Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni Ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan, àpilẹ̀kọ yín, “Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì—Ìsìn Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ” (January 8, 1996), gba àfiyèsí mi. Nígbà míràn tí ẹ bá ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, ẹ máa ṣàìlábòsí nípa jíjíròrò àwọn ipa tí ó ti kó, bíi bí ó ṣe dáàbò bo ìsìn Kristẹni nígbà inúnibíni ìsìn Mùsùlùmí àti ìṣàkóso Soviet. Yàtọ̀ sí ìyẹn, yíya Ṣọ́ọ̀ṣì àti Orílẹ̀-èdè sọ́tọ̀ kò bá Bíbélì mu. Àwọn ìjọba Ọba Dáfídì tàbí ti Sólómọ́nì ha yà sọ́tọ̀ kúrò lára Ṣọ́ọ̀ṣì bí?
M. F., United States
A kó àfiyèsí lé orí yánpọnyánrin tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ń dojú kọ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí—ọ̀ràn kan tí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde Gíríìsì ṣe àkọsílẹ̀ lé lórí dáradára. Yánpọnyánrin yìí sì jẹ́ àbáyọrí ìkùnà ṣọ́ọ̀ṣì náà láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù láti má ‘ṣe jẹ́ apá kan ayé’ àti láti wà láìdá sí tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú. (Jòhánù 17:16)—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ìkọlù Ìpayà Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Kíkojú Ìkọlù Ìpayà.” (June 8, 1996) Mo ti ń ní ìkọlù yí fún ọdún 14, mo sì rò pé èmi nìkan ni mo ní ìṣòro yìí. Nígbà míràn, mo máa ń ní ìmọ̀lára náà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro mi lè ṣàìtán, àpilẹ̀kọ yìí ti ràn mí lọ́wọ́ gidigidi.
C. C., Sípéènì
Ńṣe ni omijé ń dà wẹ̀rẹ̀wẹ̀rẹ̀ lójú mi bí mo ṣe ń ka àpilẹ̀kọ náà nípa ìkọlù ìpayà. Yóò ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí ìpayà bá tún gbìyànjú láti mú mi. Mo rò pé àpilẹ̀kọ náà jẹ́ ìdáhùn kan sí àdúrà mi.
M. B., Scotland
Fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 30 ọdún ni n kò ti lè wọ ọkọ̀ ojú irin tàbí bọ́ọ̀sì tàbí kí n wà láàárín èrò. Àwọn ìpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn àpéjọpọ̀ ti jẹ́ ìpèníjà ńlá. Nítorí náà, ẹ lè mọ bí àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ orísun ìṣírí àti ìtùnú gidigidi tó fún mi. Tinútinú ni mo ń dúpẹ́ pé ẹ ṣeun fún kíkọ̀wé nípa àìlera yìí lọ́nà tí ń gbéni ró, tí ó sì ń tuni nínú.
Y. T., Japan
Mo jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún, mo sì ti ń ní àwọn ìkọlù bíbanilẹ́rù wọ̀nyí láti 1994. Inú mi kì í dùn, n kì í sì í fẹ́ jáde nílé mi. Mo rò pé ìmọ̀lára wọ̀nyí jẹ́ nítorí àìnígbàgbọ́, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo mọ̀ pé èmi nìkan kọ́ ni Kristẹni tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí.
S. A., Brazil
Matilda Ẹlẹ́rù Orin “Matilda Ẹlẹ́rù” ń mú mi rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àyànláàyò. Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ (June 8, 1996) tí ó fúnni ní ìsọfúnni nípa bí orin yẹn ṣe wáyé. Kíkà á ti tún ta ọkàn ìfẹ́ mi jí láti máa ka gbogbo àpilẹ̀kọ inú Jí!
J. M., Germany
Àṣa Lílo Tẹlifóònù Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ títayọlọ́lá náà, “Báwo Ni Àṣa Lílo Tẹlifóònù Rẹ Ṣe Rí?” (June 8, 1996) Mo ń ṣiṣẹ́ ní báńkì kan tí ń bá àwọn oníbàárà ná lórí fóònù. Mo fún alábòójútó iṣẹ́ mi ní àpilẹ̀kọ náà, ó sì sọ fún mi pé, òun rí i pé àpilẹ̀kọ náà ṣàǹfààní, ó bọ́ sákòókò, ó sì gbéṣẹ́. Ó ní kí n jẹ́ kí gbogbo àwọn 32 tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ìpààrọ̀ ìlà ọ̀nà tẹlifóònù wa rí àpilẹ̀kọ náà.
N. J. S., Brazil
Lẹ́yìn tí àwọn olùtẹni-láago elérò ìwà ọ̀daràn ti fún wa ní ìṣòro ní àtijọ́, léraléra ni a ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ilé iṣẹ́ tẹlifóònù pé kí a máa gbé fóònù náà sílẹ̀, bí olùtẹni-láago náà bá kọ̀ láti dárúkọ ara rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti béèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà mẹ́ta. Èyí ti fa ìpalára ìmọ̀lára nígbà mélòó kan tí ọ̀rẹ́ kan bá tẹni láago, tí ó sì sọ pé, “Méfòó ẹni tí ń sọ̀rọ̀.” Àwọn àpilẹ̀kọ bí èyí ń gbé inúure àti ìgbọ́niyé lárugẹ, kódà, nínú irú àwọn nǹkan tí ó jọ pé wọ́n kéré bẹ́ẹ̀.
G. A., United States