ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/22 ojú ìwé 32
  • Jí! Ṣèrànwọ́ Láti Gba Ẹ̀mí Kan Là

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jí! Ṣèrànwọ́ Láti Gba Ẹ̀mí Kan Là
  • Jí!—1996
Jí!—1996
g96 8/22 ojú ìwé 32

Jí! Ṣèrànwọ́ Láti Gba Ẹ̀mí Kan Là

Bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ecuador ṣe ń dúró kí mẹ́káníìkí parí iṣẹ́ lára ọkọ̀ rẹ̀, aya mẹ́káníìkì náà sọ fún Ẹlẹ́rìí náà pé ìdààmú ń bá òun nípa Byron, ọmọkùnrin ọwọ́ òun. Ó ń ní àìperí ní ìgbà márùn-ún tàbí mẹ́fà lọ́sẹ̀ kan ṣoṣo, àwọn dókítà kò sì lè sọ ohun tí ìṣòro náà jẹ́. Kódà, wọ́n ti gbé Byron lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ògbóǹtagí ní Quito, olú ìlú ńlá náà.

Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo ń bá ìyá náà jíròrò, mo kíyè sí òṣìṣẹ́ kan tí ń kun ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan lọ́dà, mo sì rántí ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ kan lórí májèlé òjé nínú Jí! Ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà mẹ́nu bà á pé ọ̀kan lára àwọn àmì àrùn májèlé òjé ni àìperí. Mo sọ fún obìnrin náà pé n óò mú ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà wá fún un.”

Nígbà tí àwọn òbi Byron ka ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ náà, wọ́n gbé ọmọ wọn lọ fún àyẹ̀wò májèlé òjé. Wọ́n rí ìwọ̀n òjé gíga nínú ẹ̀jẹ̀ Byron. Ìtọ́jú ìṣègùn àti ìdènà ìṣíra sílẹ̀ sí òjé síwájú sí i yọrí sí ìmúsunwọ̀n tí ó gbàfiyèsí nínú ìlera Byron. Ẹlẹ́rìí náà sọ pé: “Kò ní àìperí kankan láàárín oṣù mẹ́rin tí ó kọjá. Láti ìgbà náà ni bàbá náà ti ń bá ọ̀pọ̀ dókítà sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn náà, ó sì sábà máa ń gbóríyìn fún Jí!, fún gbígba ẹ̀mí ọmọkùnrin rẹ̀ là. Kódà, àwọn kan lára àwọn dókítà wọ̀nyí ń ka Jí! nísinsìnyí.”

A ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ìwọ pẹ̀lú yóò jàǹfààní nípa kíka Jí! Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan tàbí kí ẹnì kan wá sí ilé rẹ láti jíròro Bíbélì pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, fún ìsọfúnni síwájú sí i, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára èyí tí a tò sí ojú ìwé 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́