti Aaroni, pẹ̀lú ìṣọ̀tẹ̀ sí ìṣètò Ọlọrun. (Numeri 16:1-3, 12-14) Juda pe àfiyèsí sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí àti àtúbọ̀tán wọn nígbà tí ó kìlọ̀ fún àwọn Kristian pé kí wọ́n yẹra fún ọ̀rọ̀ èébú, ìkùnsínú, àròyé ṣíṣe, àti sísọ “awọn ohun kàǹkà-kàǹkà.”—Juda 10, 11, 14-16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́