Ọgbọ́n Tí Ó Wà Nínú Títakété sí Ìbálòpọ̀ àti Ìgbéyàwó Ọkọ-Kan-Aya-Kan
TÍTÍ di báyìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 30 mílíọ̀nù ènìyàn tí ó ti kó fáírọ́ọ̀sì àrùn AIDS, ó sì ti lé ní mílíọ̀nù 6 ènìyàn tó ti kú. Nǹkan bí 8,500 ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun àrùn náà ni a ń ṣàwárí rẹ̀ lójoojúmọ́—1,400 lára wọn jẹ́ ọmọdé, tí wọ́n sábà máa ń kú láàárín ọdún kìíní ìgbésí ayé wọn. Àwọn ìpolongo tí a sábà ń pè ní ìbálòpọ̀ tí kò léwu, ti gba àfiyèsí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn kan gbà pé èyí kò tó. Dókítà Steven J. Sainsbury kọ nínú ìwé agbéròyìnjáde The Tampa Tribune, pé: “Àrùn panipani ni àrùn AIDS, ìgbésẹ̀ èyíkéyìí tí a bá gbé láti dènà ìrànkálẹ̀ rẹ̀ gbọ́dọ̀ gbéṣẹ́ pátápátá láìkùsíbìkan.”
Nípa ti lílo kọ́ńdọ̀mù gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti dènà àrùn AIDS, Dókítà Sainsbury sọ pé: “Ẹ wò ó lọ́nà yí. Ká sọ pé, nítorí ìdí tí a kò mọ̀, àwọn ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bú gbàù nígbà tí ẹnì kan bá ṣíná wọn. Ìbúgbàù náà ń pa àwọn ọlọ́kọ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Níkẹyìn, ìjọba wá gbé ojútùú kan jáde. Wọ́n wí pé, ṣáà wulẹ̀ da àdàlú yìí sínú epo ọkọ̀ rẹ, ewu ìbúgbàù náà yóò sì dín kù ní ìwọ̀n 90 nínú ọgọ́rùn-ún. Ìwọ yóò ha kà á sí pé a ti rí ojútùú ìṣòro náà bí? Ṣé ìwọ yóò máa wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ nìṣó? Kò dá mi lójú. Nígbà náà, èé ṣe tí a fi tẹ́wọ́ gba lílo kọ́ńdọ̀mù gẹ́gẹ́ bí ojútùú fún àrùn AIDS?”
Ní mímọ̀ pé ìbálòpọ̀ ló sábà ń fa àrùn AIDS jù lọ, Dókítà Sainsbury pèsè ojútùú kan pé: “Má ṣe ní ìbálòpọ̀ kankan títí di ìgbà tí o bá ṣe tán láti bá ẹnì kan tí kò ì kó àrùn wọnú ìbátan ìgbéyàwó ọkọ-kan-aya-kan. Àwọn ọ̀rọ̀ ṣíṣekókó náà ni títakété sí ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó ọkọ-kan-aya-kan.”
Bíbélì pàṣẹ pé kí àwọn àpọ́n ta kété sí ìbálòpọ̀, kí àwọn tí ó ṣègbéyàwó sì jẹ́ onígbeyàwó ọkọ-kan-aya-kan. Àwọn ìlànà gígalọ́lá ti Bíbélì fòfin de àgbèrè, panṣágà, àti ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀. (Mátíù 19:4-6; Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 10; 7:8, 9) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣàríwísí ìlànà yí, pé kò bágbà mu tàbí pé ó ti di ti àtijọ́, ìlànà ìwà híhù tí Bíbélì gbé kalẹ̀ ti gbé ìlera àti àlàáfíà ọkàn lárugẹ.—Aísáyà 48:17.