Èé Ṣe Tí Ó Fi Ṣe Pàtàkì fún Àwọn Kristian Láti Mú Ìfaradà Dàgbà?
Ó DÁJÚ pé ìpamọ́ra pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun. Èso ẹ̀mí rẹ̀ ni ó jẹ́. (Galatia 5:22) Ènìyàn, tí a dá ní àwòrán àti ìrísí Ọlọrun, ní ìwọ̀n ànímọ́ yìí, ó sì lè gbé e ró nípa títẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti ìdarísọ́nà ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Genesisi 1:26, 27) Nípa bẹ́ẹ̀, a pàṣẹ fún àwọn Kristian láti mú ànímọ́ yìí dàgbà, kí wọ́n sì fi hàn. (Kolosse 3:12) Àmì ìdánimọ̀ ni ó jẹ́ fún àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun. (2 Korinti 6:4-6) Aposteli Paulu sọ pé: “Ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tessalonika 5:14) Ó fi hàn pé ó ṣe pàtàkì láti fi ànímọ́ yìí hàn kí a baà lè wu Ọlọrun. Àmọ́, ìpamọ́ra ẹni kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí a bá fi ìkùnsínú àti àwáwí ṣe é. Paulu fi hàn pé ohun tí ó lè buyì kúnni ni láti “máa ní ìpamọ́ra pẹlu ìdùnnú-ayọ̀.”—Kolosse 1:9-12.
Yàtọ̀ sí ayọ̀ tí ènìyàn ń rí láti inú lílo ìpamọ́ra, àwọn èrè ẹ̀san ibẹ̀ pọ̀. Jehofa gba èrè ẹ̀san nípa yíyin orúkọ rẹ̀ lógo. A dá Ọlọrun láre, a sì fi ìpèníjà lòdì sí òdodo àti ẹ̀tọ́ ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ hàn bí èké. (Genesisi 3:1-5; Jobu 1:7-11; 2:3-5) Bí ó bá ti pa Adamu, Efa, àti Satani ní ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ńkọ́? Àwọn kan ì bá ti parí èrò sí pé ẹjọ́ Satani tọ́ nínú ìpèníjà rẹ̀. Àmọ́, nípasẹ̀ ìpamọ́ra, Jehofa fún àwọn ènìyàn ní àǹfààní láti fi hàn lábẹ́ ìdánwò pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ lórí wọn àti pé àwọ́n fẹ́ láti sìn ín nítorí àwọn ànímọ́ rere rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, láti fi hàn pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ipò ọba-aláṣẹ Jehofa ju òmìnira pátápátá lọ, ní mímọ̀ pé ó sàn jù lọ.—Orin Dafidi 84:10.
Nítorí ìpamọ́ra tí Jesu Kristi lò nínú ṣíṣègbọràn sí Ọlọrun, ó gba èrè ẹ̀san tí ó kàmàmà jù lọ, dídi ẹni tí Bàbá rẹ̀ gbé sí ipò gíga ti jíjẹ́ ọba, tí a sì fún un ní “orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.” (Filippi 2:5-11) Yàtọ̀ sí èyí, ó gba “ìyàwó” kan tí ó jẹ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ tẹ̀mí, Jerusalemu Tuntun, èyí tí a ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlú ńlá, tí orúkọ àwọn aposteli 12 ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wà lára àwọn òkúta ìpìlẹ̀ rẹ̀.—2 Korinti 11:2; Ìṣípayá 21:2, 9, 10, 14.
Lọ́nà kan náà, èrè ẹ̀san àwọn tí wọ́n bá mú ìpamọ́ra dàgbà, tí wọ́n sì ń bá a lọ ní ìbámu pẹ̀lú ète Ọlọrun pọ̀. (Heberu 6:11-15) Wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn ti ṣíṣàfarawé ànímọ́ Ọlọrun, ti ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun, àti ti níní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun. Ní àfikún, ìpamọ́ra wọn yóò mú àṣeyọrí wá nínú ríran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọrun, kí wọ́n sì jèrè ìyè ayérayé.—1 Timoteu 4:16.