Ní Èrò Ìtumọ̀ Wo Ni Ọlọrun Gbà ‘Mú Ayé Kan Padà Bá Ara Rẹ̀ Rẹ́’?
APOSTELI Paulu sọ nípa pé Ọlọrun “nípasẹ̀ Kristi ń mú ayé kan padà bá ara rẹ̀ rẹ́, láìṣírò awọn aṣemáṣe wọn sí wọn lọ́rùn.” (2 Korinti 5:19) A kò gbọdọ̀ ṣi èyí kà láti túmọ̀ sí pé a fi dandan mú gbogbo ènìyàn bá Ọlọrun rẹ́ nípa ẹbọ ìràpadà Jesu, níwọ̀n bí aposteli náà ti ń bá a lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti ṣàpèjúwe iṣẹ́ ikọ̀ ti pípàrọwà fún àwọn ènìyàn láti “padà bá Ọlọrun rẹ́.” (2 Korinti 5:20) Ní ti gidi, a pèsè ọ̀nà tí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ní ìfẹ́ inú láti dáhùn padà nínú ayé aráyé lè gbà jèrè ìbárẹ́padà. Nítorí bẹ́ẹ̀, Jesu wá ‘láti fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kan ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,’ àti pé, “ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ ninu Ọmọkùnrin ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọ́ràn sí Ọmọkùnrin kì yoo rí ìyè, ṣugbọn ìrunú Ọlọrun wà lórí rẹ̀.”—Matteu 20:28; Johannu 3:36; fi wé Romu 5:18, 19; 2 Tessalonika 1:7, 8.
Bí ó ti wù kí ó rí, Jehofa Ọlọrun pète láti “tún kó ohun gbogbo jọ papọ̀ ninu Kristi, awọn ohun tí ń bẹ ní awọn ọ̀run ati awọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé.” (Efesu 1:10) Níwọ̀n bí ìparun àwọn tí wọ́n kùnà láti “mú ọ̀ràn tọ́” (Isaiah 1:18, NW) pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun ti pọn dandan, àbájáde rẹ̀ yóò jẹ́ àgbáyé kan tí ó wà ní ìbámu pátápátá pẹ̀lú Ọlọrun, aráyé yóò sì tún dunnú nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọrun lẹ́ẹ̀kan sí i, tí wọn yóò sì gbádùn ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìtújáde ìbùkún rẹ̀ bíi ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ní Edeni.—Ìṣípayá 21:1-4.
Jehofa Ọlọrun fòpin sí ìbátan onímájẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Israeli gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan nítorí àìṣòdodo wọn àti kíkọ̀ tí wọ́n kọ Ọmọkùnrin rẹ̀. (Matteu 21:42, 43; Heberu 8:7-13) Ó ṣe kedere pé aposteli náà ń tọ́ka sí èyí nígbà tí ó ń sọ pé ‘títa wọ́n nù túmọ̀ sí ìpadàrẹ́ fún ayé’ (Romu 11:15), nítorí gẹ́gẹ́ bí àyíká ọ̀rọ̀ náà ṣe fi hàn, ọ̀ná tipa bẹ́ẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún aráyé lẹ́yìn òde àwùjọ tàbí ìjọ àwọn Júù. Ìyẹn ni pé, àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Júù ní àǹfààní nísinsìnyí láti dara pọ̀ pẹ̀lú ìyókù olùṣòtítọ́ Júù nínú májẹ̀mú tuntun gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tuntun ti Ọlọrun, Israeli ti ẹ̀mí.—Fi wé Romu 11:5, 7, 11, 12, 15, 25.
Bí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọrun, “àkànṣe ìní” rẹ̀ (Eksodu 19:5, 6; 1 Ọba 8:53, NW; Orin Dafidi 135:4), àwọn Júù ti gbádùn ìwọ̀n ìpadàrẹ́ kan pẹ̀lú Ọlọrun, bí wọ́n tilẹ̀ ṣì nílò ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìpadàrẹ́ nípasẹ̀ Olùràpadà tí a sọ tẹ́lẹ̀, Messia náà. (Isaiah 53:5-7, 11, 12; Danieli 9:24-26) Níhà kejì, àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Júù ni ‘a sọ di àjèjì sí ìpínlẹ̀-ìjọba Israeli, wọ́n sì jẹ́ àjèjì sí awọn májẹ̀mú ìlérí naa, wọn kò sì ní ìrètí kankan, wọ́n sì wà ní ayé láìní Ọlọrun,’ nítorí wọn kò ní ìbátan pàtàkì kankan pẹ̀lú rẹ̀. (Efesu 2:11, 12) Síbẹ̀síbẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú àṣírí mímọ́ ọlọ́wọ̀ nípa Irú Ọmọ náà, Ọlọrun pète láti mú ìbùkún wá fún àwọn ènìyàn “gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.” (Genesisi 22:15-18) Nítorí náà, ẹbọ Kristi Jesu, tí í ṣe ọ̀nà láti ṣe èyí, ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Júù, tí a ti sọ dàjèjì láti “wá wà nítòsí nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi.” (Efesu 2:13) Èyí nìkan kọ́, ẹbọ yẹn tún mú ìyàtọ̀ láàárín Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù kúrò, nítorí tí ó mú májẹ̀mú Òfin ṣẹ, ó sì mú un kúrò lọ́nà, tí ó tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ó ṣeé ṣe fún Kristi láti “lè mú awọn ènìyàn méjèèjì naa ninu ara kan padà bá Ọlọrun rẹ́ ní kíkún nípasẹ̀ òpó igi oró, nitori ó ti pa ìṣọ̀tá [ìyàsọ́tọ̀ tí májẹ̀mú Òfin ṣe] náà nípasẹ̀ oun fúnra rẹ̀.” Àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù lè ní ọ̀nà kàn ṣoṣo láti sún mọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ Kristi Jesu nísinsìnyí, àti bí àkókò ti ń lọ, a mú àwọn tí kì í ṣe Júù wọnú májẹ̀mú tuntun gẹ́gẹ́ bí àwọn àjògún Ìjọba pẹ̀lú Kristi.—Efesu 2:14-22; Romu 8:16, 17; Heberu 9:15.