O Ń Kóùngbẹ Ìmọ Bíbélì Bí?
NÍ ÀWỌN ilẹ̀ Kọ́múníìsì, a ti fòfin de òmìnira láti jíròrò Bíbélì fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Ṣùgbọ́n bí Ogun Tútù náà ti parí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ènìyàn níbẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìmọ̀ Bíbélì. Nígbà tí èyí ń ṣẹlẹ̀, ní pàtàkì, ní àwọn ilẹ̀ olómìnira Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí, ipò náà rí bákan náà ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn Europe.
Fún àpẹẹrẹ, ìjíròrò Bíbélì kan mú ayọ̀ ńláǹlà bá ẹni ọdún 45 kan, tí ó jẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè àti ẹ̀kọ́ ìpoǹkanpọ̀, ní Pecs, Hungary. Olùkọ́ náà kọ̀wé pé: “Ó jẹ́ ìrírí arùmọ̀lárasókè àti onídùnnú láti bá ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ nígbà tí mo ṣèbẹ̀wò sí Budapest. Mo nífẹ̀ẹ́ sí kíka Ìwé Mímọ́, n óò sì mọrírì kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tọpẹ́tọpẹ́ ni n óò tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ yín.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń láyọ̀ láti pèsè irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn níbi gbogbo. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ kí ẹnì kan kàn sí ọ láti bá ọ jíròrò Bíbélì nínú ilé rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5, fún ìsọfúnni.