Ṣírò Ohun Tí Kíkó Lọ Yóò Ná Ọ!
Láti Ọwọ́ Aṣojúkọ̀ròyìn Jí! Ní Gúúsù Áfíríkà
ÌWỌ ha ń ronú nípa kíkó lọ sí orílẹ̀-èdè míràn bí? Ṣé o ti ṣírò ohun tí yóò ná ọ? Kì í ṣe kìkì iye owó tí yóò ná ọ ni a ní lọ́kàn. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ní ń ronú nípa kíkó lọ nítorí ààbò ọrọ̀ ajé lọ́nàkọnà. Iye tí ó fara sin tí yóò ná ọ, tí ó máa ń fara hàn kìkì lẹ́yìn tí o bá ti kó lọ tán ni a ní lọ́kàn. Nígbà yẹn, ó sábà ti máa ń pẹ́ jù láti pa dà sílé. A kò pète àwọn kókó tí ó tẹ̀ lé e yìí láti kó ìdágìrì bá ọ, àmọ́, wọ́n tó láti ronú lé lórí:
“Kíkọ́ èdè tuntun kan ń gba ìrẹ̀lẹ̀ àti ìsapá. Ó máa ń ba àgbàlagbà kan lọ́kàn jẹ́ láti rí i pé àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá ń ronú pé òun jẹ́ àjèjì nítorí pé wọn kò lóye òun. Láti máa ṣe àṣìṣe lọ, bí wọ́n ṣe ń fini rẹ́rìn-ín látìgbàdégbà nítorí àwọn àṣìṣe ẹni jẹ́ ọnà lílágbára láti dán ìrẹ̀lẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn wò. Ìgbésí ayé jẹ́ ti ìdánìkanwà gan-an fún ọ̀pọ̀ àwọn àjèjì tí wọn kò lè sọ èdè àdúgbò.”—Rosemary, míṣọ́nnárì kan ní Japan.
Bóyá ìwọ lérò pé o mọ èdè náà dáradára tó láti mú kí nǹkan máa ṣẹnuure. Àmọ́, ṣé ó dá ọ lójú pé ìdílé rẹ lódindi mọ̀ ọ́n dáadáa tó, tí inú wọn yóò fi dùn nípa kíkó lọ náà?
Ipa wo ni yóò ní lórí ìdílé bí a bá tan àwọn kan lára ìdílé sípa kíkó lọ lòdì sí ìfẹ́ inú wọn? Ìwé àtìgbàdégbà náà, Psychology of Women Quarterly, sọ pé: “Àwọn obìnrin kan [láti Mexico] kò lẹ́nu sí ìpinnu láti kó lọ, wọn kò sì fẹ́ láti kó lọ rárá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dàníyàn láti wà ní United States lẹ́yìn kíkólọ.” Lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀, kíkólọ ní tipátipá lè ba ìṣọ̀kan ìdílé jẹ́. Àmọ́, bí ẹni tí ń gbọ́ bùkátà ìdílé bá dá lọ ńkọ́?
A fojú díwọ̀n rẹ̀ nínú ìwé náà, Population, Migration, and Urbanization in Africa, pé, ní ẹkùn ilẹ̀ ìgbèríko kékeré kan ní ìhà gúúsù Áfíríkà, ó lé ní ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún lára “àwọn àgbàlagbà ọkùnrin tí wọn kò fi àkókò kankan sí nílé.” Àìsínílé yìí lè fi ìtẹ́lọ́rùn àti ìdúró-déédéé du ìdílé. Ó tún lè mú kí ẹnì kejì nínú ìgbéyàwó juwọ́ sílẹ̀ fún ìwà pálapàla. Ẹ wo bí ó ti dára jù tó nígbà tí ìdílé bá lè wà pọ̀, yálà wọ́n pinnu láti kó lọ tàbí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀! Ohun tí owó kò lè rà ni ìṣọ̀kan ìdílé jẹ́.
Nígbà náà, ẹrù ìnira wíwúwo ti kíkojú ẹ̀tanú wà níbẹ̀. Ará Íńdíà kan tí ó kó lọ rántí pé: “Ìgbà tí mo kó dé England ni mo tó mọ̀ nípa ìṣòro ‘àwọ̀.’ [Bí mo ṣe mọ̀] yẹn burú jáì. Ẹ̀rù bà mí gan-an. Mo fẹ́ pa dà sí ìlú mi, láti bọ́ nínú gbogbo rẹ̀.”—The Un-melting Pot.
Nítorí náà, kí o tó kó lọ, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Kí ni mo lè ṣe dípò ìyẹn? Ṣe a kò lè ṣàtúnṣe ní ilé ni? Kíkó lọ sí orílẹ̀-èdè míràn yóò ha tóyeyẹ ní gidi bí?’ Ó lè rí bẹ́ẹ̀, ó sì lè ṣàìrí bẹ́ẹ̀, àmọ́, kí o tó ṣèpinnu, ronú lórí àmọ̀ràn rere tí Jésù fúnni yìí pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?”—Lúùkù 14:28.