ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/22 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tó Wáyé Nígbà Ìjọba Násì Ṣé Ó Ṣì Tún Lè Ṣẹlẹ̀?
    Jí!—2001
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Pa Ọ̀pọ̀ Èèyàn Nípakúpa Títí Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Kí Nìdí Tí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Fi Ṣẹlẹ̀? Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kò Ṣe Fòpin Sí I?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Onígboyà Olùpàwàtítọ́mọ́ Borí Inúnibíni Ìjọba Násì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 4/22 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Mo sábà máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ẹnikẹ́ni kò fi ké gbàjarè nípa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà. Ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ìpakúpa-Rẹpẹtẹ Náà—Ta Ní Ké Gbàjarè?” (August 22, 1995) ti dáhùn ìbéèrè mi. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ké gbàjarè, mo sì ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi yangàn!

C. B., United States

Ǹjẹ́ ẹ lè gbà èmi—ẹnì tí kì í ṣe mẹ́ḿbà—láyè láti kí yín nípa sísọ̀rọ̀ lórí kókó ẹ̀kọ́ náà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ. Ìjíròrò aláìfẹ̀tanú gbè sápá kan nípa àfihàn láabi ìwà àìláàánú tí àwọn ènìyàn ń hù síra wọn yìí ni èyí tí ń lani lóye jù lọ tí mo tí ì bá pàdé rí. Ìgboyà àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ yín ní àkókò yẹn jẹ́ ohun kan tí ó ṣeni láàánú pé aráyé kò mọ púpọ̀ nípa rẹ̀.

L. B., England

Bàbá mi kú sí Sachsenhausen. Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin àgbà pẹ̀lú kú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹgbẹ́ Nazi. Mo ṣì ń rántí inúnibíni tí ẹgbẹ́ Nazi ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dáradára. Èyí ló sún mi láti fi ìmọrírì mi hàn fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Ẹ kú iṣẹ́!

F. D. J., Kánádà

Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà wú mi lórí gan-an. Ṣùgbọ́n n kò gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nìkan ṣoṣo ni “ohùn kan láàárín ìdákẹ́rọ́rọ́.” Àwọn Kọ́múníìsì pẹ̀lú kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa Hitler kí ó tó gorí àlééfà. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.

B. W., Germany

“Jí!” gbà pé Hitler ní ọ̀pọ̀ àwọn òṣèlú alátakò. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà tọ́ka ní pàtó sí ìkùnà àwọn ètò ìsìn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn pàdí àpò pọ̀ pẹ̀lú ìṣàkóso ẹgbẹ́ Nazi. Àwọn ẹgbẹ́ Nazi fúnra wọn tọ́ka sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gẹ́gẹ́ bí lájorí àwọn alátakò onísìn àwọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ onísìn kan ṣoṣo tí wọ́n fún ní àmì ìdánimọ̀ ẹlẹ́wọ̀n tiwọn nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́—àmì elésè àlùkò onígun mẹ́ta, tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí èyí tí ó burú jù lọ.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

Ìmìtìtì Ilẹ̀ ní Japan Mo ń sunkún bí mo ṣe ń ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ìjábá Òjijì ní Ilẹ̀ Japan—Bí Àwọn Ènìyàn Ṣe Kojú Rẹ̀.” (August 22, 1995) Arábìnrin Kristian tí mo fẹ́ràn jú lọ kú nínú ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn. Onítara gbáà ni. Mo mọ̀ pé yóò ní àjíǹde, èmi yóò sì tún rí i lẹ́ẹ̀kan sí i. Mo dúpẹ́ gidigidi fún gbogbo ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti ti ara tí a rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ìjọ àti Society. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ṣì máa ń sunkún nígbà tí mo bá ronú nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn.

T. M., Japan

Ìgbésẹ̀ wíwà létò tí ó sì yára kánkán tí àwọn Ẹlẹ́rìí gbé yà mí lẹ́nu pátápátá. Nígbà tí mo ka ìhìn lẹ́tà tí ń fi ìbìkítà hàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ìjọ tí ó wà ní Korea, mo ṣáà ń sunkún ni. Inú mi ń dùn gan-an tí mo bá ronú pé mo wà lára irú ètò àjọ tí ó kún fún ìfẹ́ bẹ́ẹ̀.

M. K., Japan

Ìfìbálòpọ̀-Fòòró-Ẹni Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ìfìbálòpọ̀-Fòòró-Ẹni—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbòbo Ara Mi?” (August 22, 1995) Ọmọ ọdún 17 ni mí, mo sì pàdé ọmọkùnrin kan tí kì í ṣe Kristian ní ilé ẹ̀kọ́. Mo gbẹ́kẹ̀ lé e, ṣùgbọ́n nígbà tí ó yá, òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fòòró mi pẹ̀lú àwọn àbá ìṣekúṣe àti ìhalẹ̀mọ́ni. Mo fi ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ ki n ba à lè bọ́ nínú ìṣòro náà. Mo kọ́ ohun púpọ̀ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí. Nísinsìnyí, mo ti mọ ohun tí mo lè ṣe tí ó bá di ọ̀ràn ti bíbá ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdìkejì lo.

T. G., Portugal

Òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan fi ìbálòpọ̀ fòòró mi, ó sì halẹ̀ mọ́ mi. Nítorí pé wọ́n ti bá mi ṣèṣekúṣe nígbà ọmọdé mi, ó sábà máa ń ṣòro fún mi láti lè gbèjà ara mi. Síbẹ̀síbẹ̀, léraléra ni mo ń wí fún un pé kí ó fi mí lọ́rùn sílẹ̀. Níkẹyìn, mo fi ẹjọ́ rẹ̀ sun àwọn agbanisíṣẹ́ wa, ó wá fi mi lọ́rùn sílẹ̀ lẹ́yìn náà. Mo mọrírì ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà gidigidi. Ó yẹ kí àwọn obìnrin mọ bí wọ́n ṣe lè kojú ìṣòro yìí.

V. A., United States

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́